Kashimawo Laloko: Gbajúgbajà akọ́nimọ̀ọ́gbá eré bọ́ọ̀lù Laloko tó ṣàwárí Mikel Obi àti Osaze dágbére fáyé

Kashimawo Laloko

Oríṣun àwòrán, NFF

Iku ṣeka, iku doro. Iku ti mu ọga agba tẹrẹ ri ni ajọ to n ri si ere bọọlu afẹsẹgba lorilẹede Naijiria, NFF, Kashimawo Laloko lọ.

Ọkan lara awọn ọmọkunrin rẹ, Adewale lo kede pe ile iwosan Sacred Hearts Catholic Hospital niluu Abeokuta ni Laloko ku si lọjọ Aiku lẹni ọdun mẹrindinlọgọrin.

Yatọ si wi pe, Laloko kii fọwọ sori ahọn sọ, o ṣiṣẹ takun takun lati mu ilọsiwaju ba gbajugbaja ileeṣẹ ikọni ni bọọlu afẹsẹgba Pepsi Football Academy.

Ọpọ awọn agbabọọlu to di ilumọọka lonii lo jade lati Pepsi Football Academy.

Awọn agbabọọlu bii Mikel Obi, Osaze Odemwingie, Soga Sambo, Elderson Echejile, Joseph Akpala ati Yinka Adedeji ati bẹẹ bẹẹ lọ lo jade ni Pepsi Academy.

Koda Laloko ṣe akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Gambia nigba aye rẹ.

Awọn ẹbi ti kede pe wọn yoo sin Laloko to jẹ Olori Parakoyi ilu Egba si ile rẹ to wa lagbegbe Gbonagun niluu Abeokuta.