Èèyàn 43 di àwátì nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi tó dànù ní ìpínlẹ̀ Niger

Aworan afihan awọn to n doola ẹmi leti odo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iroyin to n tẹwa lọwọ sọ pe eeyan kan ti padanu ẹmi rẹ ti ẹlomiran naa si farapa nigba ti ọkọ oju omi kan yi danu ninu odo Zumba ni ipinlẹ Niger.

Awọn oniṣowo aadọta la gbọ pe ọkọ oju omi yi gbe nigba ti ijamba yi fi waye.

Ileeṣẹ iroyin Daily Trust lo fidi ọrọ yi mulẹ.

A gbọ pe awọn eeyan wọnyi n dari bọ lati abule Shiroro lọ si ọja Kwata ni.

Iroyin tẹsiwaju pe eeyan mẹfa ni wn ribi doola ninu ijamba ọkọ oju omi yi.

Ọga ajọ iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Niger Ibrahim Inga fidi ọrọ yi mulẹ fun ileeṣẹ iwe iroyin Daily Trust ṣugbọn ko ṣọ pato iye eeyan to farakasa ninu iṣẹlẹ yi.

Iwadii ṣi n tẹsiwaju lati ṣawari awọn mii to di awati ninu ijamba yi to waye lowurọ ọjọ Aiku yi.

Aarin omi ni ọkọ oju omi yi taku si ko to yi danu

Ọkọ oju omi to danu

Olori awọn to n ṣiṣẹ awakọ oju omi taa mọ si Sarkin Ruwa ni Kwata-Zumba, Umar Isah sọ fun awọn akọroyin pe laarin omi ni ọkọ oju omi yi to gbe awọn oniṣowo ati nkan oko yi danu si.

O ni ọkọ naa ko ọmọde, awọn obinrin, nkan tita bi maalu, ẹran ewurẹ, ẹja ati awọn nkan oko miran.

O fidi ọrọ mulẹ pe ọkan lara awọn to wa ninu ọkọ naa padanu ẹmi rẹ ti wọn si ribi doola awọn mẹfa mii.

O ni maalu mẹta ewurẹ ati awọn nkan mi ti b'odo lọ.

Isah sọ pe'' a ko tete ribi doola awọn eeyan wnyi nitori ẹru awọn janduku n ba wa.Ni nkan bi ago mẹwa alẹ lọjọ Abamẹta, a ṣi n wa awọn to wa ninu ọkọ naa.A pada ribi doola eeyan meje ṣugbọn ọkan ninu wọn padanu ẹmi rẹ''