Wo àwọn nǹkan mẹ́wàá tó ṣe láti ní ìbọn ní Naijiria
Àwọn nǹkan mẹ́wàá tí o gbọ́dọ̀ ṣe láti ní ìbọn ní Naijiria rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Igbesẹ ijọba ipinlẹ Zamfara lati faye gba awọn araalu lati ni ibọn fun abo ara wọn ti fa ọpọlọpọ awuye kaakiri naijiria.
Ijọba ipinlẹ naa ni eredi igbesẹ awọn ko ṣeyin bi awọn janduku ati ajinigbe ṣe n ṣọṣẹ nipinlẹ naa, paapaa bi wọn ṣe n kọlu awọn agbẹ ninu oko wọn.
Kọmiṣọna eto iroyin ipinlẹ ọhun, Ibrahim Magaji Dosara ni ọrọ abo ipinlẹ naa ti n kọ ijọba lominu, awọn si ni lati wa nnkan ṣe si.
O ni ijọba ipinlẹ ọhun ti paṣẹ fun kọmiṣọna ọlọpaa lati fun awọn to ba nifẹ si ati ra ibọn ni ipinlẹ naa ni iwe aṣẹ lati ṣe bẹẹ fun abo ara wọn.
Ki ni ofin Naijiria sọ nipa ki araalu ni ibọn lọwọ
Nigba ti BBC kan si agbẹjọro kan, Abubakar El Zubair, to jẹ amofin to dantọ ni Kaduna, o ni ofin ko faye gba ki eeyan da ni ibọn, ayafi to ba maa fi ibọn ọhun dẹ igbẹ.
Ọrọ yii kan naa ni onimọ nipa ọrọ abo, to tun jẹ oṣiṣẹfẹyinti ileeṣẹ ọtẹlẹmuye DSS, Akin Adeyi sọ fun BBC Yoruba.
O ni ti awọn ọmọ Naijiiria ba fẹ maa ra ibọn bi wọn ṣe n ẹ nilẹ Amẹrika, ijọba apapọ gbọdọ gbe ofin kalẹ ti yoo ṣalaye lẹkunrerẹ nipa gbogbo awọn ohun to rọ mọ, eyii ti Aaarẹ yoo fọwọ si.
O ni “Ninu iwe ofin ti a n lo lọwọ yii, ko si ẹnikẹni to laṣẹ lati ni ibọn lọwọ.”
Awọn ohun ti o gbọdọ ṣe ree lati ra ibọn
Gẹgẹ bi ohun ti Adeyi sọ fun BBC Yoruba ati ohun to wa ninu ilana ileesẹ ọmọ ogun Naijiria.
- Eni ti yoo ra ibọn naa gbọgọ jẹ ẹni ti ori rẹ pe, wọn si gbọdọ ṣe ayẹwo fun lati fidi rẹ mulẹ pe kii ṣe ẹni ti ori rẹ ti yi nigba kan ri
- Ọjọ ori ẹni to ba fẹ ni ibọn gbọdọ jẹ ẹni ẹni ọdun mejidinlogun soke
- Irufẹ ẹni bẹẹ ko gbọdọ jẹ ẹni to ni arun oju, oju rẹ gbọdọ riran kedere
- Irufẹ ẹni bẹẹ si gbọdọ jẹ ẹni ti kii binu fufu
- Ọlọpaa gbọdọ foju ganni ibọn naa
- O ni iye iwọn ti ibọn naa gbọdọ jẹ, ko gbọdọ jẹ ibọn ilewo bii pistol, 6mm tabi 9mm
- Iwadii si gbọdọ fidi rẹ mulẹ pe ẹni naa ko tii ko si papnẹ ofin ri lori ẹsun iwa ọdaran kankan
Awọn nnkan mii ti irufẹ ẹni bẹẹ yoo tun ṣe
- Ẹni naa yoo fi orukọ rẹ silẹ ni ọọfisi ọlọpaa pe oun fẹ ga aṣẹ lati ni ibọn
- Yoo jọwọ aworan rẹ fun ileeṣẹ ọlọpaa
- Yoo gba fọọmu, yoo si san owo perete fun fọọmu naa
Ẹwẹ, gẹgẹ bii ohun ti agbẹjọro, Mallam Kabiru Adamu sọ, o ni ọga agba olọpaa kan ti fi gege le fifun awọn araalu laṣẹ lati ni ibọn.
Amọ Akin Adeyi fẹsun kan ileesẹ ọlọpaa pe ọpọ igba ni wọn maa n fun ẹni ti ko yẹ ni ibọn, ti irufẹ ẹni yoo si fi wuiwa ọdaran.












