Buhari: Ẹ mú gbogbo àwọn ajínigbé àtàwọn onígbọ̀wọ́ wọn balẹ̀ ní kíákíá

Buhari atawọn ọga ileesẹ ologun Naijiria

Oríṣun àwòrán, @NigeriaGov

Aarẹ Muhammadu Buhari ti paṣẹ fun awọn ọga ileeṣẹ ọmọ ogun ni Naijiria lati palẹ awọn janduku, ajinigbe atawọn to n ṣagbatẹru wọn mọ ni kankan.

Buhari lo paṣẹ ọhun lasiko to n ṣepade pẹlu awọn ọga ileeṣẹ ologun atawọn agbofinro naa nile ijọba niluu Abuja.

O ni eyii ti awọn janduku ati ajinigbe naa ṣe ninu dida eto abo Naijiria laamu ti to, ki awọn ọgagun si fopin si iṣẹ wọn ni kiakia.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lẹyin ipade naa ni olubadamọran pataki fun Aarẹ lori eto abo, Babagana Monguno jabọ ipade ọhun fun awọn akọroyin.

Atawọn ọga ileesẹ ologun Naijiria

Oríṣun àwòrán, @NigeriaGov

Monguno ni Aarẹ ti paṣẹ fun awọn adari ileeṣẹ ologun naa pe, ki wọn bẹrẹ iṣẹ lori aṣẹ ti oun ti pa ṣaaju ninu oṣu Keji pe, oun ti gbẹsẹle irinajo ọkọ ofurufu ati iwakusa nipinlẹ Zamfara.

O ni "lori ọrọ ijinigbe atawọn janduku loke ọya, aarẹ ti sọ pe oun fẹ ki a fi ẹnu rẹ jona lẹsẹkẹsẹ."

"Aarẹ sọ fun wa kedere pe oun n fẹ ki a fi oju awọn onigbọwọ awọn janduku ati ajinigbe naa lede, ki a le da alaafia pada si awọn agbegbe naa."

Buhari atawọn ọga ileesẹ ologun Naijiria

Oríṣun àwòrán, @NigeriaGov

O fikun pe Aarẹ ko ni gba ko jẹ pe awọn janduku ni yoo maa ṣakoso awọn agbegbe kan ni Naijiria, eyii tii ṣe ilu to lọba, to tun ni ijoye.

Monguno ṣalaye pe Aarẹ ti ṣe tan lati pese gbogbo ohun ija fun awọn awọn ọmọ lati koju awọn ọdaran to n da Naijiria laamu.

O pari ọrọ rẹ pe "Aarẹ ti paṣẹ pe ki a lo gbogbo agbara wa lati mu gbogbo awọn jaduku atawọn ajinigbe naa balẹ lai yọ awọn to n ṣagbatẹru wọn silẹ."

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Asa: Ìyàtọ̀ tó wà láàrin ìlànà ìpolówó ọjà láyé àtijọ́ àti òde òní

Ipade peu awọn ọga ologun naa lo waye ṣaaju ki Aarẹ Muhammadu Buhari to tẹkọ leti lọ silẹ Gẹẹsi, nibi ti yoo ti lọ gba itọju.

Ṣaaju ni amugbalẹgbẹ Aarẹ lori ọrọ to n lọ Femi Adesina ti kọkọ kede irinajo naa, nibi to ti sọ pe Aarẹ yoo pada si Naijiria ninu ọsẹ Keji, ọsu Kẹrin.