Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí WAEC ṣí ojú òpó èsì ìdánwò 2025 padà

Oríṣun àwòrán, Olukayode Jaiyeola/NurPhoto via Getty Images
Igbimọ idanwo iwọ-oorun Afirika (WAEC) ti kede pe ẹnu-ọna esi fun danwo ile-ẹkọ giga ti Iwọ-oorun Afirika ti ọdun 2025 (WASSCE) ti o yọkuro nitori aṣiṣe imọ-ẹrọ ti ṣii pada fun awọn akẹkọọ lati wo esi idanwo wọn .
Gẹgẹ bii WAEC se sọ, awọn akẹkọọ ti le yẹ esi idanwo wọn lati mọ nnkan ti wọn gba.
Ṣaaju ni ajọ idanwo naa kede pe awọn n ṣe iwadii lori kudiẹ kudiẹ imọ-ẹrọ to waye lẹyin ti wọn kọkọ oju opo esi idanwo naa sita.
Waec ko kọkọ faye gba awọn akẹkọọ lati yẹ esi idanwo wọn wo lori oju opo ayelujara wọn.
Ẹwẹ, Waec ti tọrọ aforojin lọwọ awọn ọmọ Naijiria fun iṣẹlẹ yii.
"Oju opo esi idanwo ti si pada, awọn akẹkọọ ti ni anfani lati tun esi idanwo wọn yẹwo.
"Lẹẹkan sii, a tọrọ aforijin fun eyi, ti a si dupẹ lọwọ awọn araalu fun atileyin wọ." Waec sọ loju opo ayelujara X lọjọ Ẹti.
Ki lo yii pada?
Lẹyin ikede Waec pe awọn ti si oju opo esi idanwo fun awọn akẹkọọ lati yẹ esi idanwo wọn wo.
Awọn akẹkọọ kan ni esi idanwo ti awọn wọn tẹlẹ naa lo si n gbe sta fun wọn, ti awọn akẹkọọ mii si ni esi idanwo wọn yi pada lẹyin ti Waec se atunṣe.
Akẹkọọ kan fi aworan esi idanwo rẹ soju opo ayelujara, ti oju opo naa si n sọ fun pe asise wa lori esi rẹ.
Akẹkọọ mii to fesi fun Waec loju opo X ni oun ko ri esi idanwo oun wo rara.
Ọpọ awọn akẹkọọ lo tig be sita lati fẹhonu wọn han sita, ti kaadi ayẹwo wọn ko si gba wọn laye mọ lati wo esi idanwo naa.
Bi awọn se ni awọn ko ri esi idanwo yẹ wo ni awọn mii n se afihan ayipada esi idanwo wọn .
Akẹkọọ kan ni fẹhonuhan pe ayipada ko de ba esi idanwo Ede Gẹẹsi rẹ, to si jẹ pe oun lo nilo lati wọ ile ẹkọ giga.
"Ko si nnkan to yipada, Ede Gẹẹsi mi si w ani D7, kaadi mi o siṣẹ mọ. Ẹjọ, wọn ti pe mi fun ayẹwo ni ile ẹkọ giga awọn nọọsi, Ede Gẹẹsi yii lo n da mi duro. Nk le lọ pẹlu maaki D7," o sọ loju opo X.
Ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo tib u ẹnu atẹlu Waec lori eyi, ti wọn si ni ko yẹ irufẹ eyi tun waye lẹyin ọpọlọpọ akoko ti wọn se lati mojuto esi idanwo.

Oríṣun àwòrán, X screenshot
Ìdí rèé tí a ṣe tí ojú òpó àyẹ̀wò èsì ìdánwò wa pa - WAEC ṣàlàyé

Oríṣun àwòrán, WAEC/X
Ajọ WAEC ti kede pe awọn ti bẹrẹ iwadii si iṣẹlẹ to ṣẹlẹ si oju opo ayelujara wọn eyi ti ko fun awọn akẹkọọ ni anfani lati yẹ esi idanwo wọn wo.
Atẹjade yii lo jade loju opo ayelujara X ni WAEC ti ni awọn ṣawari awọn kudiẹkudiẹ kan ṣugbọn iwadii ti bẹrẹ lati wa ojutu si.
Igbesẹ yii jẹyọ lẹyin ti awọn akẹkọọ to kopa ninu idanwo WAEC ke gbajari sita pe awọn ko ni anfani lati yẹ si idanwo wọn wo.
Nitori iwadii yii ni WAEC fi sọ kọkọrọ si ẹnu ọna abawọle oju opo naa fun igba diẹ, eyi ti yoo fun wọn akoko lati wa ojutu si iṣoro ti wọn n koju.
WAEC ni lẹyin igbesẹ yii, awọn akẹkọọ yoo ni anfani lati yẹ esi idanwo wọn wo lẹyin wakati mẹrinlelogun.
Ọjọ Aje, Ọjọ Kẹrin oṣu kẹjọ ọdun 2025 ni WAEC kede pe esi idanwo ọhun ti jade sita.

Oríṣun àwòrán, Pascal Deloche via Getty Images
Ìdánwò WAEC ọdun 2025 ló burú jùlọ láti ọdún márùn-un séyìn - Ẹ wo ìdí abájọ
"Esi idanwo 2025 yii ko fi bẹẹ mu ayọ wa fun ọpọ akẹkọọ to ṣe e"
Ọjọ Aje, ọjọ kẹrin oṣu Kẹjọ ọdun 2025 yii ni ajọ WAEC to n ri si idanwo oniwee mẹwaa, fi esi idanwo naa fun ti ọdun yii lede.
Esi idanwo 2025 yii ko fi bẹẹ mu ayọ wa fun ọpọ akẹkọọ to ṣe e ati awọn obi wọn.
Koda, bi a ba fi esi WAEC ọdun 2025 yii we awọn eyi to ti n jade lati ọdun marun-un sẹyin, eyi lo buru julọ.
Akẹ́kọ̀ọ́ mélòó ló ṣe ìdańwo naa, báwo ni wọ́n sì ṣe ṣe?
Akẹkọọ 1,973,365 lo fi orukọ silẹ fun idanwo WAEC ọdun 2025, wọn wa lati awọn ileewe girama ti ijọba fi ọwọ si ni Naijiria, ti onka wọn si jẹ 23,554.
Ṣugbọn akẹkọọ 1,969,313 lo pada jokoo ṣe idanwo naa, gẹgẹ bi ajọ WAEC ṣe sọ.
Onka awọn akẹkọọ ọkunrin to ṣe WAEC ọdun yii bi wọn ṣe wi jẹ 976,787, nigba ti awọn obinrin jẹ 992,526 .
Awọn to yege pẹlu iṣiro ati ede oyinbo ati awọn iṣẹ mẹta mi-in to fi jẹ marun-un, jẹ 754,545.
Ida 38.32% ni eyi si jẹ ninu onka ọgọrun-un.
Ọga Agba ajọ WAEC ni Naijiria, Amos Dangut, sọ pe awọn to yege ninu idanwo ọdun yii dinku ni ida 33.8, ti a ba fi we 72.12 to wọn ri ni 2024.
O ni awọn esi idanwo ida 22.94 kan ṣi wa tawọn n ṣiṣẹ le lori lọwọ.
Màgòmágò ìdánwò
Nigba to n ṣalaye nipa magomago to ṣee ṣe ko waye ninu idanwo WAEC ọdun yii, Amos Dangut sọ pe esi idanwo 192,089 ni ajọ naa ko ti i gbe jade latari magomago.
Ọga agba WAEC ni Naijiria naa sọ pe ida 9.75% ni eyi ninu awọn akẹkọọ to ṣe idanwo naa lọdun yii.
Dangut ṣo pe adinku ba onka yii ni ida 2.17, ti a ba fi we 11.92% magomago ti wọn ṣe akọsilẹ rẹ ninu idanwo 2024.
Èsì ìdánwò WAEC lati ọdún márùn-ún sẹ́yìn
Ni 2020, ida 65.24% lo yege idanwo naa pẹlu ede oyinbo ati iṣiro, gẹgẹ bi WAEC ṣe wi.
Ni 2021, o tun pọ si i. Awọn 81.7% lo yege awọn idanwo naa pẹlu iṣiro ati ede oyinbo.
Ni 2022, o dinku si ida 76.36% .
Ni 2023, ida 79.81% lo yege iṣiro ati ede oyinbo pẹlu awọn iṣẹ mi-in.
Adinku tun ba onka naa ni 2024, o ja si 72.12.
Ṣugbọn ni 2025 yii, o ja pata walẹ si 33.8%.
Kí ló fa ìkùnà yìí?
Ninu alaye to ṣe nipa idi ti awọn akẹkọọ fi fidi rẹmi bẹẹ ni WAEC ọdun 2025, olukọ agba kan ni Naijiria, Ọmọwe Harmony Mark-Ewa, ṣalaye fun BBC, pe ajọṣepọ to wa laarin ile ati ileewe kere ni.
Ọmọwe Harmony sọ pe iwoye oun ni pe:
"Ibaraẹnisọrọ laaarin ile ti awọn ọmọ ti wa, pẹlu ileewe ti wọn n lọ ko kun to, eyi si n ṣe akoba fun aṣeyori ẹkọ.
O ni o ṣee ṣe ko jẹ pe awọn obi ki i ṣe afikun ẹkọ ti awọn olukọ n kọ awọn ọmọ naa nile ẹkọ, o si le jẹ pe ti ile ni awọn olukọ ko ṣiṣẹ tọ.
Nipa ẹkọ ile, Mark-Ewa sọ pe ile ni ẹkọ ti bẹrẹ.O ni afikun ni ti ileewe.
Bakan naa lo ni ẹkọ wa nileewe naa, ti wọn yoo sọ di odidi bi wọn ba pada dele.
Ọmọwe Mark-Ewa fi kun un pe awọn obi mi-in maa n ran ọmọ niṣẹ ju, ti ọmọ naa ko si ni i raye lati kawe.
O ni ileewe ti wọn ti kuro ati ile ti wọn n pada si ko jọra wọn, eyi naa le fa ifasẹyin bo ṣe sọ.
Bi awọn akẹkọọ yoo ba bẹrẹ si i ṣe daadaa, Ọmọwe Mark-Ewa sọ pe ajọṣepọ gbọdọ wa laaarin awọn olukọ ati awọn obi.
Bí o ṣe lè wo èsì ìdánwò WAEC rẹ
Lọ si oju opo www. waecdirect.org .
O maa nilo kaadi WAEC ti wa a bo oju rẹ lati wọle soju opo naa.
Lọ si ẹka ti esi naa wa, ti i ṣe www.waecdirect.org.
Fi nọmba idanwo WAEC rẹ si i.
Mu iru idanwo ti o ṣe, fun apẹẹrẹ, ti May/June.
Mu ọdun ti o ṣe idanwo naa, fun apẹẹrẹ 2025.
Tẹ ẹ si ibi ti wọn kọ esi naa si, yoo gbe e jade fun ọ.












