Chelsea vs Manchester United: Ole ní Man United kò bá borí Chelsea ṣùgbọ́n rẹfirí kọ̀ láti fún wọn ní pẹnárítì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Man United kò bá lu Chelsea mọ́lé, àmọ́ rẹfirí jà wá lólè pẹnárítì- Ole yarí.
Akọnimọọgba Manchester United, Ole Gunnar Solskjaer ti fi aidunnu rẹ han lórí bi rẹfiri ṣe kọ lati fun Man U ni pẹnariti ninu ifẹsẹwọnsẹ idije Premier League ọjọ Aiku.
Ole ni agbabọọlu Chelsea, Callum Hudson-Odoi fi ọwọ gbe bọọlu eyi to tumọ si pẹnariti.
- Ẹ wo àwọn tí yóò kọ́kọ́ gba abẹ́rẹ́ àjẹsárá Covid-19 to bá dé sí Naijiria...
- Irọ́ ni o! A kò tíì rí àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin tó lé ní 300 tí wọ́n jí gbé ní GGSS Jangebe - Ìjọba Zamfara
- Ẹ wo àwòrán bí Sunday Igboho ṣe ṣàbẹ̀wò sí Aarẹ Gani Adams nílé rẹ̀ nílùú Eko
- Sunday Igboho gbọdọ̀ gbàṣẹ ìdáàbòbò láti iléẹjọ́ tí kò ní jẹ́ kí ọlọ́páá mú un- Amòfin Ozekhome
Ṣugbọn rẹfiri Stuart Atwell ko fun Man United ni pẹnariti lẹyin to tun iṣẹlẹ laarin Hudson-Odoi ati Mason Greenwood wo eyi to fihan pe bọọlu kọkọ kan oke ọwọ Greenwood ko to ba agbabọọlu Chelsea lọwọ.
Amọ, Solskjaer ni ariwo tawọn alatako ẹgbẹ agbabọọlu n pa wi pe Man United ni awọn rẹfiri n fun ni pẹnariti julọ ni ko jẹ ki rẹfiri Attwell fun United ni pẹnariti.
Ẹgbẹ agbabọọlu Man United ti ni pẹnariti mejilelogun ninu idije Premier League lati ibẹrẹ saa bọọlu to lọ titi di akoko yii.
Eyi lo mu ki olukọni Liverpool, Jurgen Klopp ati akọnimọọgba Chelsea tẹlẹ, Frank Lampard sọrọ pe awọn rẹfiri n ṣegbe lẹyin Man United lori ọrọ pẹnariti.
- Àwọn Olùkọ́ Yorùbá ní ìlú Ondo fọkọyọ lórí ètò Akọ́mọlédè àti Àṣà lórí BBC Yorùbá
- Wọ ohun tí a mọ̀ nípa gbajúgbajù olórin ọmọ Naijiria, Dr Frabz tí wọ́n yìnbọn pa ?
- Ọjọ́ Ìṣẹ́gun ní abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 tó tó 4 milionu yóò bàlẹ̀ sí Nàìjíríà
- Fáàbàdà! Ìjọba mi kọ́ ní yóò buwọ́lu ìgbéyàwó akọ sákọ àti abo sábo- Ààrẹ Ghana yarí
Ole ni eyi gan an ni ko jẹ ki awọn rẹfiri fẹ maa fun Man United ni pẹnariti mọ.
Solskjaer ni ko gba ibikan ye oun idi ti rẹfiri ṣe kọ lati fun Man U ni pẹnariti.
Solskjaer ṣalaye pe lai ṣe ani-ani, tẹlifisan VAR fihan pe o yẹ ki rẹfiri fun United ni pẹnariti ṣugbọn "ariwo tawọn Chelsea n pa ni pe Greenwood lo kọkọ fi apa gbe bọọlu."
Àmọ́, akọnimọọgba Chelsea, Thomas Tuchel ti fesi si ọrọ Solskjaer.
Tuchel ni ko si ohun to jọ pẹnariti rara ninu ohun to ṣẹlẹ laarin Hudson-Odoi ati Greenwood.
Tuchel ni o ya oun lẹnu pe rẹfiri tiẹ lọ ṣ'ayẹwo iṣẹlẹ naa tẹlifísàn VAR nitori agbabọọlu Man United lo kọkọ fọwọ́ gbe bọọlu.
Ami ayo mejila ni Manchester City to wa ni ipo kinni fi n ṣiwaju Man United bayii lori tabili EPL.
Ipo karun un si ni Chelsea wa bayii lori tabili idije Premier League.















