OPC àtàwọn ẹgbẹ́ ìbílẹ̀ míì kò ní gbà kí ìkọlù wáyé nílẹ̀ Yorùbá mọ́, iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ - Gani Adams

Gani Adams

Oríṣun àwòrán, @aareganiadams

Aarẹ Onakakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ti sọ pe iran Yoruba ti ṣetan lati daabo bo ara wọn lọwọ awọn agbesumọmi.

Gani Adams kilọ fun awọn agbebọn lati dẹkun ati maa dan iran Yoruba wo pẹlu ikọlu lemọ-lemọ nitori Yoruba ti ṣetan lati dabo bo ara rẹ.

O ni awọn ẹgbẹ to n daabo bo ilẹ Yoruba, eyi ti ẹgbẹ OPC atawọn ẹgbẹ mii wa lara wọn, ko ni gba ki ikọlu kankan waye nilẹ Yoruba mọ, lati akoko yii lọ.

Aarẹ lo sọ ọrọ naa lasiko to ṣe abẹwo si Olowo ti ilu Owo, Ọba Ajibade Ogunoye kẹta ninu aafin rẹ.

Ninu atẹjade kan lẹyin abẹwo naa, Gani Adams ni iṣẹ ti bẹrẹ lati dẹkun irufẹ ikọlu to waye nile ijọsin kan niluu Owo lọjọ karun un, oṣu Kẹfa, ọdun yi.

Ko din ni ogoji eeyan to ku lẹyin ikọlu naa to waye nile ijọsin St Francis Catholic Church, to wa ni adugbo Owaluwa, niluu Owo.

Lẹyin iṣẹlẹ naa ni ijọba apapọ sọ pe ẹgbẹ agbesumọmi ISWAP lo wa nidi ikọlu naa, amọ ijọba ipinlẹ Ondo ti Arakunrin Rotimi Akeredolu n dari sọ pe oun ko gba aba naa wọle.

Adams ni ikọlu Owo ọhun jẹ eyii to gba omi loju ọpọ araalu, to tun jẹ ọkan lara awọn ikọlu to buru julọ nilẹ Yoruba.

O ni oun kọ lẹta kan si akọwe agba ajọ UN, Antonio Guterres, lori ikọlu ọhun.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, yatọ si ajọ UN, lẹta naa tun lọ si ileeṣẹ eto abo kakkiri agbaye atawọn ijọbaorilẹ-ede lagbaye.

O ni “Lọwọ yii, awa ọmọ Yoruba ti ṣe ara wa ni oṣuṣu ọwọ, a kii ṣe ojo, a ko padanu ogun kankan ri nilẹ Yoruba.”

“Nitori naa, a ko ni sinmi titi ti a oo fi le awọn agbesumọmi kuro nilẹ Yoruba”

Ọba Ogunye dupẹ lọwọ Gani Adams fun akitiyan rẹ lati daabo ilẹ Yoruba lapapọ, lẹyin naa lo bu ẹnu atẹ lu ijọba apapọ fun eto abo to mẹhẹ.

Olowo ni eto abo yoo gbe pẹli si ni Naijiria ti ijọba ba le da ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe silẹ.

Ogunoye pari ọrọ rẹ pe awọn olugbe ilu Owo ti ṣetan lati dabo bo ara wọn lọwọ awọn ẹgbẹkẹgbẹ to bat un gbiyanju ikọlu mii.