Yíyan Musulumi gẹ́gẹ́ bí igbákejì ààrẹ, àṣìṣe burúkú tí kò ní ìtẹ́wọ́gbà ni - Babachir Lawal

Àwòrán Tinubu, Lawal ati Shettima

Akowe ijọba apapọ nigba kan ri, Babachir Lawal ti bu ẹnu atẹ lu bi oludije ṣipo Aarẹ labe asia ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress, Bola Ahmed Tinubu ṣe kede ẹlẹsin Musulumi, Kashim Shettima, gẹgẹ bi igbakẹji rẹ siwaju eto idibo Aarẹ ti o waye lọdun 2023.

Lawal ninu atẹsita to fi si ori ayelujara wipe yiyan Musulumi gẹgẹ bi igbakẹji jẹ asise buruku ti ko ni itẹwogba rara.

Oludije lẹgbẹ oṣelu APC fun ipo aarẹ, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ni ọsẹ to kọja sọ pe oun ni ibọwọ to peye fun ẹsin mejeeji to tobi julọ ti wọn n ṣe lorilẹede Naijiria sugbọn oun ti yan gomina ipinlẹ Borno tẹlẹ, Kashim Shettima to jẹ Musulumi, gẹgẹ bi igbakeji oludije lẹgbẹ oṣelu APC.

O ni yiyan ti oun yan Shettima ko nii ṣe pẹlu pe oun ko bọwọ fun ẹsin Kristẹni, nitori oun bọwọ fun ẹsin naa ti oun ko si fi ọwọ rọọ si ẹyin.

Lawal, ẹni ti o ṣe atilẹyin fun Tinubu nigba idibo ẹgbẹ oṣelu APC ni yiyan Shettima jẹ apẹẹrẹ pe oludije naa ko nifẹ ẹgbẹ oṣelu ọhun, ti o si fẹran oun nikan.

“O ni lati jẹ pe awọn gomina ati awọn musulumi kan ni ariwa orilẹ ede Naijiria ni wọn gba Tinubu ni amoran lati yan igbakẹji lati ninu ẹsin Musulumi nitori wọn ko ni dibo fun ẹnikẹni to ba wa lati ninu ẹsin kristẹni ni apa ariwa orilẹ ede Naijiria.

“Ti Tinubu ba ro pe yiyan Musulumi gẹgẹ bi igbakẹji rẹ yio mu u bori ninu eto idibo to n bọ, o ni lati lọ tun un ro. Ise awọn apa ariwa orilẹ ede ni lati dibo fun ọkan lara awọn ọmọ nikan. Buhari, ọmọ wọn akọkọ ko ni si ni iwe idibo lọdun 2023, sugbọn Atiku, ọmọ wọn kẹji wa ni bẹ.”