Ẹ̀wọ̀n gbére tàbí ọdún mẹ́wàá ló tọ́ sí ẹni tó bá dá báàlùú dúró - Amòfin

Aworan ọkọ baaluu to wa loju ofurufu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gbajúmọ̀ amofin kan tó fi ìlú Ibadan ṣe ibùjókòó, Abimbola Orogade, tí sọ̀rọ̀ nípa ohun tí òfin Nàìjíríà sọ tí ẹnikẹ́ni bá fi tipátipá dá bàálù tó fẹ́ fò dúró.

Amofin Orogade ṣàlàyé ọ̀rọ̀ yìí lásìkò to ń bá BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ bí gbajúmọ̀ akọrin Fuji nni, Wasiu Ayinde Anifowose Marshal tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí KWAM I ṣe da bàálù to fẹ́ fò dúró.

Ọsan Ọjọ́ru ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ní pápákọ̀ òfurufú ni Abuja lásìkò tí KWAM I fẹ́ wọ bàálù wá sí ìlú Èkó.

Nígbà tó ń ṣàlàyé nípa ẹ̀ṣẹ̀ ti K1 ṣẹ àti òfin to de ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ náà, Amofin Orogade ní àwọn ìbéèrè kan wà, tó kọ́kọ́ yẹ káwọn èèyàn béèrè, ká tó lè mọ bóyá KWAM 1 nìkan ló dá ẹṣẹ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tàbí bẹẹ kọ.

"Báwo ni K1 ṣe gbé èròjà to jẹ omi wọ agbegbe ibi tí bàálù ń bá sí láì sí ẹni kankan tó dá a lọ́wọ́ kọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀?"

Amòfin Orogade ṣàlàyé pé

"Àkọ́kọ́ na, ṣe wọn ṣe ayẹwo fún Akọrin náà kò tó dé ibùdó tí àwọn bàálù ń bà sì, báwo ló ṣe dé ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí wáyé, ó yẹ ká kọ́kọ́ wo eléyìí náà.

Báwo ni K1 ṣe gbé èròjà to jẹ omi wọ agbegbe ibi tí bàálù ń bá sí láì sí ẹni kankan tó yẹ̀ ẹ́ lọ̀wọ̀ tàbí dá a lọ́wọ́ kọ́.

Òfin ètò irinna òfurufú kò fi ààyè gba ìwà báyìí, a gbọ pe wọn sọ fún pé kò gbé ike omi náà silẹ àmọ́ kò gbà.

Kò bàa jẹ omi lo wà nínú ike náà tàbí ọ̀tí lílé, òfin kò fi ààyè gba gbígbé irú nǹkan báyìí wọ̀ inú bàálù, KWAM I jẹbi titapa si ofin ètò irinna òfurufú.

Bákan náà ni àwọn òṣìṣẹ́ tó yẹ kó dá a dúró láti gbé èròjà ike náà dé agbegbe ti baalu ń ba si, tí wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀, náà lu òfin ìjọba."

Ìwé òfin Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Abimbola Orogade

"Ìjọba lé fi ẹ̀sùn ijinigbe kan akọrin náà, pé ó hùwà ìgbésùnmọ̀mí nípa gbígbé ìgbésẹ̀ láti jí àwọn èrò inú bàálù gbé"

Amofin Orogade wá tọkasi òfin to de eto irinna ofurufu tọdun 2022, abala kẹtalelọgbọn èyí tó ṣàlàyé àwọn ìjìyà to wa fún ẹnikẹ́ni to bá tàpá sí òfin irinna òfurufú.

" Ẹsẹ òfin náà ṣàlàyé pé ẹnikẹ́ni tó bá gbé Igbesẹ to takò tàbí to fẹ tako ààbò bàálù àti àwọn èrò inú rẹ bóyá lásìkò tí baalu ń gbéra láti fò ní tàbí nígbà tó ti fọ tán tàbí nígbà tó fẹ́ balẹ, ẹsẹ ńlá ni èyí.

A sì rí nínú fídíò tó lu orí ayélujára kan pé KWAM I dúró síwájú bàálù, tó sì ń di lọ́wọ́ láti fò, ó lu òfin náà, wọn sí lè gbé lọ sílé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn ìwà ìgbésùnmọ̀mí sì bàálù àtàwọn èrò inú rẹ.

Wọn lé fi ẹ̀sùn ijinigbe kan akọrin náà pẹlu, pé ó hùwà ìgbésùnmọ̀mí nípa gbígba ìyànjú láti jí àwọn èrò inú bàálù náà gbé.

Ìjìyà ńlá sì lọ rọ̀ mọ́ irú ẹ̀ṣẹ̀ yìí lábẹ́ òfin ètò irinna ọhun èyí tó tó ìjìyà ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá tàbí ẹ̀wọ̀n gbére kalẹ fun ẹni to bá lùgbàdì òfin náà.

Ìwà tí KWAM I hù ní pápákọ̀ òfurufú náà kìí ṣe àwàdà rárá, ẹsẹ ńlá ni."

"Awakọ̀ òfurufú náà lè fojú wina òfin lẹ́yìn ti wọn dá dúró fún oṣù mẹ́fà tóri o jẹ ki ìbínú ru bo o lójú lásìkò tó wà ní ẹnu isẹ́"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Amofin Orogade tẹsiwaju pé òfin ìwà ọ̀daràn gbáà ni ìwà yìí tó bá jẹ́ pé ẹkùn gúúsù orílẹ̀ èdè yìí ló ti wáyé, ẹ̀wọ̀n ọdún meji sì ni lábẹ́ òfin ìwà ọ̀daràn, Criminal Codes.

Àmọ́ torí pé ẹkùn àríwá Naijiria ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tí wáyé, òfin ìhùwàsí ẹ̀dá, Penal Codes, abala ofin 472 si lo de e, ẹ̀wọ̀n ọdún méjì péré ni."

Amofin Orogade ni ajọ to ń rí sì ètò irinna òfurufú yóò gbé ìgbésẹ̀ òfin lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí èyí tó ti bẹ̀rẹ̀ pẹlu ìjìyà oṣù mẹ́fà tó fún KWAM I pé kò gbọ́dọ̀ fò làwọn pápákọ̀ òfurufú tó wà ní Nàìjíríà.

Nígbà tó ń mẹ́nuba ìhùwàsí àwọn òṣìṣẹ́ pápákọ̀ òfurufú Abuja lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, Amofin Orogade ni pẹlu fídíò to wa lori ayélujára, a rí pé ìhùwàsí awakọ̀ bàálù to yẹ kó gbé KWAM 1 àtàwọn òṣìṣẹ́ yoku to wa ní pápákọ̀ òfurufú lásìkò náà, kù díẹ̀ kaato.

" Ní gbogbo isẹ aáyán láàyò, ofin wa to de ìhùwàsí oṣiṣẹ kọ̀ọ̀kan, kódà, to bá rí ohunkóhun tó ń bí i nínú.

Awakọ̀ òfurufú náà lè fojú wina òfin lẹ́yìn ti wọn dá dúró fún oṣù mẹ́fà tóri o jẹ ki ìbínú ru bo o lójú lásìkò tó wà ní ẹnu isẹ́.

Irú ipò wo ni ìrònú rẹ yóò wa lásìkò tó fi ìbínú gbéra pẹlu bàálù náà? Irú ipò wo sì ni ọkàn rẹ wà, tó fi wá baalu naa lati ilu Abuja dé Eko?

Èrò mẹtalelaadọrin lo wa ninu bàálù náà, èyí tó ń kó láti Abuja bọ̀ wá sí Eko, ó fihan gbangba pé ọkàn rẹ poruru lásìkò to ń wa baalu naa fun wákàtí kan gbáko èyí to léwu fún ààbò ẹmi rẹ̀ àtàwọn èrò tó gbé."

"Lásìkò yìí tí ìwà ìgbésùnmọ̀mí, ijinigbe àtàwọn agbébọn gogò yíká orílẹ̀èdè yìí, o yẹ kí ìjọba fi KWAM I jofin láti fa àwọn èèyàn bíi tiẹ̀ létí"

Amofin náà wà sọ pé ó yẹ kí ìwádìí abẹle wà ní iléeṣẹ́ bàálù tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tí wáyé, kí àkóso àti ìlànà sì wà, tó yẹ kí awakọ̀ bàálù máa tẹle.

Bákan náà, ó ní lásìkò yìí tí ìwà ìgbésùnmọ̀mí, ijinigbe àtàwọn agbébọn gogò yíká orílẹ̀èdè yìí, o yẹ kí ìjọba ilẹ̀ wa fi àwọn tó bá lu òfin nínú ìṣẹ̀lẹ̀ KWAM I yìí jofin láti fa àwọn èèyàn yókù, to lè fẹ́ hu irú ìwà yìí lọ́jọ́ iwájú jofin, bí bẹẹ kọ, ọ̀pọ̀ èèyàn miran ní yóò fẹ́ hu ìwà tí Wasiu Ayinde hu yìí.

Òfin kan náà lọ dé eto irinna jákèjádò agbaye, torí náà, tí orílẹ̀ èdè yìí kò sì gbọ́dọ̀ yatọ, kódà, a gbọ́dọ̀ ṣe àtúnṣe gidi sì òfin tó dé ẹka ètò irinna òfurufú.