Ariwo ìbúgbàmu gba Ukraine, ilé alájà mẹ́sàn-án wó lé ọ̀pọ̀ èèyàn lórí
Ukraine ní Russia fẹ́ halẹ̀ mọ́ òun saájú ìpàdé àgbáyé ló fa àkọ̀tun ìkọlù náà

Idi ni pe ikọ ọmọgun orilẹede Russia tun yin ọpọ aso oloro mọ ilu naa, to si ba ọpọlọpọ ile jẹ.
Eeyan meji lo fara pa ninu akọtun ikọlu to gberasọ lẹyin ti aarẹ Zelesky bẹbẹ pe ki awọn alatilẹyin awọn pese aabo oju ofurufu fun il Ukraine.
Gẹgẹ bi Mayọ ilu Kyiv', Vitali Klitschko ti wi, "ọpọ eeyan lo farapa” nitori ikọlu ado iku naa eyi to ba ilegbe kan ni deede aago mẹfa abọ aarọ oni.
"A ti n sa gbogbo agbara wa lati pa ina to suyọ ninu awọn ilegbe naa, ka si ko awọn olugbe ibẹ kuro ninu awọn ile naa.”
Awọn osisẹ adoola ẹmi si ti n saayan lati doola ẹmi awọn eeyan to wa nibi ti ado iku naa ti bu gbamu, to si bawọn ilegbe.
Gẹgẹ bi ileesẹ ọlọpaa ti wi, wọn fa ọmdekunrin kan yọ labẹ woku ile, ti wn si tun ti n saayan lati doola ẹmi iya rẹ.
Awọn adoola ẹmi ni ireti wa fun iya ọmọ naa lati ye:
Eefin si n ru lọwọ lati inu awọn ilegbe ti ado loro ba, nibi isẹlẹ naa.
Awọn osisẹ panapana si ti n lo akaọ igbalode lati sawari ibi ti obinrin naa si bi o tilẹ jẹ pe isẹ to lagbara ni igbesẹ naa.
Se ni wọn si n ko awọn awoku bulọọku to n dawo silẹ kuro, bi omiran mii un se n da wo lulẹ si.
Ireti si wa pe wọn ko ni pẹ obinrin naa yọ kuro labẹ il naa laipẹ.

Akọtun ikọlu yii lo wa lati dẹru ba Ukraine saaju ipade apero - Klitschko
Olootu ilu Kyiv, Vitali Klitschko ti wa kede pe igbesẹ lati dunkooko mọ Ukraine saaju ipade apero agbaye ti yoo waye lọsẹ yii, ni ikọlu naa se waye.
Akọroyin BBC, Nick Beake ni awọn osisẹ panapana ti n wo ilegbe alaja mẹsan ti ado oloro ba naa, ti wọn si ti fọ ferese ati aja to kẹyin lara ilegbe naa.
Amọ awọn alasẹ ni o ti ya ju lati le sọ iye eeyan to ku ninu ikọlu naa.
















