Wo àwọn ilé alákọ̀ọ́pọ̀ 'estate' 176 tí ìjọba Eko ní ayédèrú ni wọ́n

Awọn ile alakọpọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Ko din ni awọn ile alakọpọ, ti a mọ si estate ti ijọba ipinlẹ Eko ti kede bayii pe ibi ti wọn kọ wọn si lodi si ofin ile kikọ nipinlẹ ọhun.

Gbedeke ọjọ mọkanlelogun si ni wọn fun awọn to kọ ile naa lati pese iwe to fun wọn laṣẹ ati kọ ọ sibẹ, tabi ki ijọba ti ibẹ pa.

Awọn abanikọle ti ko ni iwe aṣẹ, ti a mọ si 'Developer' ni a gbọ pe wọn jẹbi iwa yii.

Laaarin ọjọ mọkanlelogun ni ijọba Eko kede pe wọn gbọdọ fi to iwe to le sọ awọn ile naa di ibugbe to tọna labẹ ofin.

Atẹjade kan lati ọfiisi ajọ to n ri si aato ilu nipinlẹ Eko, kede lọjọ Aje, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹjọ ọdun 2025 pe, awọn agbegbe bii Eti-Osa, Ajah, Ibeju-Lekki ati Epe ni awọn 'estate' naa wa.

Ọga agba nileeṣẹ to n ri si ato ilu, Oluwole Sotire, ṣalaye pe awọn ile naa lodi sofin nitori wọn ko gba iwe aṣẹ ikọle lati ileeṣẹ to n ri si ile kikọ, ki wọn to o kọ wọn.

O ni awọn 'estate' naa ko tẹle ilana ikọle 'T.H.E.M.E.S+' ti ijọba ipinlẹ Eko n lo.

Bakan naa ni agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Mukaila Sanusi, ṣalaye fun BBC pe bi awọn to ni ile wọn yii ba kuna lati pese iwe to tọ laarin ọjọ mọkanlelogun, ijọba yoo ti ibẹ pa ni.

Àwọn ilé náà tí púpọ̀ wọn wà ní erékùsù Eko rèé

  • Adron Homes, Elerangbe
  • Aina Gold Estate, Okun-Folu
  • Almond Gardens, Igbo-Esan
  • Atlantic Bay Estate, Awoyaya
  • Apple Shore Park, Akodo
  • Beach Front Gardens, Akodo
  • Belvic Housing Estate, Okun Lepia
  • Bricks and Bars Estate Phase II La Campaign Tropicana
  • Bright Water Estate Limited, Ibeju
  • Cedarwood Boulevard Estate Okun-Ajah
  • Cedarwood Estate Phase II
  • Cherrywoods Court Cherrywood
  • Coastal City Estate Phase II Orudu
  • Cornerstone Estate Eluju-Ibeju
  • Cowries Estate, Okun-Folu
  • Destiny Gardens Phase I
  • Destiny Gardens Phase II
  • Diamond Boulevard Estate Ibeju-Lekki
  • Diamond Estate, Eputu Awoyaya
  • Dominion Garden & Parks Annes
  • Dominion Onward Estate
  • Àwọn miran ni:
  • Ebenezer Estate, Igbo-Efon
  • Elnick Tourist
  • Grace Estate
  • Evergreen Estate
  • Experience Peace
  • Floodgate Gardens Estate
  • Folkalaus Estate Phase I
  • Folkalaus Estate Phase II
  • Foresight Estate Ibeju-Lekki
  • Fresh and Rest (Stallion Garden)
  • Gracias Global Estate
  • Havilah County Estate
  • Hectares of Diamond Sangotedo
  • Hectares of Diamond Phase II
  • Ikoyi Adams Estate
  • Imperial Garden Estate
  • Jenesis Colony (Lekki Garden City)
  • Jenesis Colony (Peace Estate)
  • Jewel Estate
  • Legacy Gardens
  • Lekki County Homes Ikota
  • Lekki Diamond Estate Phase II
  • Lekki Palms Estate
  • Lekki Villas 1 & 2 Bogije
  • Liberty Park 1
  • Liberty Park 2
  • Living- spring Citi 3
  • Livingstone Estate Digboloye, Ibeju
  • Livingstone Estate Orofun, Ibeju
  • Livingstone Estate Tagbati Ibeju
  • Natives Villa Estate
  • Next Ville Garden Estate
  • Oakwood Garden Park Phase II
  • Oakwood Garden Park Phase 2&3
  • Oakwood Garden Park Phase 3
  • Open Heaven Estate (Folkland Estate)
  • Open Heaven Estate Phase 2
  • Orange Pavilion
  • Orangeville Estate
  • Orisun Estate Okun-Folu
  • Pacific Homes Ikegun-Ise
  • Paradise Gardens Phase I
  • Pen Gardens Estate Phase I
  • Perez Gardens Estate
  • PHPAC Estate
  • Portview Estate
  • Prime Water View Garden Ikate Elegushi
  • Regent Park Garden Estate Phase I
  • Regent Park Garden Estate Phase II
  • Rehoboth Parks and Gardens Olomowewe Ibeju-Lekki
  • Rehoboth Parks Otolu village
  • Richwood Gardens Otolu village
  • Rosewoods Parks Phase II
  • Royal Palm Villa Igbo-efon
  • Royal Posch
  • Royal View Estate, Ikota
  • Safari Gardens Phase I
  • T.P. Voponu Integrated Estate
  • Tehila Gardens Phase I
  • The Bridge Estate Ibeju-Lekki
  • The Ebenezer Okun

Àwọn 'estate' yooku

  • Towns Parks and Gardens
  • Victory Park Estate, Ibeju Lekki LGA
  • Victory Garden Estate, Ibeju Lekki LGA
  • Walton Gate, Lakowe, Ibeju Lekki LGA
  • Wealthlands Green Estates, Awoyaya, Ibeju Lekki LGA
  • West Point Garden Phase IV, Ibeju Lekki LGA
  • Westwood Park Estate, Phase 11, Sangotedo Eti-Osa LGA
  • Flourish Residence, Sangotedo, Eti-Osa LGA
  • Westwood Park Estate, Sangotedo Eti-Osa LGA
  • Living Spring Estate Estate, Lafiaji, Eti-Osa LGA
  • Stonehelge Estate, Lafiaji Eti-Osa LGA
  • Southern Green Estate, Lafiaji Eti-Osa LGA
  • Highlink Royal Estate, Harris Drive, Sapata Eti-Osa LGA
  • Sunrise Court – 3, Harris Drive, Sapata Eti-Osa LGA
  • Crystal Estate – Off Harris Drive, Sapata Eti-Osa LGA
  • Spring Garden Estate - Phase 3, Harris Drive, Sapata Eti-Osa LGA
  • Horizon Estate, Harris Drive, Sapata Eti-Osa LGA
  • Melrose Park Estate - Harris Drive, Sapata Eti-Osa LGA
  • Victoria Crest Ill - Harris Drive, Sapata Eti-Osa LGA
  • Atlantic Ville Estate - Harris Drive, Sapata Eti-Osa LGA
  • Pacific Abode – Adekunle Idowu Close, Sapata Eti-Osa LGA
  • Royal View Estate – Ikota, Off Lekki Epe Expressway Eti-Osa LGA
  • Tulip Heaven Estate – Along Chevron ALT Route, Lekki, Eti-Osa LGA
  • Woodland Estate – Ikate, Eti-Osa
  • Stillwaters Garden – Along Ikate, Eti-Osa LGA.
  • Discovery Park Estate – Olugborogan Village Excision, Eti Osa LGA.
  • West Bridge Estate - Olugborogan Village Excision, Eti Osa LGA.
  • The Developer – Within DPK Estate, along Road 3, DPK Estate, Eti Osa LGA
  • Bricks and Brain – Within DPK Estate, along Road 3, DPK Estate, Eti Osa LGA
  • Lakeview Estate - Along Orchid Road, Eti Osa LGA
  • Hepli Royal Castle, Harris Drive, Sapata, Eti Osa LGA
  • Jennifer Garden, Phase 1 & 11, Eleko Junction, Eti Osa LGA
  • Isimi Eko, Epe
  • Pacific Abode Off Adekunle Idowu Close, lẹ́gbẹ̀ẹ VGC Lekki Epe
  • Whiteoak Estate 2, Off Adekunle Idowu Close, lẹ́gbẹ̀ẹ VGC Lekki Epe
  • Victoria Nest Lii Estate, Off Adekunle Idowu Close, lẹ́gbẹ̀ẹ VGC Lekki Epe
  • HRC Estate, Opposite Regional Road, Lekki Epe.
  • Meirose Park Estate, adojukọ Regional Road, Lekki Epe.
  • Princestone View Estate, By Harris Drive Off Regional Road, Lekki Epe.
  • Bosmak Haven 1,2,4 & 5, By Harris Drive, Off Regional Road, Lekki Epe.
  • Flourence court Estate, By Harris Drive, Off Regional Road, Lekki Epe.
  • Crystal Estate Phase 2,3 &4, By Harris Drive, Off Regional Road, Lekki Epe.
  • Carries Court Estate, By Harris Drive, Off Regional Road, Lekki Epe.
  • Briandavis Terrace Estate, lojuna Kid Court Lekki Epe.
  • Harvey Gardens Estate, lojuna Kid Court , Lekki Epe.

Àwọn mí-ìn ni

  • Micrian Villa Estate 1, lojuna Kid Court Street, Lekki Epe
  • John Great Court Estate, lojuna Kid Court Street, Lekki Epe
  • Twentieth Kid Estate, lojuna Kid Court Street, Lekki Epe
  • Marigold Ville Estatez, Along Kid Court Street, Lekki Epe
  • Sapphire Estate, lojuna Lekki Epe Expressway, Awoyaya, Ibeju Lekki LGA
  • Meridian Park Estate, lojuna Lekki Epe Expressway, Awoyaya, Ibeju Lekki LGA
  • Green Park Estate, Off Lekki Epe Expressway, Oribanwa, Ibeju Lekki LGA
  • Regent Park Estate, Awoyaya, Ibeju Lekki LGA
  • Wetland Estate, Oribanwa Phase 2, Awoyaya, Ibeju Lekki LGA
  • Mercyland Delight Estate, Oribanwa Phase 2, Awoyaya, Ibeju Lekki LGA
  • Peakpark Estate, Oribanwa Phase 2, Awoyaya, Ibeju Lekki LGA
  • Foreland Court Estate 2, Oribanwa Phase 2, Awoyaya, Ibeju Lekki LGA
  • Aswanda Estate, Maiden Village, Oribanwa, Ibeju Lekki LGA
  • Efficacy Estate, Beside FTC Yaba Staff Housing Estate, Oribanwa, Ibeju Lekki
  • FTC Yaba Staff Housing Estate, Off Lekki Epe Expressway, Oribanwa, Ibeju
  • Oakwood Garden Estate Lakowe, Ibeju Lekki LGA
  • Itunu Hills Estate, ojuna Lekki Epe Expressway, Alahun Village, Ibeju-Lekki LGA
  • Richland Garden Estate, ojuna Lekki Epe Expressway, Alahun Village, Ibeju-Lekki LGA
  • LNT New Town, Lakowe Golf Road, Lakowe, Ibeju Lekki LGA
  • Beechwood Estate,ojuna Lekki Epe Expressway, Bogije Ibeju Lekki LGA
  • Advania Estate, ojuna Lekki Epe Expressway, Lakowe, Ibeju Lekki LGA
  • Oxygen Estate, Off Lekki Epe Expressway, Aiyeteju Ibeju Lekki LGA
  • Greenville Estate, Along Lekki Epe Expressway, Atunrase, Eleko Ibeju Lekki
  • Delight Joe Bass Estate, ojuna Lekki Epe Expressway, Ibeju Lekki LGA
  • Capital Garden Estate, Along Lekki Epe Expressway, Eleko, Ibeju Lekki LGA
  • Morganite Estate, ojuna Lekki Epe Expressway, Eleko, Ibeju Lekki LGA
  • The Marbella Luxury And Smart Estate, ojuna Lekki Epe Expressway, Eleko, Ibeju Lekki LGA
  • Carlton Commercial, Ketu-Itoikin Road, Epe, Lagos, Epe LGA.
  • Lekki Palacio Garden, ojuna Lekki Epe Expressway, Ibeju Lekki LGA.
  • Dominion City Phase 1, Along Epe Ikorodu Road Epe, Lagos, Epe LGA.
  • Dukia Africa 1&2, Off Epe-Ikorodu Road, Epe, Lagos, Epe LGA.
  • White and Lilac, Off Epe-Ikorodu Road, Igbodu Epe Lagos.
  • Lavida Estate Phase 1&2, Igbodu Road, Off Epe-Ikorodu Road.
  • Royal Palm Villa, Lekki-Epe Expressway, Ibeju Lekki, Lagos.
  • Xtate, Igbodu Road, Off Epe-Ikorodu Road Epe LGA.
  • Patroit Bay Estate, Along Epe-Ikorodu Road Epe, Lagos State, Epe LGA.
  • Grand Harbor Estate, ojuna Ketu-Omu Road, Epe Lagos, Epe LGA.
  • Land of Plenty Estate (LOP), Along Ketu-Omu, Epe Lagos, Epe LGA.
  • Green City, Along Ketu-Omu, Epe Road, Epe LGA.
  • Yomade Heritage, ojuna Ketu-Omu, Epe Road, Epe LGA.
  • Coral City,ojuna Ketu-Omu, Epe Road, Epe LGA.
  • Megalopolis,ojuna Ketu-Omu, Epe Road, Epe LGA.
  • Lake View Park And Resort, Off Epe-Itoikin Road, Epe LGA.
  • Demagnificient Waterfront Estate, Off Epe-Itoikin Road, Epe LGA.

Kí ni ìwé ìlànà ilé kíkọ́ ti ìjọba ń fẹ́, báwo lo ṣe lè gba a?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iwe ilana ikọle ti a tun mọ si iwe aṣẹ ikọle (building permit) jẹ iwe aṣẹ lati kọle sibi kan lati ọdọ ijọba, eyi ti ileeṣẹ to n ri si ile kikọ niluu Eko fi ontẹ lu.

Ajọ to n ri si eyi l'Ekoo ni Lagos State Physical Planning Permit Authority (LASPPPA).

Ajọ yii lo n ri si ki ile ti wọn fẹẹ kọ ati ibi ti wọn fẹẹ kọ ọ si ba ofin mu ki wọn too bẹrẹ si i kọle naa.

Won yoo fun won ni iyọnda lati kọle ọhun, won yoo tun ri i daju pe ilana ti ofin ilu Eko (Lagos State Urban and Regional Planning and Development Law) fi lelẹ ni wọn tẹle.

Lati gba iwe aṣẹ ikọle, awọn ohun ti eeyan nilo ree:

Architectural Drawing (eyi ni aworan bi ile ti o fẹ kọ yoo ṣe ri)

Structural Drawing (eyi ni yoo fi bi ile naa yoo ṣe l'agbara si nipa ti eroja)

Electrical Drawing (afihan bi ina ẹlẹtiriiki yoo ṣe wa ninu ile naa)

Mechanical Drawing (Gbogbo igba kọ ni wọn n beere eyi).

Awọn yooku ni

1. Lẹta ti eeyan yoo kọ si kọmiṣanna eto ikọle, onimọ nipa ato ilu ni yoo kọ lẹta ọhun.

2. Ẹda ayẹwo to sọ bi ilẹ ṣe tobi to ti a mọ si survey .

3. Iwe to sọ bi ilẹ naa ṣe ri gan-an, wọn gbọdọ fi ontẹ lu u ki wọn si bo o loju.

4. Ibi ti ile naa wa.

5. Iru ile ti wọn fẹẹ kọ si i ati bẹẹ bẹẹ lọ.