Ṣé lóòótọ́ ní pé àjọ elétò ìdìbò INEC láwọn ibùdó ìforúkọsílẹ̀ olùdìbò ti wọ́n yà sọtọ ní Niger Republic?

Oríṣun àwòrán, INEC
Lawọn oju opo kaakiri ni Naijiria oriṣi iroyin la n foju ri ni paapa bayi ti akoko idibo ti n sunmọ ni Naijiria.
Pupọ awọn iroyin yi ni ko fi gbogbo ara sunmọ ootọ tawọn miran si jẹ agbelẹro patapata.
Ninu iwadii taa maa n ṣe labẹ ẹka to n tan imọlẹ si ayederu iroyin BBC, a ṣawari iroyin kan to sọ pe ajọ eleto idibo Naijiria INEC ti ya awọn ibudo idibo kan sọtọ lorileede Niger.
Se lootọ ni iroyin yi abi ahesọ ni? Ohun ti iwadii wa ṣe afihan ree
INEC ṣiwe han BBC lati ṣafihan awọn ibudo iforukọsilẹ to ṣeto.

Oríṣun àwòrán, INEC
Akọroyin wa to kan si ajọ eleto idibo INEC sọ pe ajọ naa ni awọn ko ni aaye iforukọsilẹ kankan ni orileede Niger bawọn iroyin ẹlẹjẹ to gbode loju opo ayelujara ṣe n wi.
Ọkan ninu awọn iroyin taa n wi leleyi ti Nche Nwabunkiek kanfi sita to ti sọ pe ajọ INEC ni aaye idibo to le ni ogun lorileede Niger.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nche Nwabunike
Nwabunike kọ ọrọ rẹ yi sabẹ eleyi ti ileeṣẹ iroyin oju opo ayelujara Sahara Reporters fi sita.
Ọrọ yi lawọn eeyan ri ti wọn si ya sọtọ ki wọn to bẹrẹ si ni pin kaakiri oju opo ayelujara ni paapa oju opo Whatsapp.
Iwadii lati ọwọ ẹka BBC to n risi itanmọlẹ si iroyin ẹlẹjẹ BBC Disinformation fi han pe oju opo Nwabunike to wa ni Facebbok gbarọgudu opo ni.
Iwadii fi han pe eeyan mẹsan lo ni gẹgẹ bi ọrẹ́ọ ati ko si ni iroyin kankan to ṣafihan pe eeyan gidi to lorukọ lo ni oju opo naa.
Ni ṣoki, oju opo ti wọ́n da kalẹ ti ko ni okun lọrun taa n pe ni bot account ni oju opo rẹ yi jẹ.
Lọpọ igba iru awọn oju opo yi ni wọn maa fi n tan iroyin ayederu kaakiri gẹgẹ bi iwadii wa lọdọ INEC ṣe fihan.
Awọn miran naa tan ọrọ yi kaakiri
Ọrọ ti oju opo Nwabunike gbe sita yi di nkan tawọn mii tẹwọ gba.
Koda awọn mii tun fi kun ọrọ naa lati le jẹ ki o di itẹwọgba.
Arakunrin kan loju opo Facebook, Mazi IK Ijezie jẹ ọkan ninu wọn.
Ohun to ṣe ni pe o fi aworan awọn eeyan kan kun ọrọ yi to si ni wọn to lati gba kaadi idibo ọlọjọ pipẹ ni ọkan ninu awọn aaye iforukọsilẹ to wa ni Niger.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Mazi Ik Ijezie
Iwadii wa fihan pe aworan to pe ni ti Niger yi ti n tan kaakiri oju opo ayelujara lati oṣu Keje ọdun 2018 ati pe nibi idibo Gomina ipinlẹ Ekiti ni wọn ti ya aworan yi.
Agbẹnusọ INEC Festus Okoye sọ fun BBC pe ofin ko faaye gba awọn lati forukọ awọn oludibo kankan silẹ lẹyin odi ibi ti ilẹ Naijiria de tori naa ko si bawọn ṣe le lọ ṣeto iforukọsilẹ fawọn eeyan ni Niger.
O ni bi eeyan kankan ba forukọsilẹ loju opo INEC o di dandan ki iru eeyan bẹẹ foju han ni aaye ti wọn yoo ti ya aworan rẹ silẹ ti wọn ba fẹ dibo ni ibudo idibo.
Ibudo idibo meloo lo wa ni Naijiria?
Ajọ eleto idibo INEC fi kun pe awọn ni ibudo idibo to le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun kan (176, 846) ni orileede Naijiria awọn ko si ni ibudo idibo kankan lẹyin odi.
Arakunrin Okoye fi kun pe ọrọ yi wa lara awọn ahesọ ọrọ tawọn kan n gbe kaakiri lati fi mu iyapa ati ija ẹlẹyamẹya wa laarin awọn eeyan Naijiria.
Lẹnu ọjọ mẹta yi, wahala ati ri kaadi idibo ọlọjọ pipẹ gba ni Naijiria da bi nkan.
Ko pe si asiko yi lawọn kan sọ pe awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo n kọdi awọn ẹya kan lorileede Naijiria lati ri kaadi idibo yi gba ni ilu Eko.
Gbogbo bi awọn eeyan ṣe n ṣuuru bo ibudo iforukọsilẹyi lo mu ki ajọ INEC kede pe awọn yoo sunjọ gbedeke gbigba kaadi idibo yi siwaju si.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post












