Mọ̀ nípa ọdún Obalufon Alayemore níbi tí ìyàwó kábíèsí gbọ́dọ̀ ti rugbá lọ sídì òòṣa nílùú Ido-Osun

Iyawo kabiesi to rugba
Àkọlé àwòrán, Iyawo to kere ju laafin Ọba Olojudo lo ma n ru igba lọ si oju oori Obalufon
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Tilu-tifọn ni awọn eniyan ilu Ido-Osun, nipinlẹ Osun fi ṣe ayẹyẹ ọdun Obalufon, babanla wọn.

Ọdọọdun ni wọn ma n ṣe ọdun naa to farajọ ọdun Osun-Osogbo ti wọn n ṣe niluu Osogbo.

Yatọ si eyi, oriṣiriṣi nnkan ni ilu Ido-Osun fi jọ Ile-Ife, nitori pe babanla wọn ti wọn n ranti, Obalufon, ti jẹ Ooni Ile-Ife ri.

Koda, oun ni Ooni kẹta to jẹ.

Oun naa ni Ooni karun un ni ilu Ile-Ife ko to di pe o tẹ Ido-Osun do, to si jẹ ọba akọkọ nibẹẹ.

Oun lo gba ade Oba lẹyin ti baba rẹ Obalufon Ogbogbodirin waja .

Ni igba iwasẹ, aawọ waye laarin Oranmiyan ati Ọbalufọn Alayemọrẹ, eyi to mu ki Ọbalufọn wa lati tẹdo si Ido-Osun to wa ni ijọba Ibilẹ Egbedore nipinlẹ Osun.

Ọba Olayinka Oyetunde Ishola, Olojudo Alayemọrẹ ti Ido-Osun, ni, Ile-ife ni gbogbo idile to wa niluu Ido-Osun ti sẹ wa. Iran Ọbalufọn Alayemọrẹ si ni gbogbo awọn.

Ọbalufọn Alayemọrẹ jẹ Ooni kẹta ati Ẹkẹfa ni iluu Ile-ife ko to wa tẹdo. Nigba ti Oranmiyan pada de si iluu Ile-ife lati gba ipo Ooni lo mu ki Ọbalufọn kuro, to si wa tẹdo si Ido-Osun.

Oba Olojudo

Eyi si lo fa a ti awọn eniyan ilu naa ṣe ma n pe wọn ni ibatan pẹlu Ile-Ife, ti wọn si n ṣe ayẹyẹ ọdun Obalufon.

Kabiesi ilu naa, Ọba Olayinka, Olojudo Alayemore, sọ nibi wi pe, ẹya kan ni Ido-Osun ati iluu Ile-ife jẹ. Ati wi pe, gbogbo orisa to wa niluu Ile-ife lo wa niluu Ido-Osun.

Ọba Olayinka, wa rọ gbogbo awọn Oriade lati pada si asa iluu kowa wọn ki ilẹ Yoruba le leke nipa asa ati iṣe.

Nigba ti oun naa n sọrọ nibi ayẹyẹ naa, Ọba Adeagbo Michael Ajayi, Elerinmọ ti Erinmo Ijesa, salaye wi pe, Ọbalufọn Alayemọrẹ ni ẹni akọkọ to kọkọ de Ade are iluu Ile-ife.

Bakan naa lo wi pe, Ọbalufọn tun ni ẹni akọkọ to wọ ilẹkẹ fun awọn Oloye ati fun ara rẹ niluu Ile-ife.

"Ọbalufọn Alayemọrẹ lo so iluu Ido-Osun, Erinmo Ijesa ati Ile-ife papọ ti wọn fi jẹ ọmọ iya kan naa.

"O ti pẹ ti Ido-Osun ati Iluu Erinmo Ijesa ti jọ wa papọ nipasẹ Ọbalufọn Alayemọrẹ to so wọn papọ."

Awọn araalu to n ṣe ọdun Obalufon

Ki ni o waye nibi ayẹyẹ naa?

Aworan awọn araalu to n ṣe ọdun

Awọn oun to waye nibi Ayẹyẹ ọdun Ọbalufọn Alayemọrẹ, ni bi iyawo to kere ju laafin Alayemọrẹ ti gbe igba lọ si ojubọ Ọbalufọn Alayemọrẹ.

Eyi jẹ ọna lati ṣe irubọ si Obalufon, ati lati bu ọla fun un.

Aṣọ funfun ni awọn Ọlọsun ati Ọlọbatala wọ, pẹlu mọriwo lara wọn.

Ọjọ kẹrindinlogun, osu Kẹjọ ni asekagba ayẹyẹ ọdun Ọbalufọn Alayemọrẹ nibi ti ọdọ lobinrin ti ko mọ ọkunrin ri yoo ti rugba lọ si ọdọ ọsun niluu Ido-Osun.

Araba ilu Osogbo, Ifayemi Elebuibon, lo ṣe iwure ipari ni ọdun Ọbalufọn Alayemọrẹ to waye ọhun.

Awọn araalu ko ẹbun lọ saafin ọba
Aworan Yemi Elebubion
Àkọlé àwòrán, Araba ilu Osogbo, Ifayemi Elebuibon, lo ṣe iwure ipari ni ọdun Ọbalufọn Alayemọrẹ to waye ọhun.