Ilégbèé àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ dà wó, orí kó ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ yọ

Ilegbe awọn akẹkọọ fasiti to da wo
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn akẹkọọ fasiti Alex Ekwueme to wa ni Ndufu-Alike Ikwo, nipinlẹ Ebonyi, ti ṣalaye bi ori ṣe ko wọn yọ lasiko ti ilegbe wọn dawo lọjọ Ẹti, ọjọ karundinlọgbon, oṣu Keje, ọdun 2025 yii.

Ilegbe naa ti orukọ rẹ n jẹ 'Pentagon Lodge' lo tobi julọ ninu awọn ile akẹkọọ to wa lagbegbe ọhun ṣaaju ko to da wo.

Nigba ti akọroyin BBC lọ sibẹ lọjọ Abamẹta, o ri bi awọn akẹkọọ ṣe n gbiyanu lati ṣa dukia wọn ninu awoku ile naa.

Ile Awọn akẹkọọ fasiti Alex Ekwueme to wa ni Ndufu-Alike Ikwo, nipinlẹ Ebonyi, lẹyin to dawo

"Dukia ti owo rẹ to ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu naira ni a padanu sinu ile to da wo naa"

Ko si ẹnikankan to ba iṣẹlẹ naa lọ.

Lara awọn dukia awọn akẹkọọ to bajẹ ni ẹrọ amohunmaworan, ẹro ilewọ, ẹrọ kọmputa, ẹrọ amounjẹ tutu atawọn dukia miran.

Awọn akẹkọọ ti a ba sọrọ, Ujunwa Rita, Wisdom Ugochukwu atawọn mii sọ pe dukia ti iye owo rẹ to ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu naira ni awọn padanu.

Wọn ni nnkan bii aago mẹsan an aarọ ọjọ Ẹti ni ile naa dawo lasiko ti awọn akẹkọọ n mura lati lọ si kilaasi wọn.

Ile Awọn akẹkọọ fasiti Alex Ekwueme to wa ni Ndufu-Alike Ikwo, nipinlẹ Ebonyi, lẹyin to dawo

"Owo ile ti a san nile to dawo yii ko tii tan, pupọ ninu wa si ṣẹṣẹ san owo ile ni"

Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, wọn gbọ ti akẹkọọ kan pariwo ninu yara rẹ to si sa jade, lẹyin naa ni ile ọhun la si meji, ti ọkan lara awọn aja rẹ si wọ inu ilẹ lọ.

Eyii lo mu ki pupọ wọn bẹrẹ si maa gbẹ ile naa lati doola ara wọn.

Awọn akẹkọọ ọhun ṣalaye pe awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa fun wọn ni ilegbe kan ti orukọ rẹ n jẹ 'Convocation Arena' amọ ile naa ko yẹ fun awọn lati gbe.

Wọn sọ siwaju si pe owo ile ti awọn san nile to dawo yii ko tii tan ti pupọ ninu wọn si ṣẹṣẹ san owo ile.

Wọn ti wa ke si onile naa ati ijọba ko wa ọna lati da owo ile ti wọn san pada fun wọn ki awọn le lọ gba ile miran.

Ile Awọn akẹkọọ fasiti Alex Ekwueme to wa ni Ndufu-Alike Ikwo, nipinlẹ Ebonyi, lẹyin to dawo

"Ẹni to kọ ile naa yoo jẹ iya to tọ labẹ ofin"

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Ebonyi ti paṣẹ ki wọn wo iyoku ile naa ki wọn si bẹrẹ iwadii lori eredi to fi wo.

Kọmiṣọna fun ọrọ ile gbigbe ati idagbasoke awujọ ipinlẹ ọhun, Elechi Inyima, lo sọ bẹẹ lasiko to ṣabẹwo sibẹ.

Gomina ipinlẹ naa, Francis Nwifuru tun ti paṣẹ iwadii to peye lori ile ọhun.

O ni gbogbo awọn to lọwọ ninu kikọ ile naa to fi dawo ni yoo foju wina ofin.

Ile Awọn akẹkọọ fasiti Alex Ekwueme to wa ni Ndufu-Alike Ikwo, nipinlẹ Ebonyi, lẹyin to dawo