Ṣé lóòótọ́ ni Gómìnà Ademola Adeleke ná 3.1bn lórí ìrìnàjò lọ s'ókè òkun?

Oríṣun àwòrán, Governor Ademola Adeleke/ Facebook
Bii ina inu ọyẹ ni iròyin naa bẹrẹ si i ran, ti wọn n gbe e kiri pe Gomina ipinlẹ Osun, Ọmọọba Ademola Adeleke, na 3.1bn lori irinajo lọ silẹ okeere, ati pe owo ipinlẹ Osun lo n na yafun-yafun bẹẹ.
Ẹka iroyin ayelujara to fi iroyin naa lede, ṣalaye pe laaarin oṣu kin-in-ni si ikẹfa ọdun 2025 ni Adeleke nawo to le ṣe ọpọ ẹka lanfaani lori irinajo lasan.
Owo ti iye rẹ to 2.854b ni iroyin sọ pe Gomina Adeleke na lati wọ baaluu, nigba ti wọn lo na 256m lori ẹkọ to lọọ kọ ati awọn irin to rin ko too debẹ.
Lori ounjẹ ati ipanu, N1.674 billion ni iroyin sọ pe gomina yii ṣe lofo danu, nigba ti owo ijokoo agba ati ti ẹ ṣe ti ẹ wa jẹ N702.8 million.
Iru owo nla yii yoo ni ipa to buru pupọ lara eto iṣuna ipinlẹ Osun, gẹge bi iroyin naa ṣe wi, pẹlu bo ṣe jẹ pe nnkan ko fi bẹẹ rọgbọ fun awọn olugbe ibẹ.
Iroyin naa fi kun un pe gbese pọ lọrun ijọba Osun, o ni owo ti wọn fi n san gbese fẹrẹ pọ ju owo ti wọn fi n ṣe nnkan alumọni lọ.
Ìjọba Osun ṣàlàyé
Ẹni ti a ti ọran mọ ki i dakẹ, ko ma baa jẹbi.
Kete ti iroyin owo nla ti wọn ni Gomina Adeleke na ninu owo ipinlẹ rẹ naa jade ni gomina ti sọrọ lati ipasẹ Agbẹnusọ rẹ, Mallam Olawale Rasheed.
Ninu atẹjade ijọba Osun ni wọn ti ṣalaye, pe loootọ ni gomina n rin irinajo, ṣugbọn ki i ṣe owo ijọba lo n na bẹẹ.
Atẹjade naa sọ pe baaluu aladaani (private jet) to jẹ ti ẹbi Adeleke ni gomina fi n rin irinajo rẹ, ki i ṣe owo ilu lo n na.
Wọn fi kun un pe lati din nina owo ipinlẹ Osun ku ni Adeleke ṣe maa n fi baaluu ẹbi rẹ tirafu lọpọ igba.
Bakan naa ni ijọba Osun ṣalaye, pe owo ti iroyin naa kede yii, jẹ iye tijọba ya sọtọ fun ọgọrun-un kan ileeṣẹ ijọba.
O ni owo naa wa fun idanilẹkọọ wọn fun odidi ọdun kan.
Ọpọ awọn ileeṣẹ ijọba naa lo si ti lọ fun idanilẹkọọ ti wọn nilo lọdun yii, gẹgẹ bi Agbẹnusọ gomina ṣe sọ.
O ni wọn tete lọ lati gbaradi fun idibo gomina ti yoo waye l'Osun ni 2026.
''Àwọn alátakò ìjọba ló ń gbé ohun tí kò rí bẹ́ẹ̀ kiri''
Ni itẹsiwaju alaye Agbẹnusọ Gomina Adeleke, o ni:
"Ki i ṣe pe iroyin ti wọn n gbe kiri naa le ṣi eeyan lọna lasan, o tun kun fun etekete pẹlu.
"Awọn alatako lo n ran ẹka iroyin naa niṣẹ, wọn si ti kuna.
"Bo tiẹ ṣe jẹ pe ijọba ipinlẹ Osun maa n gbe bo ṣe nawo rẹ soju opo ayelujara, ti fi han pe ko si nnkan kan ti a fi n pamọ.
"Gomina wulẹ jẹ olori ijọba ni, ọpọ awọn ẹka naa lo tun wa ti wọn n rin irin ajo, ti wọn yoo si ṣi owo wọn mọ irinajo gomina.
"Fun idi eyi, ko tọna lati sọ pe Gomina Adeleke n na aduru owo yẹn lori irinajo.
"Bẹẹ lo si yẹ ka wo pataki irinajo ti wọn n lọ naa, ki i ṣe pe wọn n da owo nu, anfaani ti yoo mu ba ipinlẹ wa laipẹ lo yẹ ka bojuto''
ìrìnàjò tí Gomina Adeleke ti lọ lọ́dún yìí
Lara irinajo ti Mallam Rasheed Olawale ka silẹ pe Gomina Adeleke ti lọ lọdun yii ni:
Commonwealth Business Investment Conference, nibi to ti gbiyanju lati pe awọn olokowo lati waa da ileeṣẹ silẹ l'Osun, to si tọwọ bọwe adehun pẹlu (MOU) ESG Management Services UK Ltd.
Nipa owo ti wọn fi tun ile ijọba ṣe, Agbẹnusọ Adeleke ṣalaye pe atunṣe naa kan awọn ileeṣẹ ijọba yoku.
O lo kan awọn ẹka ẹkọ, ẹka ilera, ileewe ijọba ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Nigba to n fi da araalu loju pe ijọba Adeleke n ko akoyawọ ninu eto rẹ, Olawale sọ pe ko si kinni kan ti ijọba yii fi n pamọ fun wọn.
" Awa o lẹbọ lẹru, a rọ awọn to ba fẹ atupalẹ bi ijọba ṣe n nawo ilu lati beere fun un labẹ ofin Federal Freedom of Information Act,"
Bẹẹ ni Agbẹnusọ Gomina Ademola Adeleke ṣalaye.














