Eye Bank in Lagos: Ibùdó ìtọ́jú ojú ní kẹ fi ẹyinjú yín sílẹ̀ tẹ bá kú, àwọn kìí fojú ṣe ètùtù tàbí rúbọ
Oniruuru arun ẹfọju lo wa ti ko han si awọn eeyan, eyi to si yẹ ka da ara wa lẹkọ le lori.
Awọn eroja kan wa ninu oju ti a mọ si Conias, orisirisi nnkan si lo le fa a, ki awọn eroja naa da isẹ silẹ.
Aisisẹ wọn si le fa ipenija oju tabi ki oju naa fọ patapata, idi si ree ti BBC Yoruba fi lọ si ibudo ise oju pamọ lọjọ si to wa nilu Eko, to maa n fun awọn eeyan ti oju wọn ti fọ ni oju mii.
Amọ o se ni laanu pe ọpọ eeyan ni ko setan lati sugba ibudo yii, ti wọn kii si tọwọ bọ iwe lati fi oju wọn silẹ lẹyin ti wọn ba ku tan.
Mosunmade aya Faderin, tii se onimọ nipa itọju oju salaye fun wa nipa awọn eroja oju wọnyii, to si ni ti ọlọjọ ba de, oju nikan lo kọkọ maa yọ laarin ọjọ mẹta.
Amọ tawọn eeyan ba ti fun onimọ isegun ni asẹ lati tete yọ oju alaisi naa laarin ọjọ kan to ku, wọn yoo se itọju rẹ fun iwulo ẹlomiran.
Eyi si lo ni yoo mu ki awọn eeyan to ni ipenija oju, ti ko si riran mọ, le ri aanu gba lati riran pada.
Bakan naa ni ọkunrin kan, Emma Akana salaye fun wa nipa isẹ abẹ oju to se nigba ti ko le riran mọ, amọ to riran pada lẹyin ti wọn fun ni oju ẹlomiran.
- Ọọ̀ni obìnrin, Lúwòó Gbàgídà rèé, akọni tó ń gun ọkùnrin ní ẹṣin rìn
- Ìtàn Ọba Yorùbá tí wọ́n yẹgi fún torí ó jí ọmọ gbé ṣe ètùtù
- Mọ̀ síi nípa Shina Rambo tó pàdé Jesu lọ́gbà ẹ̀wọn lẹ́yìn tó ti jalè
- Ogun Àgbẹ́kọ̀yà, ìjà òmìnira fáwọn àgbẹ̀ ni àbí ìfẹ̀míṣòfò?
- Irú èpè wo ni Aláàfin Aolẹ ṣẹ́ fún ìran Yorùbá?
- Àwọn ọba Yorùbá kan rèé tí wọ́n rọ̀ lóyè, tí ọba míràn jẹ lójú ayé wọn
- Ìtàn Gbọnka àti Timi, akọni méjì tó borí Aláàfin Ṣango
- Ìdílé márùn-ún tó gbajúmọ̀ fún òwò ẹrú nílẹ̀ Yorùbá
- Ìtàn ayé Ọba Seriki Abass ti Badagry, tó ní aya 128, ọmọ 144
Aya Faderin wa n rawọ ẹbẹ pe ki awọn alaye wa fun ile iwosan lasẹ lati yọ oju wọn lẹyin ti wọn ba ku tan fun iwulo ẹlomiran.
O fikun pe awọn kii fi oju naa se ẹbọ abi etutu gẹgẹ bi awọn eeyan kan se lero.


