Football market: Wo bó ṣe ń lọ lágbo káràkátà àwọn agbábọ́ọ́lù lọ́sẹ̀ yìí

Lionel Messi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Fun anfani gbogbo ololufẹ ere bọọlu, ti ẹ si fẹ mọ bo ṣe n lọ lagbo karakata awọn agbabọọlu kaakiri agbaye, a ti gbe ohun ti ẹ mọ n jẹ de.Lọwọlọwọ yii, ẹgbẹ agbabọọlu Paris St-Germain ti n gbero lati ra ẹlẹsẹayo ọmọ orilẹ-ede Portugal, Christiano Ronaldo lati Juventus, iyẹn to ba fẹ ni o.Bakan naa ni atamatase ọmọ ilẹ Argentina, Lionel Messi yoo tẹkọ leti lọ si Inter Miami l'Amẹrika, lẹyin to ba ti gba bọọlu fun saa meji tan ni Yuroopu.

Boya ẹ ti gbọ pe oju ikọ Chelsea ti wa lara agbabọọlu Bayern Munich, iyẹn Kingsley Coman lati fi rọpo Christian Pulisic, iyẹn to ba wu Comman lati lọ si Stamford Bridge.Ko tan sibẹ, Arsenal, West Ham, Everton ati Brighton ti n figa gbaga ki ẹlẹjẹ tutu lati orilẹ-ede Scotland, iyẹn Ibane Bowat le tẹ wọn lọwọ lati Fulham.Ẹwẹ, agbabọọlu Manchester United, Nemanja Matic ti sọ ye yoo wu oun lati tẹkọ leti lọ si ẹgbẹ agbabọọlu Benfica ti wọn ba fiwe pe oun, bo tilẹ jẹ o ni Old Trafford san oun.Ka to maa lọ, Barcelona ti na ọwọ ifẹ si Georginio Wijnaldum to n gbaradi lati fi Liverpool silẹ ni kete ti adehun wọn ba pari ni opin saa yii.Lakotan, akọnimọọgba Chelsea tẹlẹ, Maurizio Sarri ti n mura lati pada si Napoli gẹgẹ bii akọnimọọgba tuntun.

Àkọlé fídíò, Mo bẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ jijà ní ọmọ ọdún méjì, inú mi dùn pé bàbá mi fi mí sí ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀ jíjà - Tijani Azeez