Ṣe ó tọ́ fún ìjọba Amẹrika láti lé àwọn ọ̀daràn orílẹ̀èdè rẹ̀ sí Afrika?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Priya Sippy
- Role, BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Ijọba ilẹ Amẹrika ti bẹrẹ si n tare awọn ọdaran rẹ si awọn orilẹede ilẹ adulawọ.
Loootọ ni wọn n tare awọn kan si Central America ati South America, lọjọ kejila oṣu Keje ọdun yii ni wọn tare awọn ọdaran lati Mexico, Myanmar ati Yemen lọ si Eswatini ati South Sudan nilẹ adulawọ.
Wọn tun tare ọmọ orilẹede Sudan kan pada si orilẹede rẹ.
Ijọba Amẹrika tun ti n ba awọn orilẹede mii sọrọ ni Afrika lati gba awọn ọdaran naa wọle lẹyin ti ijọba awọn orilẹede awọn eeyan naa kọ wọn.
Lọdun to kọja ni Aarẹ Trump ṣeleri lati maa da awọn ọmọ ilẹ okere to n wu iwa ọdaran pada silẹ wọn, paapaa awọn to jẹ ọmọ orilẹede ti ko rọwọ họri ti ọpọ araalu si faramọ igbesẹ naa.
Amọ awọn onimọ ti sọ pe Trump le ru ofin agbaye nipa igbeṣe ọhun.
Ṣe o tọ labẹ ofin agbaye lati maa da ale awọn ọdaran sawọn orilẹede ti ko rọwọ họri?
O ṣeeṣe ki igbesẹ naa ba ofin mu amọ kii ṣe ni gbogbo igba.
Ọjoọgbọn Ray Brescia lati ile ẹkọ US' Albany Law School sọ pe "ofin kan wa ninu ofin agbaye ti wọn n pe ni "non-refoulement" eyii to n tumọ si pe ijọba kan ko ni ẹtọ lati da eeyan pada si orilẹede rẹ ti ewu ba wa fun ẹmi irufẹ ẹni bẹẹ nilẹ rẹ.
Nitori naa, ti wọn ba le irufẹ ẹni bẹẹ si orilẹede mii ti ko rọwọ hori lagbaye le daabo bo ẹmi rẹ.
Ti ko ba si abo fun afurasi ọhun ni orilẹede rẹ, o le lodi si ofin agbaye lati le irufẹ ẹni bẹẹ pada sibẹ - gẹgẹ bi ile ẹjọ to ga julọ ni UK ṣe dena igbesẹ ijọba ilẹ Gẹẹsi lati le awọn to fẹ ṣe atipo nibẹ pada si Rwanda lọdun 2023.
O ṣe pataki lati gbe ọrọ naa gba ọna to yẹ.
Awọn alejo naa lanfani lati pe ẹjọ tako igbesẹ lati le wọn pada ti ibi ti wọn n le wọn pada si ba lewu fun wọn.
Ọmọwe Alice Edwards, to n ri si ọrọ ifiyajẹni ninu ajọ UN sọ pe ile ẹjọ yoo ṣe agbeyẹwo irufẹ igbeaye ti alejo naa yoo maa gbe nibi ti wọn le si ati irufẹ ile ti yoo maa gbe nibẹ.
Amọ ṣa, lọpọ igba lo maa n ṣoro fun awọn ajoji lati tete ri anfani si eto idajọ nilẹ okere.
Ṣe o lodi si ofin bi Amẹrika ṣe le awọn ọdaran si Eswatini ati South Sudan?
Ọjọgbọn David Super, to jẹ onimọ ofin lati fasiti Georgetown ni ọrọ naa pin si meji.
Lakọkọ, o ni "ko si aridaju pe ijọba Amẹrika fun awọn to le lanfani lati pe ẹjọ tako bo ṣe le wọn lọ ati pe, Amẹrika ko lanfani lati le awọn alejo naa si ibi ti wọn yoo ti gbogun ti wọn.
O sọ fun BBC pe "ijọba South Sudan ati Eswatini ni ibere lati dahun lori ọrọ ẹtọ ọmọniyan."
Nigba ti wọn le awọn ọdaran naa lọ si South Sudan ninu oṣu Karun un, awọn kan pe ijọba Amẹrika lẹjọ lẹyin ti baalu to n ko wọn lọ gbera tan.
Adajọ ile ẹjọ naa sọ pe igbesẹ lati gbe wọn lọ ti tako idajọ oun pe awọn eeyan naa lanfani lati pe ẹjọ tako igbesẹ lati le wọn lọ orilẹede ti ko rọwọ họri.
Baalu wọn ya si Djibouti nibi ti wọn ti ko wọn sinu ile ẹru ti wọn ti gbọ ẹjọ naa.
Lẹyin naa ni wọn tare ẹjọ ọhun si ile ẹjọ to ga julọ l'Amẹrika ti ile ẹjọ naa si sọ pe wọn le maa ko wọn lọ South Sudan gẹgẹ bii ibi ti abo yoo ti wa lori wọn.
Ọmọwe Edwards sọ pe igbẹjọ naa pẹ ko to bẹrẹ latari pe wọn ti n gbe wọn lọ ki igbẹjọ wọn to bẹrẹ.
Ṣe abo to peye wa ni Eswatini ati South Sudan?
Yatọ si pe wọn ko gbe ọrọ naa gba ọna to yẹ, niṣe ni wọn n fi awọn alejo naa sọko si orilẹede ti ko ni eto abo to peye – eyii to tako ofin agbaye.
Ileeṣẹ ijọba Amẹrika ti kede pe awọn eeyan rẹ ko gbọdọ rinrinajo lọ si South Sudan nitori eto abo ilẹ naa ti ko ṣe dede.
Ni ibẹrẹ ọdun yii ni wọn sọ pe orilẹede ọhun to jẹ ọkan lara awọn orilẹede to toṣi julọ lagbaye ṣeeṣe ko bẹrẹ ogun abẹle miran.
Ọmowe Edwards ni "a n kọminu lori ipo ti nnkan wani South Sudan, nipa iwa ipa, ijoba ti ko ṣe dede ati ikọlu lemọlemọ to n waye nibẹ."
Lọwọ yii, ọgba ẹwọn kan niluu Juba ni awọn ti wọn le lọ sibẹ wa, ọgba ẹwọn naa si buru jọjọ.
Ijoba orilẹede naa ko si ti kede iye igba ti won yoo fi wa lọgba ẹwọn ọhun.
"We don't foresee they will stay long enough to be integrated into society"
Ni Eswatini, awọn alaṣẹ sọ pe awọn eeyan naa wa ni ọgba ẹwọn kan amọ wọn yoo da wọn pada laipẹ pẹlu iranlọwọ ajọ Organization of Migration (IOM).
Ijọba Amẹrika ni ero ti pọju ninu ọgba ẹwọn naa bẹẹ ni eto ilera rẹ ko dara to.
Agbẹnusọ ijọba Eswatini, Thabile Mdluli sọ fun BBC pe "a o ri pe wọn maa duro pẹ nibi de bi pe wọn maa darapọ mọ awujọ wa" amọ ko mẹnuba bi wọn yoo ṣe pẹ to nibẹ.
Ijọba Amẹrika ni awọn ti wọn ko lọ si Eswatini wa lara awọn to wu iwa ibi to buru julọ bii fifi ipa ba ọmọde lopọ, fifi ọwọ kan obinrin lọna aitọ ati iwa ipaniyan.
Ọpọ awọn ọmọ Eswatini lo ti n bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa.
Ẹgbẹ oṣelu alatako Eswatini, People's United Democratic Movement sọ pe ajọṣepọ laarin orilẹede naa ati Amẹrika lori ọrọ ọhun da bii igba ti wọn n ta eeyan si oko ẹru.
Ajafẹtọọ ọmọniyan kan, Lucky Lukhele ni ko yẹ ki ijọba orilẹede naa sọ orilẹede oun di aatan ti wọn yoo ma da awọn ọdaran lati Amẹrika si.
Bo tilẹ jẹ pe ijọba Amẹrika tako ofin agbaye pẹlu igbesẹ naa, Ọjọgbọn Super ni ko si ijiya kankan ti yoo wa fun latari pe ko naani pupọ ninu awọn ile ẹjọ agbaye.
Anfani wo ni igbesẹ yii yoo ṣe fun South Sudan ati Eswatini?
Pupọ ninu ohun to rọ mọ igbesẹ naa ni wọn ṣe ni oku oru.
Mdluli sọ fun BBC pe oun ko ni le sọ eredi ti Eswatini ṣe gba awọn eeyan naa wọle fun BBC lasiko yii.
Amọ ṣa, Eswatini ati South Sudan sọ pe ajọṣepọ to dan mọran laarin orilẹede awọn ati Amẹrika lo mu ki wọn gba awọn ọdaran naa wọle.
Ọjọgbọn Brescia ni awọn orilẹede kan le gba awọn eeyan wọle latari ibẹru pe Amẹrika le gbẹsan lara wọn ti wọn ba kọ lati ṣe bẹẹ.
Ninu oṣu Kẹrin ọdun yii, Amẹrika ni oun yoo wọgile fisa to fun awọn eeyan South Sudan lẹyin ti ijọba ilẹ naa kọ lati gba ẹni ti wọn le pada sibẹ wọle.
A ko le sọ boya ayipada ti de ba eyii ni bayii to ti gba awọn ti Amẹrika le lọ sibẹ wọle.
Ajafẹtọ Machar sọ pe South Sudan gba lati gba awọn atipo ọhun wọle ki ijoba Amẹrika le gbẹsẹ kuro lori ofin to fi de igbakeji Aarẹ wọn, Benjamin Bol Mel.
Ọdun 2021 ni Amẹrika kọkọ fẹsun iwa ajẹbanu kan Bol Mel ki wọn to tun mẹnuba ẹsun naa lọdun yii.
Amọ ṣa, awọn orilẹede bii Naijiria ti kọ jalẹ.
Minisita ọrọ ilẹ okere Naiiria, Yusuf Tuggar sọ ninu oṣu Keje pe "Awa naa ni iṣoro tiwa ti a n koju."
Ọmọwe Edwards ni gbigba awọn eeyan naa wọle ni anfani tirẹ.
O ni lawọn igba ti irufẹ nnkan bẹẹ ti waye sẹyin, Amẹrika maa n fi ọpọlọpọ owo atawọn ohun ija oloro tẹle fun awọn orilẹede to ba gba awọn ọdarna naa wọle.
Ninu oṣu Kẹta ọdun yii ni ijọba Trump sọ pe oun yoo fun ijọba El Savador ni miliọnu mẹfa dọla lati gba awọn ọdaran ọmọ orilẹede Venezuela wọle silẹ rẹ.















