Mike Tyson Canabis ambassador: Malawi kọ lẹ́tà sí Mike Tyson pé kó di asojú wọn fún ewé ọlà, igbó

Mike Tyson

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileese eto ọgbin lorilẹ-ede Malawi ti kọwe ẹbẹ ransẹ si Mike Tyson pe ko di asoju awọn lori ọrọ Igbo.

Mike Tyson to jẹ gbajugbaja abẹsẹkubi ojo ni ti gba iwe ifẹ lati ọdọ ileesẹ ijọba apapọ orilẹ-ede Malawi to n ri sio eto ọgbin.

Won ni ki Mike Tyson jọwọ ara rẹ gẹgẹ bii asoju wọn lori ọra Igbo to jẹ ewé ọlà.

Minista Lobin Lowe salaye nipa bi Igbo se di eyi ti ofin Malawi faaye gba nile ati nita orilk-ede Malawi.

Ileese eto ọgbin naa ni pe Egbẹ United States Cannabis Association naa lọwọ si ipe lati soju naa.

Ogbẹni Lowe so pe olokowo naa ni Mike Tyson ati pe oun naa ni oko Igbo to ti na owo si to pọ.

Àkọlé fídíò, Timothy Adegoke: Màmá olóògbé ní ògó ilé àwọn ni wọ́n pa, ikú rẹ̀ kò gbọdọ̀ já sásán

'Malawi Gold' to jẹ wura Malawi ni orukọ ti wọn n pe Igbo ni Malawi.

Ọdun 1985 ni Mike Tyson bẹrẹ abẹṣẹkubi ojo, ko to fẹyinti lọdun 2005.

Àkọlé fídíò, EndSARS Victims: Ìyá méjì nínú mẹ́ta ti kú nínú àwọn ọmọ tí ọlọ́pàá gbé àmọ́ torí ìwọ́de