Abdulmajeed Abdulsalam: Wọ́n ti bá mi nu Kẹ́míkà tí ẹnikejì táa jọ ń "paint" pákó mi dà sí mi lójú àmọ́...

Àkọlé fídíò, 'Ó ṣì wù mí kí n fi ojú mi ríran padà, owó India ni kò sí! Hip hop yìí nìkan ni mo fi ń gbéra'

Kedere ni oju Abdulsalam n riran titi to fi dagba di ọdọ, wọn o bi oju fifọ yii mọ ọ.

Lẹyin oṣu meji ti o ti n lo ogun ti wọn fun un nileewosan, Abdulsalam rii pe oju rẹ su ti ko si mọlẹ daradara mọ.

Abdulmajeed Abdulsalam

Abdulmajeed Abdulsalam ṣalaye fun BBC Yoruba pe oun n kọ iṣẹ mọ iwe ti o n ka nigba naa lọhun to si ni awọn maa n lo Kẹmika lati fin awọn pako ti wọn fi n ṣiṣẹ gẹgẹ bii Kafinta.

O jẹ ko di mimọ pe ẹnikeji ti awọn jọ n ṣiṣẹ lo fẹ du ki pako ti wọn n fin lọwọ ma yi ilẹ ko ma dọti, afi to di pe Kẹmika to gbe lọwọ kan dede da sinu oju Abdulsalam ni.

O ni kii ṣe pe o mọọmọ da a si oju oun.

Ki ni igbesẹ ti Abdulmajeed ati mọlẹbi ti gbe?

Abdulmajeed Abdulsalam

"Iya mi ti gbe mi lọ si oriṣiriṣi ileewosan kaakiri ti wọn n gbiyanju lati ma jẹ ki oju rẹ fọ.

Wọn tilẹ sọ fun wa pe iṣẹ abẹ ti mo nilo kii ṣe eyi taa le ṣe ni Naijiria nibi".

O ni wọn o tii ṣe iṣẹ abẹ lori oju yii ri ayafi ki a gbe e lọ si India amọ owo naa ni ko si.

"O si wu mi lati fi oju mi yii riran tori wọn sọ fun mi pe o si ṣeeṣe".

Ẹwẹ, awọn dokita ti fi daa loju pe bi awọn ẹbi rẹ ba ri owo ko jọ, wọn yoo gbe e lọ si Indian lati lee ṣe iṣẹ abẹ to nilo.