Ẹlẹ́rìí rojọ́ tako agbẹ̀ tó fi adélébọ̀ obìnrin méjì bọ́ ẹlẹ́dẹ̀ rẹ̀ nítorí mílìíkì

Oríṣun àwòrán, Makgato Family
Ọkunrin alawọ funfun ọmọ orilẹede South Africa kan, Adrian de Wet, ti wọn fi ẹsun ipaniyan kan, ti ṣalaye pe ko wu oun lati fi oku awọn obinrin meji ti oun n jẹjọ iku wọn fun ẹlẹdẹ jẹ.
Gẹgẹ bi awọn agbẹjọro ṣe wi, ipa ni wọn fi mu Adrian de Wet to n jẹjọ ipaniyan lati fi oku awọn obinrin naa fun ẹlẹdẹ jẹ.
Adrian de Wet jẹ ọkan lara awọn ọkunrin mẹta to n jẹjọ ipaniyan, lẹyin ti wọn ni awọn obinrin meji, Maria Makgato ati Lucia Ndlovu, pade iku ojiji nibi ti wọn wa ounjẹ lọ.
Oko kan to wa nitosi Polokwane, lapa Ariwa Limpopo, ni South Africa ni awọn obinrin meji naa ti pade iku lọdun to kọja.
Ẹni ọdun marundinlaadọta (45) ni Maria, nigba ti Lucia jẹ ẹni ọdun mẹtalelọgbọn( 34).
Inu oko ti wọn wa ounjẹ lọ naa ni iroyin sọ pe wọn pa wọn si, wọn si pada ri ajẹku oku wọn ti ẹlẹdẹ ti jẹ.
Lati bo aṣiri iku naa la gbọ pe wọn ṣe ju awọn oku naa fun ẹlẹdẹ jẹ.
Ọkọ Lucia, Mabutho Ncube, ni ori ko yọ ninu iṣẹlẹ ọjọ naa, bo tilẹ jẹ pe ibọn ba a.
O raaye rakoro jade, to si rọju pe dokita fun iranlọwọ.
Ọgbẹni Mabutho ṣalaye pe oun fi iṣẹlẹ ọhun to ọlọpaa leti, ti awọn ọlọpaa si ba iyoku ara iyawo oun ati Arabinrin Makgato to ti n jẹra, ninu ile awọn ẹlẹdẹ lẹyin ọjọ diẹ.
Awọn eeyan naa ni iroyin sọ pe wọn lọ sinu oko ọhun lati wa ounjẹ lara awọn ẹru ounjẹ ti ọjọ ti lọ lori wọn tabi to ku diẹ. Ọpọ igba ni wọn ma n ko wọn da sita ni oko naa, ti wọn si ma n fi wọn bọ ẹlẹdẹ.
''Ẹni tó ni oko ló yìnbọn pa wọ́n''

Oríṣun àwòrán, Nomsa Maseko/BBC
Ninu alaye ti De Wet, ẹni ogun ọdun ṣe fun kootu lọjọ Aje, lo ti ni ẹni to ni oko naa lo yinbọn pa awọn obinrin meji ọhun.
De Wet to ti di ẹlẹrii ijọba bayii, ṣalaye pe Zachariah Johannes Olivier, ni ẹni to ni oko naa, o ni oun naa lo yinbọn pa Maria ati Lucia.
Iṣẹ alabojuto ẹlẹdẹ ni De Wet n ṣe loko naa, o si ṣalaye pe awọn miliiki ti ko ni i pẹẹ bajẹ mọ tawọn tọju fun awọn ẹlẹdẹ lati mu ni awọn obinrin naa n wa nibẹ ti oloko fi yinbọn mọ wọn.
O ni lẹyin iku awọn mejeeji ni Zachariah to yinbọn pa wọn paṣẹ pe, ki oun ju oku wọn fun ẹlẹdẹ.
"Bi ẹlẹdẹ ba fi wọn jẹ tan pata, ko sẹni ti yoo ri oku wọn, aṣiri ọna ti wọn gba di awati ko si ni i tu saye ni ero Zachariah."
Àwọn olùjẹ́jọ́ méjì yókù wà ní gbaga

Zachariah Johannes Olivier, ẹni ọgọta ọdun (60) to ni oko naa pẹlu alabojuto keji, William Musora; ẹni aadọta ọdun (50) ko ti i rojọ ni kootu.
Atimọle ni awọn mejeeji ṣi wa lori ẹsun ipaniyan ti wọn wọn fi kan wọn.
Bakan naa ni awọn mejeeji pẹlu De Wet yoo tun jẹjọ igbiyanju lati pa eeyan.
Ile ẹjọ sọ pe wọn yoo jẹjọ yii latari ibọn ti wọn yin fun ọkọ Lucia ti oun naa wa loko ẹlẹdẹ ọhun pẹlu awọn obinrin meji to d'oloogbe.
Wọn yoo tun jẹjọ lori nnkan ija ti wọn ni lọwọ lai gba aṣẹ, ati bi wọn ṣe da oju ọrọ ru nipa jiju awọn oku naa fun ẹlẹdẹ jẹ.
Ni ti Musora, ọmọ orilẹede Zimbabwe ni.
Wọn ni yoo jẹjọ nipa bo ṣe wa ni South Africa lai gba ọna to tọ wọle labẹ ofin.
Fọfọ ni ile ẹjọ giga Limpopo to gbọ ẹjọ naa kun fun ẹbi awọn ti ọrọ kan, bẹẹ ni awọn ajafẹtọọ ọmọniyan to ti ni ki wọn ti oko ẹlẹdẹ naa pa wa nibẹ pẹlu.
Igbẹjọ mi-in di ọsẹ to n bọ.
Iroyin iṣẹlẹ yii ti gba gbogbo South Africa kan.
Ọpọ eeyan lo n sọ pe lẹyin ọdun gbọọrọ ti ẹlẹyamẹya 'Apartheid' ti pari, awọn kan ṣi n huwa idẹyẹsi si alawọ dudu niluu naa.
Ohun ti a gbọ pe o n fa eyi ju ni pe awọn alawọ funfun ti ko to nnkan lo n ṣakoso awọn ilẹ oko, nigba ti ọpọ awọn to n ṣiṣẹ fun wọn jẹ alawọ dudu.
Wọn ki i sanwo gidi fun awọn oṣiṣẹ alawọ dudu naa, eyi to maa n fa ki awọn eeyan dudu naa binu, ti awọn alawọ funfun yoo si maa ṣaroye pe iwa ibajẹ n pọ si.














