Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí tó jí ìkókó ní Ekiti, wọn rí ọmọ tuntun náà gbà padà

Iléeṣẹ́ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti ṣe awari ọmọ ikoko ti wọn ji gbe salọ nile iwosan alabọde to wa nilu Ado.
Ṣáájú ni a ti mú ìròyìn wá fún yín nípa bí ìkókó náà, tí wọn bí ní ọjọ́ Àìkú ṣe di àwátì.
Àmọ́ ìwádìí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ekiti nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti so eso rere pẹlu bi wọn ṣe rí ọmọ tuntun tó sọnù náà gbà padà.
Bákan náà, ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ti tẹ afurasí tí wọn lo jí ọmọ náà gbe lọ.

"Ààyè ni ọmọ ikoko naa wa, a ti fi kele ofin gbe arabinrin to ṣiṣẹ laabi ọhun"
Kọmísánà fún ile iṣẹ ọlọpaa ni ìpínlẹ̀ Ekiti, Joseph Eribo, lo fidi iroyin naa mulẹ fun Akọroyin BBC News Yoruba.
O ni, "Aaye ni ọmọ ikoko naa wa nigba ti a doola rẹ.
Bákan naa ni a ti fi kele ofin gbe arabinrin to ṣiṣẹ laabi ọhun.
Kódà, obinrin naa jẹwọ fún àwa ọlọ́pàá ìdí tó ṣe jí ọmọ tuntun jòjòló náà gbe."
Bí àṣírí afurasí Ajọ́mọgbé náà ṣe tú rèé - Kọmísánà Ọlọ́pàá
Kọmísánà Ọlọ́pàá ní Deborah Ayeni ni orúkọ arabinrin afurasi ajọmọgbe náà, to si jẹ ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn, to si pa irọ pé òun lóyún.
O ṣàlàyé pé ọwọ ọlọ́pàá tẹ obìnrin náà nígbà tó gbàgbé baagi rẹ sílè ìwòsàn èyí tí risiti to fi ra oogun wa ninu rẹ.
Tún wẹ, ẹ̀rọ tó ń ká àwòrán silẹ, CCTV, àti alaye ẹnikan nípa obìnrin náà, lo tètè jẹ ki wọn rí mú.
"Oyún tí mo ní ti bajẹ, n kò sì fẹ́ kí ọkọ mi tó wà lókè òkun mọ pe oyún náà tí bajẹ, lo mú kí òun da bíi ọgbọ́n"
Lásìkò to ń ṣàlàyé ìdí tó ṣe jí ọmọ gbé, arábìnrin Ayeni ní lóòótọ́ ni òun jí ọmọ ọhun gbé.
O ni oyún tí òun ní ti bajẹ, tí òun kò sì fẹ́ kí ọkọ òun tó wà lókè òkun mọ pe oyún náà tí bajẹ lo mú kí òun da bíi ọgbọ́n.
"Mo dinbọn bi alaboyun pẹlu kiko aṣọ si ikun lọ sílé ìwòsàn, ki n lee raye ṣiṣẹ ibi naa.
Lasiko ti iya ọmọ naa lọ si baluwẹ láti wẹ, ti baba rẹ naa lọ si Mọsalasi, ní mo rí ààyè gbé ọmọ tuntun náà salọ."
Kọmisọna ọlọpaa ti paṣẹ kí wọn ti arabinrin naa mọle, ki ìgbésẹ̀ iwadi lee tẹsiwaju.

Bawo ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe rí lára àwọn òbí ọmọ tuntun náà?
Ṣáájú ní a ti mú ìròyìn wa fún yín pé ori iporuru ọkan ni awon obi ọmọ ikoko ti wọn ji gbe salọ nile iwosan alaboode to wa ni adugbo Okeyinmi nilu Ado Ekiti wa.
Akọroyin BBC News Yoruba kan sí tọkọ tiyawo to jẹ obi ọmọ naa, ni ilegbe wọn nilu Ado Ekiti, lati mọ bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe waye.
Baba ikoko naa, Mustapha Ali, salaye wipe owurọ ọjọ Aiku, tii se ọjọ kẹta Osu Kẹjọ ọdun 2025 ni iyawo oun bi ọmọ tuntun ọkunrin sile iwosan alabọde naa.
"Mo sakiyesi obinrin alaboyun kan nile iwosan to wa joko ti Ìyàwó mi , to si n saajo rẹ amọ a ko mọ ri rara"
Mustapha ni, nigba ti oun de ile iwosan, oun sakiyesi obinrin alaboyun kan to wa joko ti Iyawo oun, to si n saajo wọn sugbọn wọn ko mọọ ri rara.
O tẹsiwaju ninu alaye rẹ pe obinrin naa sun si lle iwosan naa titi di idaji ọjọ Aje, Ọjọ Kẹrin Oṣù Kẹjọ ọdun 2025, to si sọ fun wọn wipe ọmọ loun naa wa bi nibẹ.
Mustapha sọ pé 'O gbe ọmọ mi dani nigba ti iyawo mi wa lori ibusun, iyawo mi ko lee sọ ede Yoruba rara'.
'Ọmọ bIbI ipinlẹ Benue ni awa mejeeji'.
O juwe obinrin ajoji naa bii ẹni to dudu to si ga diẹ.
"Nigba ti asiko Irun kiki idaji to lọwọ aago marun-un abọ, mo lọ sí Mọsalasi lati kirun, sugbọn n kò ri ọmọ ikoko naa mọ nigbati mo pada de".
"Asiko ti mo wọ inu baluwẹ obinrin yii ji ọmọ mi gbe"
Iya ọmọ ikoko naa, Palmata Lawal, salaye wipe lasiko ti oun lọ si ibaluwẹ ni obinrin ajoji naa ji ọmọ oun gbe salọ.
Mustapha sọ wipe 'Ojojumọ ni emi ati iyawo ni fi n sun ẹkun latigba ti ọrọ naa ti ṣẹlẹ tori pe ibanujẹ lo jẹ fun wa'.
Ọ̀kan lara awọn ọrẹ iya ikoko naa, Mariam Mukaila, salaye fun BBC News Yoruba wipe Ọkunrin ni ọmọ ikoko náà, wọn sí jii gbe lai tíì pé wakati mẹ́rìnlélógún ti wọn bii.
Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá mú afurasi mẹ́rin láti ṣe ìwádìí bí ìkókó ṣe di àwátì
Sunday Abutu, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ti ipinlẹ Ekiti sọ wipe ọwọ ofin ti tẹ awọn afurasi mẹrin kan lori iṣẹlẹ naa.
Àwọn mẹrẹẹrin ti ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni oṣiṣẹ to n sọ ẹnu ọ̀nà ile iwosan naa, osise to n tun ayika ile iwosan ṣe ati Nọọsi meji.
Ọlọpaa ni iwadi ti gberasọ lori iṣẹlẹ naa lati ṣe awari ìkókó ti wọn ji gbe naa.















