Òṣèré tíátà míì dágbére fáyé, ohun táa mọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Others
Ironu dori agba kodu nigba ti iroyin pe oṣere tiata, ọdọmọbinrin ti o ṣẹṣẹ n di ilumọka, Omotola Odunsi jade laye.
Akẹgbẹ rẹ, Bakare Zainab lo fi di iroyin naa mulẹ loju opo ayelujara rẹ, Instagram lọjọ kọkanlelọgbọn oṣu keje ọdun 2025.
Iroyin nipa ohun to ṣokunfa iku oloogbe ni ko ti han si araaye ṣugbọn ọpọ awọn oṣere tiata lo ti n ba awọn mọlẹbi Omotola Odunsi kẹdun lori iṣẹlẹ.
"O darọ, Omotola suure o," Zainab kọ ṣabẹ aworan to gbe sita lati fi kẹdun oloogbe naa.
Bakan naa gbajugbaja oṣere tiata, Akinola Akano,ẹni ti ọpọ mọ si Segbowe naa fi di iṣẹlẹ naa mulẹ.
Ṣegbowe gbe fọnran ọrọ ti oun ati oloogbe sọ ṣaaju ko to jade laye, nibi to ti ni ara oun ti n ya.
"Motola! Eyi yani lẹnu ṣugbọn mo gbiyanju lati bẹ ẹ wo ni owurọ ọjọ naa.
"O sọ fun mi pe ara rẹ ti ya, ti o si ti pada. Eyi yami lẹnu, Omotola, suure o. Ọlọrun yoo duro ti awọn mọlẹbi rẹ," Segbowe sọ.
Gbajugbaja oṣere tiata, Odunlade Adekola, ẹni to jẹ pe abẹ rẹ ni Omotola ti kọ iṣẹ, fọhun: "Jesu Kristi, Suure Omotola." motola."
Ta ni Omotola Odunsi?
Oloogbe naa kopa ninu ọpọ sinima, to fi mọ Lisabi: The Uprising, Officer Adaeze, Amonata, Ayanmo Ire, ati Ifedayo, ko to jaye laye.
Motola the Actor ni wọn bi niluu Ijebu-Ode, nipinlẹ Ogun, ti awọn mọlẹbo rẹ si wa lati ilu Ago-Iwoye.
O ka imọ ẹkọ nipa Microbiology ni fasiti Olabisi Onabanjo, ni bẹ lo ti pade Lateef Adedimeji, ti wọn ti jọ se ere ori itaje papọ.
O sisẹ diẹ gẹgẹ bii osisẹ banki, ko to kuro nibẹ patapata ni ọdun 2019 lati gbejumọ sinima sise.
O darapọ ile ẹkọ sinima Odunlade Adekola ni ọdun 2018.















