Àwọn olóṣèlú lápá Ariwa fẹ̀ yọwọ́ Tinubu láti díje, àmọ́ a kò ní gbà - Igbimọ Apapọ Yoruba Lagbaye
Bola Tinubu: Ẹgbẹ́ Igbimọ Apapọ Yoruba Lagbaye ní àwọn kò ní gbà kí Ariwa dí Tinubu lọ́nà láti díje fún ipò ààrẹ

Oríṣun àwòrán, official BAT/Instagram
Ẹgbẹ kan to n ja fun ẹtọ ọmọ Yoruba, Igbimọ Apapọ Yoruba Lagbaye, Yoruba Council Worldwide, ti fẹsun kan awọn agba oloṣelu kan ni Ariwa pe wọn n gbimọ lati yọ ọwọ Bola Tinubu kuro lawo eto ibo sipo Aarẹ ti yoo waye lọdun to n bọ.
Aarẹ ẹgbẹ naa, Omoluabi Oladotun Hassan sọ nibi ipade awọn akọroyin kan l’Abuja pe awọn gbagbọ pe awọn eeyan naa fẹ yọ Tinubu ninu ere ije ipo Aarẹ bi wọn ṣe yọ Obafemi Awolowo ati oloye MKO Abiola.
Ninu atẹjade ti Hassan fi ṣọwọ si BBC Yoruba, o ni ọna ti awọn oloṣelu Ariwa naa n gba ni lati maa sọrọ kobakungbe lori awọn iwe iroyin nipa awọn iwe ẹri ile ẹkọ Tinubu.
Iwe ẹri Tinubu ni wọn fẹ fi ṣatako rẹ

Oríṣun àwòrán, @officialABAT
O ni eyii n waye lẹyin ti wọn ti kọkọ gbiyanju lati gbe Sẹnetọ Ahmed Lawan gẹgẹ oludije ẹgbẹ oṣelu naa amọ to ja kulẹ.
Hassan ni wọn fẹ lo iwe ẹri ile ẹkọ Tinubu lati ja kulẹ loju awọn araalu, awọn ko si ni gba iru rẹ laaye.
O ni “A ti mọ nipa ọgbọn ti awọn oloṣelu Ariwa n da lati yọ Tinubu kuro ninu ere ije ipo Aarẹ lọna ati faye gba oloṣelu miran lati inu ẹgbẹ mii, amọ to jẹ ọmọ bibi iha Ariwa.”
“A si ti mọ nipa ero wọn lati fi ọwọ eyin gbe Atiku wọle, ki wọn si le ṣatilẹyin fun lati di Aarẹ.”
“Igbimọ Apapọ Yoruba Lagbaye fẹ ki gbogbo aye mọ pe a ko ni faye silẹ ki wọn ṣe ohun kan naa ti wọn ṣe fun Obafemi Awolowo ati MKO Abiola si Tinubu.”
Gẹgẹ bii ohun ti Hassan sọ fun BBC, ẹya Yoruba lo ṣokunfa bi eto ijọba awarawa ṣe ṣeeṣe ni Naijiria nipa, o si yẹ ki ẹya kan naa lẹtọọ lati du ipo Aarẹ lai si ẹtanu kankan lati ọdọ awọn ẹya to ku.
O ni “O da wa loju gedegbe pe Asiwaju Bola Ahmed Tinubu nikan ni ọna abayọ si gbogbo iṣoro to n koju Naijiria lasiko yii.”
“Eto oṣelu ti a si n fẹ ni eyii ti yoo lọ wọọrọwọ, ti awọn eeyan yoo fi le yan ẹni to wu wọn gẹgẹ bii awọn ẹgbẹ oṣelu ṣe fẹnuko lori gbigbe ipo naa si ẹlẹkunjẹkun.”















