Tọkọ-tayà pàdánù ọmọ mẹ́ta lásìkò tí wọn lọ lúwẹ̀ẹ́
Lagos Pool Incident: Ọkọ àti ìyàwò pàdánù ọmọ mẹ́ta lẹ́ẹ̀kanṣoso sínú 'pool' nípínlẹ̀ Eko

Awọn ọkọ ati iyawo kan ti padanu ọmọ mẹtẹẹta ti wọn bi lẹẹkan ṣoṣo nipinlẹ Eko lẹyin ti awọn ọmọ naa ri sinu omi adagun 'pool' nipinlẹ Eko.
Awọn lọkọ-laya naa ni iroyin gbe pe wọn lọ si ibi ayẹyẹ kan ti wọn si fi awọn ọmọ mẹta silẹ ni ile, ti awọn ọmọ naa si gba ibudo iluwẹ lọ lati lọ luwẹ.
Bi isẹlẹ iku wọn ṣe waye ko i tii han si gbangban amọ awọn ara adugbo ati ẹṣọ inu agbegbe Ajah nibi ti wọn n gbe lo ri awọn ọmọ naa nibi ti wọn wa ninu omi naa ti wọn ti lefo.
Ẹni ti ọrọ naa ṣoju rẹ ni, kete ti wọn gbe awọn ọmọ naa kuro ninu omi, ti wọn si ri pe wọn ko mi mọ, ni wọn gbe wọn lọ si ileewosan nibi ti dokita ti sọ pe wọn ti ku.
''Ọga ẹṣọ alaabo agbegbe naa wa lara awọn to kọkọ ri ọmọ naa ti wọn si gbe wọn lọ si ileewosan.
Bakan naa ni wọn pe awọn ọlọpaa lẹsẹkẹsẹ , ti wọn si sọ fun awọn obi naa lori ẹrọ ilewọ wọn pe nkan pajawiri ti ṣẹlẹ ki wọn wa si ileeṣẹ ọlọpaa amọ ti wọn ko sọ nkan to ṣẹlẹ fun wọn.
Kete ni awọn obi ọmọ naa wa ti wọn si ba olori awọn ẹṣọ nibẹ, ti wọn si sọ fun wọn pe awọn ọmọ wọn mẹtẹẹta ti ri sinu omi.
Lẹyin ti wọn gbọ ọrọ yii ni baba ati iya awọn ọmọ naa daku gbọnrangandan, ti wọn si de ileewosan ki wọn to ji si aye pada.
Iroyin nipe ọmọbinrin ni awọn mẹtẹẹta, ti akọkọ si jẹ ọmọ ọdun mẹrinla, ekeji jẹ ọmọ ọdun meje, ti ikẹta si jẹ ọmọ ọdun mẹta.
Ẹ ma luwẹ lai si omuwẹ ni tosi yin - Ileeṣẹ ọlọpaa
Amọ lasiko to n fesi si iṣẹlẹ naa, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin loju opo Twitter ba awọn ẹbi ati ara ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si kẹdun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
''Imọran ni mo gba yin, ti ẹ ko ba ri omuwẹ ni tosi, ẹ ma lo omi adagun 'pool' lati wẹ.''
''Bakan naa ni ki ẹ ma wẹ ninu omi nla, ti ko ba si iranwọ ni tosi nitori o ṣeeni laanu pe awọn iya mẹta ri sinu omi lẹẹkan naa.''
''Agba ninu wọn si jẹ ọdọ, ki ẹ si ma ṣọra ni gbogbo ọna.''












