APC Presidential Candidate 2023: Oluwo ní kò sí ìṣọ̀kan láàrín àwọn ọmọ Yorùbá tó ń díje ní APC

Aworan Tinubu ati Oluwo Iwo

Oríṣun àwòrán, Facebook/officialasiwajubat/emperortelu1

Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi ti fi idunnu rẹ han si bi iyapa ṣe wa laarin awọn agba oṣelu ti wọn jẹ ọmọ Yoruba lorilẹede Naijiria.

Ọba Akanbi fi ero rẹ han ninu atẹjade to fi lede ṣaaju idibo abẹle sipo aarẹ ni ẹgbẹ oṣelu APC ṣaaju idibo gbogboogbo ti ọdun 2023.

Oluwo ni iyalẹnu gba lo jẹ fun oun bi iyapa ṣe wa laarin awọn ọmọ Yoruba ni ẹgbẹ oṣelu APC to n ṣejọba orilẹede Naijiria ati ẹgbẹ oṣelu PDP.

Àkọlé fídíò, 'Tí kìí bá ṣe pé mo rọ lẹ́sẹ̀, àwọn èèyàn sì kọ̀ láti gbé mi lọ ilé ẹ̀kọ́, ó yẹ kí ń ti dí "Lawyer" àmọ́...'

O ni eleyii ṣafihan aisi iṣọkan laarin awọn agbaagba ilẹ Yoruba naa.

Oluwo wa rọ aṣiwaju Bola Tinubu lati pawọpọ pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ ni ẹgbẹ oṣelu ki ilọsiwaju le de ba ilẹ Yoruba.

''Ifọwọsowọpọ laarin awọn Yoruba ni ẹgbẹ oṣelu APC ni Yoruba fi le ri ọwọ mu nitori naa ki wọn ma fi ti imọtaraẹni ṣe oṣelu lasiko yii.''

Àkọlé fídíò, Ko sọna ni APC ati PDP

''Asiko yii jẹ asiko to lamilaaka ni itan oṣelu orilẹede Naijiria paapaa ni ilẹ Yoruba, nitori naa ki gbogbo wọn jọ ṣiṣẹ pọ fun itẹsiwaju ilẹ wa''

''Gẹgẹ bi baba ni ilẹ Yoruba, awọn iṣẹlẹ yii n kọ mi lominu nitori naa ki awọn agbaagba ni awujọ dide ki wọn dasi ọrọ to wa nilẹ yii.''

''Mo bẹbẹ lọwọ aṣiwaju lati ko ipa baba lasiko yii bi o ti ma n se ni atẹyinwa, ki ọna abayọ le wa fun ilẹ Yoruba ni apapọ.''

''A ko gbọdọ tun padanu tabi ṣe aṣemaṣe kankan lasiko yii, asiko iṣerere wa ni eleyii.''

Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdurọsheed wa pe fun ipade oṣelu ni ilẹ Yoruba gẹgẹ bi ọna abayọ si gbogbo aigbọraẹniye to wa nilẹ.

Bakan naa lo rọ awọn agbaagba lati parapọ yan ẹnikan ṣoṣo ti yoo dije dupo lati ilẹ Yoruba ni ẹgbẹ oṣelu APC.

Oluwo ni oun lero wi pe asiko ko i tii lọju lati ṣe atunṣe ki ohun gbogbo le lọ ni irọwọrọsẹ.

Oba ilu Iwo naa parọwa si gbogbo awọn eekan ni ilẹ Yoruba lati da si ọrọ yii ki wọn ba le tun ile ara wọn to ki ọla ma ba pẹju fun ilẹ Yoruba