Sowore gba ìtúsílẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ méjì ní àtìmọ́lé ọlọ́pàá

Omoyele Sowore

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore

Àkọlé àwòrán, Sowore fẹsun kan awọn ọlọpaa pe wọn ji gilaasi olowo iyebiye RayBan owun
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Akọrin to tun jẹ ajafẹtọọmọniyan, Omoyele Sowore ti jade kuro ni atimọlẹ ọlọpaa lẹyin to ti lo ọjọ meji nibẹ.

Ninu fidio kan to fi lede loju opo Facebook rẹ, ajafẹtọọmọniyan naa, to tun jẹ oludasilẹ ileeṣẹ iroyin Sahara Reporters fi ẹmi imoore han si awọn ololiufẹ rẹ fun aduroti wọn lasiko atimọle rẹ.

Nigba to n sọrọ, o ni "ileeṣẹ ọlọpaa ti juwọ silẹ fun ijijagbara ayipada wa, wọn ti tu mi silẹ kuro ni ahamọ wọn eyii ti ko ba ofin mu.

"Bo tilẹ jẹ kii ṣe ohun to yẹ ki a maa ṣajọyọ le lori, mo dupẹ lọwọ yin ti ẹ ko sọ ireti nu."

Ṣaaju akoko yii ni ọlọpaa ti mu Sowore ni aimoye igba lori ijijagbara rẹ eyii to fi n pe fun ayipada ninu eto oṣelu ati ọrọ aje Naijiria.

Atimọle ti wọn fi si kẹyin yii ni ọpọ araalu atawọn ajafẹtọọmọniyan koro oku si.

Sowore ti dupẹ lọwọ awọn eeyan jankan-jankan niluu fun atilẹyin wọn lasiko to wa latimọle ọlọpaa.

Gbas-gbos laarin Sowore ati ileeṣẹ ọlọpaa

Wahala Sowore pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa bẹrẹ lọtẹ yii lẹyin to fẹsun kan ọga agba ileeṣẹ naa, Kayode Egbetokun pe asiko rẹ ti to lati fẹyintin lẹnu iṣẹ amọ to kọ lati fi iṣẹ silẹ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Akọroyin naa tun fi oniruru ẹsun kan ileeṣẹ ọlọpaa bii ifiyajẹ araalu lọna aitọ, titẹ ẹtọ araalu loju mọlẹ, gbigba riba, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Asiko ti awọn ọlọpaa jale agbọn Sowore ni igba ti ẹnikan ji gilaasi olowo iyebiye Rayban rẹ lasiko iwọde kan to ṣe niluu Abuja, ninu eyii to fi n ke si awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa pe ki wọn maa tọju ọlọpaa daadaa.

Asiko ti iwọde naa n lọ lọwọ ni ọkunrin kan to wọ aṣọ funfun ni iha ti awọn ọlọpaa duro yọ gilaasi naa loju rẹ.

Iṣẹlẹ ọhun mu ki Sowore fẹsun kan awọn alaṣẹ ọlọpaa pe awọn lo ran ọkunrin niṣẹ lati ji gilaasi ọhun, amọ titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, ọlọpaa ko sọ nnkankan nipa gilassi naa bẹẹ ni ko fi ṣikun ofun mu ọkunrin to yọ gilaasi ọhun loju Sowore.

Lẹyin naa ni Sowore bẹrẹ si n sọrọ kobakungbe si awọn ọga ọlọpaa ki wọn to fi iwe pe e ti wọn si tii mọ ahamọ.

Ninu atimọlẹ ọhun, a gbọ pe awọn ọlọpaa lu u niluu bara ti wọn si kan ọwọ rẹ amọ ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe ko si ootọtọ ninu iroyin naa.

Ẹwẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejobi ti sọ pe eredi ti awọn fi mu Sowore ko ṣẹyin awọn ẹsun ti wọn fi kan an bii iwe yiyi, idunkokomọni lori ayelujara atawọn ẹsun mii eyii ti iwadii rẹ ṣi n lọ lọwọ.

Adejobi tun sọ pe awọn ko lu Sowore ni atimọle ati pe awọn ko tẹ ẹtọ rẹ loju mọlẹ latari bi wọn ṣe tu silẹ lẹyin ọjọ ni atimọle gẹgẹ bii ofin ṣe ṣagbekalẹ rẹ.

Ẹ̀ṣẹ̀ wo ló tún gbé Sowore dé àhámọ́ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lọ́tẹ̀ yìí?

Omoyele Sowore

Oríṣun àwòrán, Other

Àkọlé àwòrán, Oṣu Kinni ọdun 2025 ni Adajọ Musa Liman, ti kọkọ fi anfaani beeli silẹ fun Sowore, pẹlu alaye pe oniduuro rẹ naa gbọdọ jẹ ọmọluabi.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti oludije sipo aarẹ nigba kan, ẹni to tun jẹ ajafẹtọ ọmọniyan, Omoyele Sowore, yoo dero ahamọ ileeṣẹ ọlọpaa lori ẹsun kan tabi omiran.

Omoyele Sowore ni ọwọ tun tẹ lanaa ode yii niluu Abuja.

Agbẹjọro rẹ, Marshal Abubakar sọ fun BBC pe ẹsun iwa ọdaran ati yiyi iwe ọlọpaa ni wọn fi kan an lasiko yii.

Saaju ki ileeṣẹ ọlọpaa to fi Sowore si ahamọ lo ti kọkọ jẹ ipe wọn niluu Abuja pẹlu agbẹjọro ati awọn alatilẹyin rẹ.

Ninu fọnran to bọ sori ayelujara, Sowore ni a ri to di ẹru dani bi ẹni to ti mọ pe oun yoo dero ahamọ lẹyin to jẹ ipe ileeṣẹ ọlọpaa.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Olumuyiwa Adejobi ko ti sọrọ nipa eyi nigba ti akọroyin BBC kan si i.

Kí ni Sowore ṣe?

Lati ọdun to kọja ni Sowore ti n fẹsun kan ọga ọlọpaa Kayode Egbetokun pe ọna to gba de ipo ọga ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, jẹ ayederu.

Lọdun to kọja bakan naa ni Ileeṣẹ ọlọpaa fẹsun kan Sowore pe o gbe fọto Egbetokun soju opo X rẹ, to si pe e ni "alaikoju oṣuwọn ati jẹgudujẹra".

Wọn lo tun lo kọ ọ sibẹ pe orilẹede ti awọn ti ko niwa ba n dari rẹ ko le ni ilọsiwaju.

Awọn ọlọpaa tun sọ pe Sowore kọ ọ soju opo X rẹ, pe ''Ọga ọlọpaa Egbetokun ni yoo ba Naijiria jẹ bi a ko ba tete gbe igbesẹ bayii."

Ọrọ naa di ti ile ẹjọ niluu Abuja, amọ lẹyin to ni ohun ko jẹbi awọn ẹsun wọnyii ni adajọ sun igbẹjọ naa siwaju.

Ẹgbẹ AAC fohun sita….

Ẹgbẹ oṣelu The African Action Congress (AAC) to jẹ ẹgbẹ ti Omoyele Sowore wa, ti bu ẹnu atẹlu igbesẹ ileeṣẹ ọlọpaa lati ti Olori ẹgbẹ naa mọ ahamọ lẹyin to yọju si olu ileeṣẹ ọlọpaa niluu Abuja

Gbogbo ẹbi ni ẹgbẹ oṣelu naa da le iṣejọba Aarẹ Bola Tinubu pe o yan ayederu Ọga fun ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, iyẹn Kayode Egbetokun.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ẹgbẹ AAC, Femi Adeyeye fi ransẹ si awọn akọroyin, o ni ohun ti Sowore n gbiyanju lati se ni lati tan imọlẹ si ohunkohun to n lọ ni ileeṣẹ ọlọpaa eyi to gbagbọ pe Ọga ọlọpaa Egbetokun ati awọn eeyan kan lo wa nidi rẹ.

"Nigba ti Sowore de si ileeṣẹ ọlọpaa ni ọjọ Kẹfa oṣu Kẹjọ ọdun 2025, wọn ko fun laaye lati mọ ẹni to kọwe ẹsun mọ tabi idi ti wọn fi ransẹ pe, eyi to jẹ ẹtọ rẹ labẹ ofin.

"Lẹsẹkẹsẹ ni awọn ọlọpaa bẹrẹ si ni dẹru ba pe awọn yoo fi si atimọle, ti wọn si tun kọlu agbẹjọro rẹ, ki wọn to gbe ọkọ wa lati wa gbe lọ.

"Iwadii wa fihan pe Ọga ọlọpaa funra rẹ lo kọwe tako Sowore. Iwa idojutini ni eyi ti ko ba ofin mu rara."

Bakan naa ni ẹgbẹ AAC n rọ gbogbo ọmọ orilẹede Naijiria lati gun le iwọde kaakiri orilẹede Naijiria titi Sowore yoo fi gba ominira.

Ki ni igbesẹ ile ẹjọ lori ọrọ yii tẹlẹ?

Ile ẹjọ giga kan ilu Abuja fi aaye beeli silẹ fun Omoyele Sowore, pẹlu miliọnu mẹwaa naira ati oniduuro kan niye kan naa.

Ẹsun to ni i ṣe pẹlu lilo ayelujara nilokulo ni wọn fi kan an.

Ọjọbọ, ọgbọnjọ oṣu Kinni ọdun 2025 ni Adajọ Musa Liman, fi anfaani beeli naa silẹ pẹlu alaye pe oniduuro naa gbọdọ jẹ ọmọluabi.

O fi kun un pe ẹni naa gbọdọ ni awọn ile lagbegbe kootu naa.

Ile ẹjọ faaye beeli naa silẹ lẹyin ti agbejọro Sowore, Marshall Abubakar, pe fun beeli rẹ.