Methodist church Prelate Samuel Kanu: Báyìí nì orí ṣé kò olórí ìjọ Methodist, àlùfáà méjì ní Abia yọ lọ́wọ́ ajínigbé

Aworan olori ijọ ti o ko sọwọ ajinigbe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ ọlpaa ti fidi rẹ mulẹ awọn ajinigbe ti tu olori ijọ Methodist Samuel Kanu ti wọn jigbe ni Abia silẹ.

Alukoro ọlọpaa ni ipinlẹ naa lo ṣalaye ọrọ yi fun BBC.

Amọ SP Geoffrey Ogbonna ko ṣalaye bi wọn se tu silẹ tabi boya wọn san owo idoola.

Ni opin opin ọsẹ to kọja yi ni wọn ji olori ijọ yi gbe.

Koda wọn ji alufa ijọ meji kan gbe pẹlu rẹ nigba ti wọn n dari bọ lati eto ile ijọsin kan to wa ni ipinlẹ Abia.

Ọlọpaa ni awọn to wa pẹlu olori ijọ yi naa ti gba itusilẹ

Awọn biṣọọbu meji to wa pẹlu rẹ ni Biṣọọbu ijọ Methodist Owerri Diocese, ati Prelate Chaplain ijọ naa.

Prelate Samuel Kanu

Oríṣun àwòrán, METHODIST CHURCH OF NIGERIA

Àwọn ajínigbé gbé olórí ìjọ Methodist, àlùfáà méjì ní Abia, Ohun tí Ọlọ́pàá ń ṣe rèé

Olori kan ijọ eleto, Methodist Church of Nigeria, Ọmọwe Samuel Uche, ti di awati, lẹyin ti awọn kan ji gbe nipinlẹ Abia.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ naa, Geoffrey Ogbonna, sọ fun ileeṣẹ iroyin abẹle, Channels Television pé, ọjọ Aiku ni iṣẹlẹ naa waye.

Gẹ́gẹ́ bo ṣe sọ, ojisẹ Ọlọrun naa ati eeyan meji ni wọn ji gbé - Biṣọpu ìjọ Methodist ni Owerri,Rt. Rev. Dennis Mark, ati alufaa kan.

Ogbonna salaye pe ni nkan bi aago meji ọsan ni wọn ji wọn gbe lasiko ti wọn kuro nibi ìsìn ìjọ kan nilu Okigwe nipinlẹ Imo, pada si ijọba ibilẹ Umu Nneochi nipinlẹ Abia.

Àkọlé fídíò, 'Ó ṣì wù mí kí n fi ojú mi ríran padà, owó India ni kò sí! Hip hop yìí nìkan ni mo fi ń gbéra'

Agbẹnusọ ọlọpaa ni ijinigbe naa jẹ nkan tó buru pupọ, ṣùgbọ́n o ni idaniloju wa pe ileeṣẹ ọlọpaa ti n sakitiyan lati ri pe wọn pada sile laaye.

Bákan naa lo rọ awọn araalu lati fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti, ti wọn ba kẹfin ohunkohun to le mu ki ominira awọn ojiṣẹ Ọlọ́run naa rọrun.

Ọjọ diẹ sẹyin ni awọn agbebọ̀n pa ọmọ ile asofin kan nipinlẹ Anambra, Okechukwu Okoye.

Wọn ti kọkọ ji Okoye gbe lọjọ kẹẹdogun, oṣu Karun-un, ki awọn araalu to o ri oku rẹ lai ni orí.