What is BVAS?: Àwọn ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ẹ̀rọ BVAS tí INEC yóò lò fún ìdìbò gómìnà Ekiti

Àjọ eleto idibo ni Naijiria, INEC, ti dan ẹ̀rọ to n ṣe àyẹ̀wò oludibo Bimodal Voters Authentication System, BVAS, wo nipinlẹ Ekiti.
Ọjọ Aje, ọgbọnjọ, osu Karùn-ún, ọdun 2022, ni eto naa waye.
Wọn dan àwọn ẹ̀rọ naa wo ni ilu Ado-Ekiti, Igede Ekiti, ati Ikere Ekiti.
Àjọ INEC fi ẹ̀rọ naa yẹ kaadi àwọn oludibo kan wo, nipasẹ ìka ọwọ wọn ati oju wọn.
Alaga àjọ INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, ati awọn lọga-lọga mii lo kopa nibi eto naa, gẹgẹ bi ara imurasilẹ fun idibo gomina ipinlẹ naa ti yoo waye lọ́jọ́ kejidinlogun, oṣu Kẹfa.
Ọjọgbọn Yakubu sọ pe iṣẹ àwọn ẹ̀rọ naa tẹ oun lọrun ati pe ko si ni ko ni si iyọnu kankan lasiko idibo.
O ni INEC ti ṣakiyesi awọn ipenija to rọ mọ imọ ẹ̀rọ BVAS, ti awọn si tun ti ṣe irolagbara fun isẹ rẹ lori ayẹwo orúkọ oludibo lasiko idibo gomina ti yoo waye ni ipinlẹ Ekiti ati Osun.
"Pẹlu ayẹwo ti a ṣe lónìí, mo fẹ́ ki awọn oloselu to n siyemeji nipa ijafafa ẹ̀rọ yii, fi ọkan wọn balẹ pe, yoo mu ki idibo waye lai si magomago kankan."
Bákan naa lo sọ pe gbogbo awọn eroja idibo lo ti gunlẹ gbogbo ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa ni Ekiti.
Àwọn nkan to yẹ ki o mọ nipa BVAS

Ọjọ kọkanla, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2022, ni INEC kọkọ lo BVAS, nibi atundi ibo ile asofin Isoko South I, nipinlẹ Delta.
Lẹyin naa lo tun lo o ni oṣù Kọkanla, ọdun 2021 lasiko idibo gomina to waye ni ipinlẹ Anambra.
INEC bẹ̀rẹ̀ si ni lo ẹ̀rọ yìí, lati le fi opin si àwọn magomago to ma n waye nipa iye oludibo.
Imọ ẹ̀rọ ayelujara 'internet' ni ẹ̀rọ BVAS fi n sisẹ.
Ẹ̀rọ BVAS ma n ṣe ayẹwo àkọsílẹ̀ oludibo nipasẹ ika ọwọ wọn ati ẹyin ojú wọn.
Pẹlu imọ tuntun yii, oludibo ti ko ba ni ojulowo kaadi ko ni le dibo.
Bakan naa, oludibo ti ẹ̀rọ naa ko ba ri ayẹwo kaadi rẹ ṣe, ko ni le dibo botiwu ki kaadi rẹ jẹ ojulowo to.
Ẹ̀rọ BVAS yii tun ni ayaworan 'camera' lara, eyi to mu ko seese fun lati ya aworan esi ibo ni ibudo idibo kọọkan, ti yoo si tun fi esi naa si ori ayelujara INEC, nibi ti àwọn araalu ti le ri i ti idibo ba ṣe n pari.















