Kókó ohun mẹ́fà pàtàkì nípa òfin adójútòfò tí Ààrẹ Tinubu ṣẹ̀ṣẹ̀ buwọ́lù

Aworan Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọjọ Iṣegun, ọjọ karun un, oṣu Kẹjọ, ọdun 2025 ni Aarẹ Bola Tinubu buwọlu aba ofin to ni ṣe pẹlu eto adojutofo faraalu, Nigerian Insurance Industry Reform Bill (NIIRA) 2025.

Bayo Onanuga, to jẹ agbẹnusọ Aarẹ Tinubu lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan.

Ofin NIIRA yii ni ọpọ awọn onimọ ti juwe gẹgẹ bii ipele ati aṣẹyọri pataki ninu ẹka adojutofo ni Naijiria.

Afojusun ijọba Tinubu ni lati pa tiriliọnu kan dọla wọlé sapo ijọba látí ipasẹ òfin adójútòfò

Ofin ọhun lo ṣe atunṣe si awọn eto adojutofo atẹyinwa ni Naijiria, paapaa ti ọdun 2023.

Gẹgẹ bii ọrọ Tinubu ti Onanuga fi lede, ofin naa yoo ṣe akoso awọn oniṣowo adojutofo ni Naijiria.

Eyii to ṣe pataki julọ nibẹ ni pe Tinubu sọ pe o jẹ ọkan lara awọn ọna lati ṣaṣeyọri ninu afojusun ijọba oun lati mu owo ti iye rẹ to tiriliọnu kan dọla wa sinu owo ti ijọba apapa n pa wọle.

Aarẹ ti wa paṣẹ fun ajọ to n bojuto ẹka adojutofo ni Najiria, National Insurance Commission (NAICOM) lati bẹrẹ amulo ohun to wa ninu ofin NIRA 2025 naa ki iṣẹ le bẹrẹ ni kankan.

Iwọnyii ni awọn ohun mẹfa to yẹ ki o mọ nipa ofin NIRA 2025 yii

Ohun to yẹ ki o mọ nipa ofin yii

  • Gbogbo awọn ileeṣẹ ti yoo maa pese eto adojutofo gbọdọ ni owo gọbọi lọwọ ki wọn to bẹrẹ eto wọn
  • Eto adojutofo ti di dandan lọna ati daabo bo ẹtọ araalu
  • Gbogbo ohun to ni ṣe pẹlu eto adojutofo gbọdọ wa lori ẹrọ ayarabiiaṣa ki iṣẹ rẹ le maa ya ati lati fun araalu lanfani lati le mọ ohun to yẹ ki wọn mọ nipa rẹ lai si magomago kankan
  • Ofin tuntun yii tun sọ pe awọn ileeṣẹ adojutofo gbọdọ san owo to yẹ fun ẹni to ba tọ si tabi ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe ni kankan, lai fi akoko ṣofo
  • Awọn ọmọ Naijiria yo le janfani eto adojutofo lawọn orilẹede to yi Naijiira ka, to fi mọ eto ECOWAS Brown Card System
  • Awọn araalu yoo janfani ninu owo ti ijọba ya sọtọ lati daabo bo eto adojutofo naa

Alaye nipa eto adojutofo ni Naijiria

Ṣaaju ofin tuntun yii, iroyin ni ko to ida kan ọmọ Naijiria to ni anfani si eto adojutofo, eyii to jẹ ọkan lara eyii to kere julọ nilẹ adulawọ.

To n tumọ si pe awọn ọmọ orilẹede Kenya ati South Africa ni anfani si eton aa ju awọn ọmọ Naijiria lọ.

Ni South Africa, ida 13.7% awọn araalu lo ni anfani si eto adojutofo nigba ti ida 2.14% awọn ọmọ Kenya pere n janfa ni eto adojutofo.