Ìyàwó MKO Abiola, Doyin, jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Others
Agba akọroyin, Dokita Doyin Abiola, ẹni to jẹ iyawo oludasilẹ ileeṣẹ iroyin Concord ati olubori eto idibo aarẹ ni ọdun 1993, MKO Abiola ti jade laye lẹni ọdun mejilelọgọrin.
Ọjọ Karun un Oṣu kẹjọ ọdun 2025 ni Doyin Abiola jade laye, lẹyin to ṣe aisan ranpẹ .
Doyin Abiola, ni obinrin akọkọ ti yoo jẹ olori fun ileeṣẹ iwe iroyin lorilẹede Naijiria.
Gẹgẹ bii ti awọn iyawo Abiola yooku, oun naa la ọpọ nnkan kọja lasiko eto idibo aarẹ ọdun 1993.
Ohun taa mọ nipa Doyin Abiola
Doyin Abiola kawe ni fasiti ilu Ibadan, nibi to ti gba imọ oye ninu ẹkọ Gẹẹsi ati Ere sise lọdun 1969.
Lẹyin ti pari ẹkọ rẹ, o bẹrẹ iṣẹ pẹlu ileeṣẹ iwe iroyin Daily Sketch Newspaper. Lasiko yii, oun n kọ abala iwe iroyin kan ti o pe orukọ rẹ ni 'Tiro,' eyi to fi n tan imọlẹ si awọn ohun to n lọ ni ilu, ko to di pe o morile orilẹede Amẹrika lati ka nipa iroyin fun oye imọ ijinlẹ keji.
Nigba to pada de, o sisẹ pẹlu Daily Times, to si di ọkan lara ọga agba wọn.
Doyin tun lọ si fasiti New York nibi to ti gba oye imọ PhD ninu eto ibanisọrọ ati imọ oṣelu lọdun1979.
Lẹyin to gba Ph.D, o pada si Daily Times, to si ni anfaani lati sisẹ pẹlu eekan ninu iṣẹ iroyin bii Stanley Macebuh, Dele Giwa ati Amma Ogan. Ko duro fun igba pipẹ ti Ileeṣẹ iwe iroyin National Concord fi ransẹ pe ko wa di ọga agba fun ileeṣẹ naa ni ọdun 1986.
Eyi lo fun ni anfaani lati di obinrin akọkọ ti yoo di ipo ọga agba fun ileeṣẹ iroyin mu ni ọdun 1986.
Ọdun 1981 lo ṣe igbeyawo pẹlu oloogbe Moshood Abiola.















