‘Kò sí ohun tó burú nínú kí àwọn ènìyàn máa lo ìbọn nígbà tí àwọn agbésùnmọ̀mí náà ti ń gbébọn’

Gani Adams

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Ìgbìmọ̀ Ààrẹ Ọ̀nà Kakaǹfò ilẹ̀ Yorùbá ti kan sáárá sí ìjọba ìpínlẹ̀ Zamfara.

Paapaa lórí àṣe tó fún àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà láti máa gbé ìbọn láti lè fi máa dá ààbò bò ara wọn lọ́wọ́ ìkọlù àwọn agbébọn.

Onírúurú ìkọlù ló ń wáyé lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí ní ìpínlẹ̀ Zamfara níbi tí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ti ń pàdánù ẹ̀mí wọn tí ìjínigbé náà sì ń fi ojoojúmọ́ peléke si.

Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹfà ni Gbonka Aarẹ-Onakakanfo, Gboyega Adejumo rọ àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá láti tẹ̀lé ìlànà tí gómìnà ìpínlẹ̀ Zamfara fi lélẹ̀.

Adejumo rọ àwọn gómìnà ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà láti pàṣẹ fún àwọn ènìyàn agbègbè wọn náà láti máa gbé ìbọn rìn.

O ni eyi yoo je kí wọ́n le máa fi dá ààbò bò ara wọn lọ́wọ́ ìkọlù àwọn agbébọn tó ń fi ojoojúmọ́ wáyé ní ilẹ̀ Yorùbá.

Bákan náà ló ni èyí tí àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá fi ààyè gba ìkọlù, ìjínigbé, ìpànìyàn àti àwọn ìwà láabi mìíràn tí àwọn agbébọn ń ṣe sí àwọn ẹ̀yà Yorùbá ti tó.

Ó ní bí àwọn agbéṣùmọ̀mí tí wọ́n ń pe ara wọn ní àgbébọn àti ajínigbé ṣe ń pa àwọn ènìyàn bí ẹran àti bó ṣe wù wọ́n ní ilẹ̀ Yorùbá ti tó kó dópin báyìí.

Ó fi kun pé gómìnà Bello Matawale ti ṣí ojú àwọn gómìnà báyìí kí gbogbo àwọn gómìnà sì là ojí=ú wọn láti gbèjà ara wọn káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

“Gbígbé ohun ìjà ogun láti fi dá ààbò bo ara ẹni kìí ṣe ohun tuntun káàkiri àgbáyé, ohun tó yẹ kí ìjọba tì lẹ́yìn ni níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ti fòfin dè é.”

Adejumo wá gbóríyìn fún ìjọba ìpínlẹ̀ Eko pẹ̀lú bó ṣe fi òfin dé àwọn ọ̀kadà ní àwọn agbègbè kan.

Bákan náà ló tún rọ àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ara wọn kí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan bíi Amotekun le rí iṣẹ́ wọn ṣe bó titọ́ àti bó ṣe yẹ.

Ìjọba Oyo fẹ́ gba àfikún Amotekun 500 ṣíṣẹ́ láti ṣàfikún ààbò tó gbópọn

Seyi Makinde ní ojúṣe gbogbo èèyàn ni ìpèsè ààbò tó gbópọn, kìí ṣe tìjọba nìkan

Ikọ Amotekun ati Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, seyimakinde/Facebook

Gomina ipinlẹ Oyo, Onimọ-ẹrọ, Seyi Makinde ti kede pe eto ti debi to lapẹrẹ bayii lati gba ẹẹgbẹta osisẹ Amotekun si nipinlẹ naa.

O ni awọn osisẹ naa ni yoo maa ku ikọ Amotekun to wa nilẹ lọwọ, ki wọn le peye eto aabo to peye fun awọn eeyan ipinlẹ Oyo.

Gomina Seyi Makinde lo sisọ loju ọrọ yii lasiko ipade olosoosu fawọn eeyan ti eto aabo gberu nipinlẹ naa, ninu eyi tawọn alaga ijọba ibilẹ, awọn olori ileesẹ alaabo atawọn ọba alaye peju si.

Ile igbimọ lọbalọba to wa lọgba Secretariat nilu Ibadan ni ipade naa ti waye lopin ọsẹ.

Nigba to n salaye nipa aabo ipinlẹ Oyo, Makinde ni ojuse gbogbo eeyan ni ipese aabo to peye jẹ, bi o tilẹ jẹ pe ojuse naa wa lọrun ijọba julọ.

“Ta ba wo gbogbo iroyin ta n gbọ yika Naijiria, a si le ni alaafia si n jọba nipinlẹ Oyo bẹẹ si ni kii se ijọba nikan lo ni aseyọri yii bikose pẹlu aayan awọn eeyan mii ti eto aabo gberu.

Bakan naa lo fikun pe afojusun ipade naa ni lati se agbekalẹ bi alekun ati amugbooro yoo se ba eto aabo ipinlẹ Oyo.”

Gomina Makinde wa lo anfaani akoko naa lati mọriri awọn osisẹ agbofinro nipinl naafun aayan alailẹgbẹ wọn lati mu ki alaafia jọba, to si tun rọ wọn lati tubọ mu aayan naa ni ọkunkundun.

Bakan naa ni gomina ana nipinlẹ Oyo, agba oye Rashidi Adewolu Ladoja toun naa wa nibi ipade ọhun kan saara si gomina Makinde lori bo se n gbe igbesẹ kiamọsa lori eto aabo eyi to ti seranwọ fun ipinlẹ Oyo.

Àwọn ọ̀dọ́ sun adigunjalè ọlọ́kadá ní iná nílùú Ibadan 
Aworan ibi tí wọ́n ti ń sún àwọn adigunjale

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Awọn afurasi adigunjale meji ni awọn ọdọ kan sun ni ina latari bi wọn ṣe gbinyanju lati ji ọkada gbe salo.

Iṣẹlẹ naa waye lagbegbe Ijokodo niluu ibadan ni owuro Ọjọbọ nigba ti ọwọ tẹ àwọn adigunjale naa.

Ósojumikoro to ba awọn akoroyin sọ̀rọ̀ ni pe awọn mẹta ni awọn adigunjale naa ti ọwọ si tẹ meji ninu awọn mẹta naa, ti ọkan si salọ.

O ni kete ti ọwọ awọn ọdọ tẹ àwọn adigunjale naa ni wọn sọ taya si wọn lọrun ti wọn dana sun wọn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

"Awọn koko na awọn adigunjale naa ki awọn olopaa to de, wọn ko wọn si ninu moto, ọkan lara awọn adigunjale naa gbẹmimi, eyi lo mu ki olopaa gbe oku wọn silẹ."

"Kete ti awọn olopaa sọ awọn adigunjale naa silẹ ni awọn olokada ni agbegbe Waec sọ taya si wọn lọrun ti wọn si dana sun wọn."

Nigba ti Iko BBC News Yoruba kan si agbenuso ileeṣẹ ọlọpaa, Olawale Osifeso, o ni iwadi ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.