Olè àti jàǹdùkú tó wọlé mi ni kò jẹ́ ki ń ní ìwé ẹ̀rí mọ́, aláìníkánṣe làwọn tó ń halẹ̀ mọ́ mi - Tinubu
Bola Tinubu: Asiwaju kọ́wé sí ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá láti fèsì sáwọn tó ń halẹ̀ mọ lórí àìsì ìwé ẹ̀rí rẹ̀

Oríṣun àwòrán, OfficialAsiwajuBAT/Instagram
Oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu APC< Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti kọwe sọwọ si ọga agba ọlọpaa lori awuyewuye to n waye nipa bi ko se ri iwe ẹri ile ẹkọ to lọ ko silẹ.
Tinubu, ti agbẹjọro rẹ amofin Ojo Ayodele kọwe naa lorukọ rẹ salaye pe alainikan se ni awọn eeyan to n dunkooko mọ ọga agba ọlọpaa pe ko ba oun se ẹjọ lori aisi iwe ẹri naa.
O salaye pe asiko ti oun lọ se atipo nilu oyinbo laye ijọba ologun to gbogun ti ikọ NADECO, to n pe fun ijọba awa ara wa, ni wọn wa gbọn ile oun wo yẹbẹ yẹbẹ lẹyin oun.
Igba tawọn ole wọle mi ni awọn iwe ẹri mi di awati:
Asiwaju sọ siwaju si pe asiko yii naa nijọba ologun fẹ gbẹmi Wole Soyinka, Gani Fawehinmi, Kudirat Abiola, Ken Saro Wiwa ati oun gan.
O ni eyi si lo mu ki ọpọ awọn sa lọ soke okun lati se atipo, idi si ree tawọn ole, janduku ati ajidukiaẹni se raye wọ ile oun, ti gbogbo iwe ẹri oun si di awati.
Oludije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oselu APC naa tẹsiwaju pe oun ti lọ bura nile ẹjọ lati gba afidafiti lori isẹlẹ naa, ootọ ọrọ ti yoo si ba oun w saare ni eyi.
Alainikanse lawọn to ni ki ọga ọlọpa ba mi se ẹjọ lori aisi iwe ẹri mi:
Asiwaju Tinubu wa n rọ ọga agba ọlọpaa nilẹ wa lati fi ọwọ rọ awuyewuye ẹgbẹ ajijagbara to ni ki ileesẹ ọlọpaa ba oun se ẹjọ nitori ayederu iwe ẹri.
O salaye pe igbesẹ ẹgbẹ ajijagbara naa lọwọ oselu ninu, to si wa lati ta epo si asọ aala oun nitori aimọye igba ni wọn ti fi ẹsun yii kan oun latẹyin wa.
O wa n rọ ọga ọlọpaa pe ko sọ fawọn alatako oun naa pe ki wọn gba ile ẹjọ lọ lati pe oun lẹjọ, dipo ki wọn wa maa wa halẹ mọ ileesẹ ọlọpaa.
Bakan naa lo fikun pe ẹgbẹ ajijagbara Centre for Reform and Public Advocacy (CRPA) naa ko ni asẹ lati sọ fun ọọfisi ọga ọlọpaa pe ko tanna wadi oun nitori oun ko ni ohunkohun se pẹlu wọn.

Oríṣun àwòrán, OfficialAsiwajuBAT/Instagram
Ki lo ti sẹlẹ saaju:
Saaju ni ẹgbẹ Centre for Reform and Public Advocacy (CRPA) ti kọwe ransẹ si ọga agba ọlọpaa pe ko gbe Asiwaju Bola Tinubu ti mọle, ko si gbe lọ sile ẹjọ laarin ọjọ meji pere.
Agbẹnusọ fun ẹgbẹ ajijagbara naa, Agu Kalu lo leri leka bẹẹ lasiko ipade awọn akọroyin to se nilu Abuja lọjọ Satide.
Ẹsun ti ẹgbẹ ajijagbara naa fi kan Tinubu ni pe o ko awọn ayederu iwe ẹri silẹ lati du ipo oludije sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oselu APC.
Ẹgbẹ CRPA wa n dunkooko mọ ọga agba ọlọpaa pe to ba kọ lati se ohun ti awọn n fẹ, awọn yoo pe lẹjọ, pe kile ẹjọ pasẹ fun lati dahun ibeere awọn.
Ọrọ aisi iwe ẹri Tinubu yii lo ti n fa awuyewuye lori ayelujara eyi ti ọpọ eeyan n koro oju si.
















