Mínísítà méjì àti èèyàn mẹ́fà mí-ìn kú nínú ìjàm̀bá ọkọ̀ òfurufú ní Ghana

Oríṣun àwòrán, DR OMANE BOAMAH/MURTALA MOHAMMED/FACEBOOK
Awon minisita meji gboogi ninu ijoba orílẹ̀ ede Ghana pelu awon osise ijoba mefa mi-in ni won padanu emi won loni ninu ijamba oko ofurufu agberapa kan lorileede naa.
Dokita Omaneh Boamah, minisita eto aabo ati Dokita Ibrahim Murtala Mohammed, minisita eto ayika ni won jade laye pelu awon eeyan mefa náà.
Olori osise ni Ghana, Julius Debrah lo kede isele naa.
Gege bo se wi, yàto sí àwọn minisita meji yìí, awon mi-in to tun
jade laye ninu ijamba naa ni:
- Dr Muniru Mohammed Limuna.
- Dr Samuel Sarpong.
- Samuel Aboagye.
- Squadron Leader Peter Bafemi Anala
- Flying Officer Twum Ampadu ati
- Sergeant Ernest Addo Mensah.
Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀?

Oríṣun àwòrán, GHANA AIR FORCE/FACEBOOK
Ninu alaye ileese ologun ile Ghana, GAF, won ni ọkọ̀ agberapa Z9 to n lọ si ẹkun Ashante naa ti figba kan poora, nígbà to kuro loju ona re.
Atejade GAF sọ pe nnkan bii aago mẹsan - an kọjá iseju mejila ni baaluu naa gbera lati Accra, Obuasi ni won ni o n lọ to fi poora.
Kaputeeni Veronica Adzo Arhin to je agbenuso fun ileese ologun Ghana, kede pe osise ọkọ naa meta ati ero ọkọ márùn-ún lo wa ninu re nigba to gbera ni Accra.
Alaye awon o soju mi koro lori ijamba naa ni pe ọkọ agberapa naa gbina ni.
Won fi kún un pé o jona koja idanimọ.
Ibi eto kan ti yoo gbogun ti awon ti won n wa kusa lona aitọ, eyi to n fa wàhálà fun awon odo ati igbo ọba ni awon eeyan to di olóògbé naa n lọ ki wọn too pade iku ojiji.
Iṣẹlẹ ijamba ọkọ ofurufu to ti ṣẹlẹ̀ koja
Losu Kefa odun 2012, ọkọ ofurufu Naijiria kan ja lule ni Gbana, èèyàn mewaa lo ku, o kere tan.
Losu Kefa odun 2020, ọkọ ofurufu ologun kan bale lojiji ni Ganvuliga, ni ekun Kumbungu, eyi ko pa enikeni.
Lojo kokandinlogun osu Keta odun 2019, oko ofurufu ologun kan tun jabo ni agbègbè Ahanta, ni Ghana.
Eeyan mokanlelogun lo wa ninu oko naa, won sare gbe awon to farapa lo sile iwosan., won si doola awon kan.















