Èèyàn mẹ́tàlá pàdánù ẹ̀mí wọn nígbà tí adó olóró kọlù ilé ìtajà Ukraine

Aworan ile itaja to n jona ni Ukraine

Oríṣun àwòrán, State Emergency Service of Ukraine

Awọn olori orileede agbaye ti n bẹnu atẹ lu ikọlu ado oloro to ṣẹ si ile itaja nla igbalode kan ni Kremenchuk,Ukraine nibi ti eeyan mọkanla ti ku.

A gbọ pe o to eeyan ogoji ti awọn alaṣẹ ṣi sọ pe o farapa ninu iṣẹlẹ yi.

Ado oloro to ṣokunfa ibugbamu to mu ki ile itaja yi sna wa lati ọwọ awọn ọmọ ogun orileede Russia.

Russia ati Ukraine ti n dojuija kọ ara wọn o to ọjọ mẹta bayi latari ikọlu ti Russia ṣe si Ukraine.

Minisita fọrọ ilẹ okere orileede Amẹrika Anthony Blinken sọ pe ''ado oloro ti Russia ju loni si Ukraine ba awọn eeyan ninu jẹ lagbaye loni eleyi to kọlu ile itaja to kun fọfọ ni Ukraine''

O fi kun pe Amẹrika yoo tẹsiwaju pẹlu iranwọ forileede Ukraine tawọn ko si ni fi Russia silẹ lalae pe wọn lẹjọ.

Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi ni tiẹ Boris Johnson sọ pe ikọlu yi ṣe afihan iwa ọdaju aarẹ orileede Russia Vladimir Putin

Bi ipade awọn olori orileede G7 ṣe n gberasọ, pupọ awọn olori yi lo to pinu lati ṣe iranwọ owo ati nkan ija fun Ukraine

Ajọ isọkan agbaye UN naa ti bẹnu atẹ lu ikọlu ado olori yi ti wọn si juwe rẹ gẹgẹ binkan to fọwọ kan ni lẹmi.

Aworan ile itaja to n jona ni Ukraine

Oríṣun àwòrán, State Emergency Service of Ukraine

Ki lo ti ṣẹlẹ lonii?

  • O kere tan eeyan mọkanla lo padanu ẹmi wọn ninu ibugbamu ado oloro Russia to ba ile itaja igbalode kan ni Kremenchuk
  • Gomina agbegbe Poltova juwe iṣẹlẹ yi gẹgẹ bi ẹsẹ ogun
  • Aarẹ Ukraine Volodomyr Zelensky sọ pe o ṣeese ki eeyan ẹgbẹrun kan wa ninu ile itaja nla naa nigba ti ibugbamu yi ṣẹlẹ
  • Ọpọ awọn olori orileede lagbaye ati ajọ iṣọkan agbaye UN lo ti bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ ikọlu buruku yi.