Afurasí Fulani darandaran gún èèyàn kan pa l‘Eko torí pé ọkọ̀ pa màálù kan
Lagos Death: Bí Fulani darandaran ṣe pa ẹnìkan l‘Eko rèé torí màlúù tó kú

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Rogbodiyan waye ni opopona Lagos-Badagry ni ọjọ aje lẹyin ti awọn afurasi Fulani darandaran gun awakọ ọkọ elero pa ni ipinlẹ Eko.
Awọn darandaran meji ti wọn fẹsun kan naa ni wọn ti wa ni panpẹ ọlọpaa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin to fi idi ọrọ naa mulẹ loju opo Twitter rẹ salaye bi iṣẹlẹ naa ṣe waye.
‘’ Ọkọ akero ti ipinlẹ Eko to n sare bọ kọlu malu meji ni agbegbe Agemowo, ni Badagry, to si pa maluu ẹyọ kan.’’
‘’Awọn Fulani darandaran naa ṣekọlu si ẹnikan ti wọn rọ wi pe oun ni awakọ ọkọ naa, to si jasi iku rẹ.’’
Bi iṣẹlẹ ọhun ṣe waye ree
Hundeyin salaye pe lẹyin iku ẹni ti awọn darandaran naa pa ni awọn ọdọ ni agbegbe naa bẹrẹ ifẹhọnuhan ti wọn si yari pe wọn ko ni gba lori iṣẹlẹ naa.
O fikun un pe ọga ọlọpaa DPO ti Morogbo Division pẹlu iranwọ awọn ikọ ọmọogun 243 Recce Battallion, Badagry ni wọn dasi iṣẹlẹ naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
‘’Nibayii, alaafia ti pada si agbegbe naa, ti opopona naa si ti pada si ipo fun awọn arinrinajo lati kọja.’’
Bakan naa lo fikun un pe ko si otitọ ninu iroyin pe awọn ọlọpaa da ọkunrin ti wọn pa naa pada nigba to n sa asala fun ẹmi rẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
‘’Ko tilẹ le kuro nibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ nitori ibẹ lo kusi, ti ko si de agọ ọlọpaa.’’
Nibayii, ileeṣẹ ọlọpaa fidi rẹ mulẹ pe wọn ti fi panpẹ ọba mu awọn afurasi meji naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa naa ni iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹwu, ti awọn yoo si fi lede bi ọrọ ba ṣe n lọ lori iṣẹlẹ naa.