UNICEF Report: Ìfipá bá ọmọdé lọ̀pọ̀, ìpànìyàn ń dá ẹ̀mí àwọn ògo wẹẹre légbodọ̀ ní Naijiria

Children

Oríṣun àwòrán, otherss

Iwadii ti Ajọ to n risi ọrọ awọn ọmọde lagbaye, UNICEF gbe jade ti ni o kere tan awọn akẹkọọ to le ni egbeje ni ileẹkọ bii marundinlọgbọn, ni awọn agbebọn ti ji awọn ọmọde gbe lọ lasiko ikọlu si ibẹ lorilẹede Naijiria.

Iwadii naa ni o kere tan awọn ọmọde lọna ẹgbẹrun mọkanlelogun ni Ajọ Iṣọkan Agbaye,UN ti fi idi rẹ mulẹ pe wọn n lo gẹgẹ bi agbebọn ni iha Iwọ Oorun ati Gbungun Ilẹ Afrika.

Ajọ UNICEF ni lati ọdun 2016 ni Iwọ ati Gbungun Ilẹ Afrika ti leke tente ni awọn orilẹede to n fi iya jẹ awọn ogo wẹẹrẹ lasiko ti rogbodiyan tabi ogun ba bẹ silẹ.

Bakan naa ni wọn fẹsun kan awọn ẹṣọ alaabo to fi mọ awọn to n koju wọn, pe wọn ma n fi iya jẹ awọn ọmọde.

Ajọ UNICEF ni awọn ọmọde to le ni ẹgbẹrun mọkanlelogun ni wọn n lo gẹgẹ bi ọmọogun , ti wọn a si tun fi ipa ba ẹgbẹrun meji o le ninu wọn lopọ.

O kere tan ẹgbẹrun mẹta aabọ ni wọn ti jigbe lọ lasiko ikọlu si ileẹkọ bi ẹgbẹrun kan aabọ, to fi mọ ile iwosan ni agbegbe Iwọ ati Gbungun ilẹ Afrika laaarin ọdun marun.

Ni ọdun to kọja nikan, awọn ọmọde to le ni ẹgbẹrun mẹfa ti ida mejilelọgbọn ninu wọn jẹ obinrin ni wọn fi ipa ba lọpọ.

Àkọlé fídíò, Timothy Adegoke: Màmá olóògbé ní ògó ilé àwọn ni wọ́n pa, ikú rẹ̀ kò gbọdọ̀ já sásán

Ninu ọrọ olori awọn oṣiṣẹ Ajọ UNICEF ni Naijiria, Phuong Njuyen ni awọn ọmọde ni Naijiria ni wọn n faragba julọ ninu ọrọ eto aabo to mẹhẹ kaakiri ẹkun to wa lorilẹede naa.

''Eleyii kii ṣe ohun to yẹ ka fi ṣe ere rara nitori ifiyajẹni lọna aitọ si awọn ọmọde wọpọ lorilẹede Naijiria to fi mọ Iwọ oorun ati Gbungun ilẹ Afrika''.

''Awọn ọmọde gbọdọ ni anfaani lati dagba ninu ọgbọn, ki wọn lọ si ileẹkọ, ki wọn ri iṣẹ ṣe, ki wọn si ko ipa to tọ ni iṣejọba ati ọjọ iwaju orilẹede wọn.''

Nitori naa Ajọ UNICEF kesi gbogbo awọn ti ọrọ kan lati fi opin si ifiyajẹni awọn ọmọde ati ifipabanilopọ awọn ogo wẹẹrẹ ni Naijiria ati ni ilẹ Afrika ni apapọ.

Àkọlé fídíò, EndSARS Victims: Ìyá méjì nínú mẹ́ta ti kú nínú àwọn ọmọ tí ọlọ́pàá gbé àmọ́ torí ìwọ́de