Wo iṣẹ́ ọwọ́ mẹ́wàá tó ti n lọ sóko ìparun nítorí ìmọ̀ ẹ̀rọ òde òní

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ojoojumọ ni aye n yi, bẹẹ ni imọ ẹrọ igbalode n tẹsiwaju kikankikan to bẹẹ ti ilana igbesi aye n yipada bi ojumọ ṣe n mọ.
Ọpọ nnkan elo ti ko si tẹlẹ lo ti wa lasiko yii, ti wọn n mu aye dẹrun ju ti tẹlẹ lọ.
Bi wọn ṣe wa n mu ayederun yii naa ni wọn tun n fi opin si awọn nnkan atijọ, titi kan iṣẹ ti awọn eeyan n ṣe.
Ọna atijẹ yii gan-an ni imọ ẹrọ to n dagba fi n dẹru ba awọn ẹlomi-in, nitori iṣẹ ti wọn n ṣe ti n lọ sókun igbagbe diẹdiẹ.
Wọnyi ni mẹwaa ninu awọn iṣẹ aje to ṣee ṣe ki wọn ma si mọ to ba ya pẹlu imọ ẹrọ igbalode ode oni, bi BBC ṣe ṣagbekalẹ wọn
Kásẹ́ẹ̀tì títà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Laye atijọ, ọna to rọrun ju lati gbọ orin tabi ohùn ẹnu yowu ko jẹ lorii redio ni nipa kasẹẹti ti wọn ti ka ohùn naa si.
Awọn eeyan yoo gbera lọ sọja lati ra kasẹẹti ni nigba naa lọhun-un, ki wọn le gbọ ọ nile tabi ninu mọto wọn.
Koda, wọn n ta kasẹẹti ti ko si ohun kankan ninu rẹ, ki awọn to ba fẹẹ ka ohun to wu wọn sinu rẹ le lo o.
Ṣugbọn lode oni, kasẹẹti ti kasẹ nilẹ. MP3 lawọn eeyan fi gbọ ohun ti wọn ba fẹẹ gbọ.
O wa lori aago awọn ẹlomi-in paapaa, irọrun gidi lo ba de.
Eyi ti ṣakoba fun ọja awọn to n ta kasẹẹti, o si le di dandan ki wọn wa nnkan mi-in ṣe.
Títa ẹrọ agbelewo DVD/CD

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Igba kan ti wa ri to jẹ ike pẹlẹbẹ ti wọn ti ka ere agbelewo tabi orin si lo gbode kan ni Naijiria yii.Ṣaaju rẹ si ni awọn eyi ti a mọ si DVD ti wọn fi n wo o.
Nigba naa, ọja igbalode gidi to gba oju ọwọ ni, o si n ta witiwiti.
Awọn eeyan ṣi ṣọọbu rẹ ti wọn n ya awọn to ba fẹẹ wo o, wọn a gbowo lọwọ wọn.
Gbogbo ṣọọbu bẹẹ lo ti kogba wọle bayii, nitori ẹka YouTube ati Netflix to gbode.
Rédíò títúnṣe àti títà
Nigba kan, redio jẹ ọkan lara awọn ko ṣee ma ni dukia tawọn eeyan pupọ ni, paapaa lati le maa fi gbọ iroyin agbaye ati awọn eto.
Awọn Hausa ni wọn tilẹ fẹran redio ju, wọn ki I ṣe alai ni i.
Lasiko naa, redio ta lọja, bẹẹ ni awọn ti wọn n tun un
ṣe to ba bajẹ naa n ka koko owo.
Ṣugbọn lonii, pẹlu imọ ẹrọ to faaye gba gbigbọ ohun ti o ba wu ọ lai lo redio, okowo redio ati atunṣe rẹ ti lọ silẹ jọjọ.
Awọn eeyan n gbọ redio lorii foonu wọn lai nilo redio rira mọ
Aago ara ògiri

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aye atijọ ni agogo baba mi kan laelae n duro lẹgbẹ ogiri, lasiko yii, yatọ si ṣọọṣi ati mọṣalaaṣi, lilo aago aye ọjọun lẹgbẹ ogiri ti dinku.
Eyi naa lo si fa a ti awọn ti wọn n tun aago atijọ naa ṣe ko ṣe pọ mọ.
Bi a ba yọwọ aago ọwọ ti a fi n kun ẹṣọ ara, to si ṣee so pọ mọ foonu lati fi gbe ipe tabi yẹ ilera wo, awọn aago mi-in si maa n juwee bi ibi kan ṣe jinna si, lo ṣi n jẹ ki aago ọwọ naa wulo, ti awọn ti wọn tun un ṣe si wa pẹlu.
Títà àti títún àtùpà ṣe
Laye ọjọun, atupa elepo tabi awọn ti wọn n lo batiri wọpọ, nitori ko si ina mọnamọna nigba yẹn.
Awọn eeyan n ra a, awọn to n tun un ṣe naa si wa, paapaa labule.
Ṣugbọn bayii, ina igbalode ti awọn eeyan le ro lagbara pada (rechargeable lamp) ni wọn n lo.
Ina solar to n lo itansan oorun ati ina ọba si wa pẹlu.
Koda, awọn to n lo atupa onikerosinni paapaa ti dinku jọjọ.
Títa káàdì ìpè

Oríṣun àwòrán, MTN
Igba kan ti wa ri ti awọn eeyan maa n du kaadi ipe ra,eyi ko ri bẹẹ mọ bayii.
Ọpọ eeyan lo n ra kaadi ipe lati inu apo ikowosi banki wọn.
Awọn mi-in n ra a lọwọ awọn oniPOS .
Iṣẹ́ fọ́tọ̀ yíyà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nigba kan ri, awọn eeyan yoo lọ si ṣọọbu awọn to n ya fọto, wọn yoo ya fọto pelebe (passport), awọn mi-in yoo ya ti igbeyawo tabi ayẹyẹ yoowu ti wọn ba fẹẹ ṣe.
Lonii, awọn foonu igbalode to n ya fọto ju kamẹra mi-in lọ ti wa.
Wọn yoo ya fọto to rẹwa to si mọlẹ kedere, bi wọn ba tun fẹẹ ṣe atunṣe si fọto naa, funra won ni wọn yoo ṣe e lorii foonu wọn.
Eyi ti mu adinku ba iṣẹ awọn ayaworan.
Ìwé títà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ile itawe wọpọ nigba kan, paapaa nitosi awọn ileewe.
Awọn akẹkọọ, olukọ ati awon eeyan mi-in naa maa n ra iwe nile itawe, lonii nkọ?
Awọn eeyan n ra iwe lati ori ayelujara, 'e-books, PDF ati awọn oju opo pọ ti eeyan ti le gbe gbogbo iwe to fẹ sọkalẹ sorii foonu tabi kọmputa wọn.
Ṣọ́ọ̀bù ìpè

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Igba kan ti wa ri ti awọn eeyan yoo fi ikalẹ si ṣọọbu awọn to n fi foonu silẹ pe ki wọn fi pe, ti wọn yoo si sanwo iye asiko ti wọn ba lo.
Awọn mi-in maa n lọ sibẹ nitori ai ni foonu, awọn kan si ni foonu, wọn ko le ra kaadi ipe ni.
Awọn eeyan naa yoo lọ sọdọ awọn oniṣọọbu ipe ti a mọ si Business center, wọn yoo sanwo pe tabi ki wọn fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si ẹni ti wọn fẹẹ ba sọrọ.
Ṣugbọn ni bayii, ọpọ eeyan lo ni foonu, wọn n pe bo ṣe wu wọn, wọn n fi atẹjiṣẹ ranṣẹ lawọn oju opo bii WhatsApp, Facebook, Instagram, Twitter ati awọn mi-in.
Títa orin lati ẹ̀ka Bluetooth tàbi kasẹẹti

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Igba kan ti wa ri ti awọn ọdọ maa n gba orin tabi fidio lati ori foonu kan si ikeji, ti wọn yoo lo ẹka Bluetooth tabi kaadi kekere ti wọn n pe ni Memory card.
Awọn kan si tun maa n gba awọn orin naa sorii kasẹẹti nigba yẹn, ti wọn yoo gbowo lọwọ ẹni ti wọn ba fi ranṣẹ si.
Ni bayii, pẹlu ẹrọ igbalode ayelujara ati awọn eyi ti wọn n pe ni Boomplay, Spotify ati Telegram, wọn ti fopin si ilana atijọ.
Awọn eeyan maa n sọ gbogbo ẹ kalẹ (download) bayii ni sorii foonu wọn taara.
Bi awọn iṣẹ kan ṣe n lọ si òkun igbagbe ni foonu n rọpo wọn. Ọpọ nnkan ni eeyan le ṣe nile rẹ lorii foonu lai tiẹ ṣe wahala kankan.
Eyi ti mu bi aye ṣe gbarale awọn iṣẹ kan nigba kan dinku, ko sẹni to nilo wọn mọ.
Ọgbọn n rewaju ni ọrọ ẹrọ igbalode asiko yii, bo ṣe n yi ni aye n ba a yi lọ.














