Mùsùlùmí òdodo ni mí, n kò wá ìwòsàn lọ ṣọ́ọ̀ṣì Christ Embassy - Kemi Afolabi

Oríṣun àwòrán, Kemi Afolabi Adedipe/Instagram
Gbajugbaja oṣere tiata obinrin nii, Kemi Afolabi ti figbe ta lori fọnran fidio kan to ṣafihan obinrin ti wọn n gba adura fun nile ijọsin Christ Embassys.
Iroyin to tẹle fọnran yi ni pe ilumọọka Pasitọ Chris Oyakhilome n gbadura fun Kemi Afọlabi ti ara rẹ si ti ya.
Afolabi ti wa sọ pe oun kọ loun wa ninu rẹ.
Ninu ọrọ to kọ soju opo rẹ ni Instagram lọjọ Aiku, Afolabi ni ko si igba kankan ti oun lọ si ṣọọsi lati lọ gba iwosan lori ipenija ailera ti oun n koju.
O ni lati igba ti iroyin aarẹ ti o n ṣe oun ti di ohun ti gbogbo eeyan mọ, orisi iroyin ayederu lo ti gbode lori iṣẹlẹ yi.
Afolabi ni tori naa loun ko ṣe ya si wọn ti oun si kọju si igbe alaafia ati ilera oun.
Musulumi ododo ni mi, mi o wa igbala lọ si ṣọọṣi
Nigba to n ṣalaye okunfa ti oun fi ni latio sọrọ soke lori nkan tawọn eeyan n sọ lori aisan rẹ yi, Afolabi ni musulumi ododo loun ati pe oun ni igbagbọ pe Allah ni yoo tan iṣoro toun n koju.
O ni ''Mo tẹra mọ eyi o si dami loju pe ayọ ni yoo kẹyin rẹ''
O ṣalaye pe jẹjẹ loun fi fidio ibi toun ti n ṣe adura nilana musulumi sita afi ti arakunrin kan kọ ọrọ to fọwọ kan ni lẹmi ni esi labẹ fidio naa.
''o beere pe ṣe mo ṣẹṣẹ mọpe musulumi ni mi ni abi nibo ni igbagbọ Islam mi wa nigba ti mo n wa ojutu sọrọ mi ni inu ṣọọṣi''
''Ọrọ yi bami lojiji ti mo si n ro pe bawo lawọn eeyan ṣe daju bayi.Mo fẹ fi asiko yi tako iroyin kankan pe mo lọ gba iwosan ni ile ijọsin ṣọọṣi ''
''Emi kọ nimo wa ninu aworan to gbode mo si fẹ ki awọn eeyan ma ṣe kaa kun.''

Oríṣun àwòrán, Kemi folabi Adedipe/Instagram
Kini aisan Lupus ti Kemi Afolabi n koju?
Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka ètò ìlera UK ṣe sọ ìyẹn UK National Health Service, àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́ ni Lupus, tó sì máa ń fa ara ríro, kó máa rẹ ènìyàn àti kí nǹkan máa ṣú sí ènìyàn lára. Lupus jẹ́ àìsàn tí kò gbóògùn ṣùgbọ́n ènìyàn le ṣe àmójútó rẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́ tí ènìyàn bá tètè mọ̀ wí pé ó wà lára. Bákan náà ló jẹ́ àìsàn tó máa ń bẹ̀rẹ̀ díẹ̀díẹ̀ kó tó di ńlá.
Tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ̀rẹ̀, ó máa ń fa ara ríro, kó máa rẹ̀ ènìyàn ní gbogbo ìgbà àti kí ara máa ṣú. Bẹ́ẹ̀ náà ló jẹ́ àìsàn tó máa ń mú ènìyàn tóbi ní gbogbo ara, ọkàn, ọ̀nà ọ̀fun àti kídìnrín nígbà tó bá ti pẹ́ lára díẹ̀ si. Nígbà tó bá búrẹ́kẹ́ tán, ó máa ń dá ọgbẹ́ sínú ọkàn, ọ̀nà ọ̀fun àti kídìnrín, kí ènìyàn máa wú lódìlódì tó sì lè mú ẹ̀mí lọ.

Kí ló ń fa lupus?
Kò ì tíì sí ìwádìí tó fi ohun tó ń fa lupus múlẹ̀ gan an .
Kìí ran ènìyàn, èyí túmọ̀ sí pé kìí ṣe àìsàn tí èèyàn le kó láti ara ẹnì kan sí ẹlòmíràn. Àmọ́ lára àwọn ohun tó le fa lupus nìyìí: • Òògùn • Òòrun • Ọmọ bíbí • Kí obìnrin ma ṣe nǹkan oṣù mọ́ • Fáírọ̀ọ̀sì Ìwádìí fi hàn pé obìnrin ló sábà máa ń ní lupus ju ọkùnrin lọ, tó sì wọ́pọ̀ nílẹ̀ Adúláwọ̀ àti ilẹ̀ Asia















