Wo àwọn agbègbè tí ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ní kí àráàlú fi sílẹ̀ ní kíákíá nítorí ẹ̀kún omi tó n bọ̀

Awọn ọkọ to ri sinu omi nitori ẹkun omi to waye nipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba ipinlẹ Eko ti gbe ikilọ sita fun awọn olugbe agbegbe kan, pe ki wọn kuro ni agbegbe naa ni kiakia nitori ojo arọọrọda to bẹrẹ nipinlẹ naa.

Ọpọ awọn agbegbe nipinlẹ Eko lo jẹ pe wọn ti kun fun omi, ti awọn araalu si n kegbe pe ki ijọba ran wọn lọwọ.

Ikilọ naa waye lẹyin omiyale to waye ni awọn agbegbe kan lọjọ Aje lẹyin ojo arọọrọda.

Nigba to n sọrọ lori eto kan nileeṣẹ amohunmaworan Channels TV, Kọmisanna fun ayika nipinlẹ ọhun, Tokunbo Wahab ni o ṣe koko ki awọn eeyan kuro awọn agbegbe naa ṣaaju ki ajalu nla to waye.

O darukọ awọn agbegbe kan to wa ni Lekki, Ikorodu ati Ajegunle pe ki awọn olugbe agbegbe kuro lọ sibi ti ẹkun omi ko ti ni da wọn laamu.

"Fun awọn eeyan to wa ni agbegbe Ajilete niluu Eko, iyẹn ni Ajegunle, wọn ni lati kuro ni agbegbe naa," Wahab sọ.

Bakan naa ni Ikorodu, Majidun, ati awọn agbegbe kan ni Lekki."

Wahab sọ pe agbegbe Isheri ni OPIC jẹ ibi kan ti iṣoro omiyale ti n waye, ti o si ni ki awọn olugbe agbegbe naa ṣe ni oju ni alakan fi n sọri lasiko yii.

Ẹwẹ, Wahab sọ pe ko sewu ẹkun omi ni awọn agbegbe bii Epe, Mushin, ati Ikeja.

Ijọba apapọ ni o ṣe e ṣe ki iṣẹlẹ Omiyale waye nipinlẹ mọkandinlogun

Aworan bii ọkọ se n gba inu agbaara

Oríṣun àwòrán, Others

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bakan naa ni ijọba apapọ lorilẹede Naijiria ti fi ikilọ ransẹ si ipinlẹ mọkandinlogun pe oṣeeṣe ki iṣẹlẹ omiyale waye ni awọn ipinlẹ ọhun.

Ikilọ ọhun lo jade lọjọ Isẹgun lati ọwọ ajọ National Flood Early Warning Systems Centre of the Federal Ministry of Environment, ti wọn si kesi awọn ti ọrọ kan pe ki ri daju pe awọn olugbe agbegbe wọn se ohun to tọ lati dena de iṣẹlẹ omiyale.

Ikilọ yii lo waye lẹyin ti iṣelẹ omiyale waye ni awọn ipinlẹ bii Ogun, Eko ati Gombe bẹrẹ lati ọjọ Aje to fi mọ awọn ipinlẹ bii, Plateau, Anambra, ati Delta.

Awọn agbegbe ti ajọ naa gbe sita ni Akwa-Ibom (Edor, Eket, Ikom, Oron, Upenekang); Bauchi (Tafawa-Balewa, Azare, Jama'are, Kari, Misau, Jama'a); Ebonyi (Abakaliki, Echara, Ezilo); Cross-River (Ogoja Edor, Obubra); Nasarawa (Keana, Keffi, Wamba); Benue (Agaku, Buruku, Gboko, Igumale, Ito, Katsina-Ala, Ugba, Vande-Ikya); Kaduna (Jaji, Kafancha, Birnin-Gwari, Zaria) ati Katsina (Bindawa, Bakori, Daura, Funtua).

Awọn yooku ni Kebbi (Bagudo, Birnin-Kebbi, Bunza, Gwandu, Jega, Kalgo, Kamba, Kangiwa, Shanga, Ribah, Sakaba, Saminaka, Yelwa, Gauri-Banza); Kano (Bebeji, Gezawa, Gwarzo, Kano, Karaye, Tundun-wada, Wudil, Kunchi); Niger (Kontagora, Rijau, Ringim); Plateau (Mangu); Taraba (Donga, Takum); Jigawa (Diginsa, Gumel, Dutse, Gwaram, Hadejia, Miga); Yobe (Machina, Potiskum); Zamfara (Anka); Sokoto (Sokoto, Wamakko); Borno (Biu); ati Gombe (Bajoga).