Wo àwọn ọ̀nà tí wọ́n ń gbà yan olórí ní UK

Boris Johnson

Ní àná ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Keje, oṣù Keje, ọdún 2022 ni olóòtú ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sí, Boris Johnson fi ipò sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí ẹgbẹ́ òṣèlú Conservative.

Èyí kò ṣẹ̀yìn ìpè tí àwọn kan ń pè tako Johnson pé kó fi ipò sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olóòtú ìjọba orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sí.

Ẹ̀sùn aṣemáṣe tí wọ́n fi kan Chris Pincher tí wọ́n ni Johnson mọ̀ sí àti àwọn ẹ̀sùn mìíràn ló ṣokùnfà tí Johnson fi kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ bí olórí ẹgbẹ́ òṣèlú Conservative.

Àmọ́ yóò ṣì máa tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́ bí olóòtú ìjọba.

Ní báyìí tí Boris Johnson ti kọ̀wé fipò sílẹ̀ wọ́n nílò láti yan olórí mìíràn fún ẹgbẹ́ òṣèlú Conservative.

Báwo ni wọ́n ṣe ń yan olórí ẹgbẹ́ òṣèlú Conservative mìíràn?

Tí àwọn olùdíje báti jáde láti jẹ olórí ẹgbẹ́ òṣèlú Conservative, olùdíje kọ̀ọ̀kan nílò láti ní àtìlẹyìn mínísítà mẹ́jọ tí yóò ṣe àtìlẹyìn fún-un.

Tó bá di àsìkò tí wọ́n yóò bá dìbò, ní ìpele àkọ́kọ́ ẹni tí kò bá ti ní tó ìbò méjìdínlógún ma já kúrò nínú ìdíje.

Ní ìpele kejì, ẹni tí kò bá ti ni ìbò mẹ́rìndílógójì ló máa já kúrò nínú ìdíje náà.

Àmọ́ tí gbogbo wọn bá ní iye ibò yìí, ẹni tí ìbò rẹ̀ bá kéré jùlọ ló ma já.

Báyìí ni wọ́n máa tẹ̀síwájú títí tó ma fi ku ènìyàn méjì.

Tó bá ti ku àwọn olùdíje méjì ní àwọn ọmọ ẹgbẹ́ lápapọ̀ máa ni àǹfàní láti dìbò yan ẹni tó bá wù wọ́n.

Ẹni tó bá gbégbá orókè níbi ìdìbò yìí ni yóò máa jẹ olórí ẹgbẹ́ àti olóòtú ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sí.

Àwọn nǹkan márùn-ún tó fà á tí Boris Johnson fi kọ̀wé fipò sílẹ̀ rèé

Ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn ni Boris Johnson jáwé olúborí láti di olóòtú ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fún ẹgbẹ́ Conservative láti ọdún 1987 sẹ́yìn.

Àwọn nǹkan tó fàá tó fi kọ̀wé fipò sílẹ̀ nìyí:

Ọ̀rọ̀ Chris Pincher

Ní ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹfà, Mínísítà Chris Pincher lọ síbi ayẹyẹ kan tó sì mú ọtí àmujù ní èyí tó mu ṣe àwọn aṣemáṣe kan.

Lára àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án ni wí pé ó fọwọ́ kan àwọn obìnrin méjì kan lọ́nà àìtọ́.

Johnson ní òun kò mọ ohunkohun nípa àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n kà sí Pincher lọ́rùn ṣùgbọ́n wọ́n ní irọ́ ni.

Johnson lọ sí ibi ayẹyẹ lásìkò tí òfin kónílé-ó-gbélé wà níta

Nínú oṣù Kẹrin ọdún 2022, wọ́n ní kí Johnson san ìtanran nítorí pé ó lọ síbi ayẹyẹ lásìkò tí òfin kónílé-ó-gbélé wà níta nínú oṣù Kẹfà ọdún 2020 lásìkò ọjọ́ ìbí rẹ̀.

Johnson tọrọ àforijí fún títẹ òfin lójú mọ́lẹ̀ nígbà náà ṣùgbọ̀n tó ní gbogbo òfin tó de Covid-19 ni àwọn tẹ̀lé níbi ayẹyẹ náà.

Ọ̀wọ́n gógó àti àlékún owó orí

Ọ̀wọ́n gógó ti bá gbogbo nǹkan ní orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní ọdún 2022 sí ìdá 9.1%. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀wọ́n gógó yìí kìí ṣe ẹ̀bi Johnson síbẹ̀.

Lára ohun tó fà á tí àwọn ọjà fi gbówó lórí ni ogun tí Russia ń gbé ti Ukraine.

Ìjọba gbé ìgbésẹ̀ láti mú àdínkù bá owó orí epo síbẹ̀ Johnson mú àlékún bá owó orí tí àwọn ènìyàn ń san.

Ọ̀rọ̀ Owen Paterson

Ní oṣù Kẹwàá ọdún 2021, ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní kí ilé ní kí Owen Paterson lọ rọ́kún nílé fún oṣù kan nítorí pé ó tẹ òfin lójú mọ́lẹ̀.

Ṣùgbọ́n ẹgbẹ́ Conservative tí olórí wọn jẹ́ olóòtú ìjọba fẹ́ tẹ ọ̀rọ̀ náà rì nípa gbígbé ìgbìmọ̀ míì dìde láti ṣèwádìí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Paterson

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ariwo Paterson kọ̀wé fipò sílẹ̀ tí Johnson náà sì ní òun gbà pé òun kò ṣe dada lórí ọ̀rọ̀ ọ̀hún.

Wọ́n ní Johnson kò ní àfojúsùn

Lára ohun tó gbé Johnson wọlé ni ọ̀rọ̀ Brexit.

Ṣùgbọ́n láti ìgbà tó ti ṣe èyí ni ẹnu ti ń kùn-ún wí pé ìjọba rẹ̀ kò ní àfojúsùn kankan.

Lára àwọn tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ Johnson àmọ́ tí wọ́n ń tàkó ní báyìí, Dominic Cummings kò ní àfojúsùn kankan fún orílẹ̀ èdè náà.

Boris Johnson kéde pé òun ti fipò olóotú Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sí sílẹ̀

Aworan Boris Johnson

Oríṣun àwòrán, Google

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Inu mi baje lati fi iṣẹ to dara julọ lagbaye sile- Boris Johnson

Olootu ile Geesi, Boris Johnson ti kọwe fipo rẹ silẹ bayii.

O ni pe o dun oun pe oun ko el pàri gbogbo erongba rere ti oun ni lokan lati se fun ile Geesi.

Saaju ni Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Boris Johnson ti kọkọ gba lati fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bi adari ẹgbẹ oṣelu Conservative

Eyi ko ṣẹyin ipe ti awọn kan n pe tako Johnson pe ko fipo silẹ gẹgẹ bi olootu ijọba orilẹ ede UK

Nitori ẹsun aṣemaṣe ti wọn fi kan Chris Pincher ti wọn ni Johnson mọ si Amọ yoo ṣi maa tẹsiwaju gẹgẹ bi olootu ijọba

Saaju ni Olootu Ilẹ Gẹẹsi, Boris Johnson ti kọkọ tẹnu mọ pe oun ko ni fi ipo silẹ lẹyin to ja iwe lọ gbe ile rẹ fun akọwe ijọba lori ọrọ ile gbigbe, Michael Gove.

Ọpọlọpọ awọn alabaṣiṣẹ rẹ to fi mọ awọn ẹgbẹ oṣelu rẹ lo ti kọ iwe fi ipo silẹ.

Johnson lasiko to n ba awọn aṣofin Ilẹ Gẹẹsi sọrọ ni oun yoo tẹsiwaju ninu iṣẹ oun lai wo ẹyin.

‘’Iṣẹ Olotu Ilẹ Gẹẹsi kii ṣe iṣẹ to rọrun amọ a gbọdọ ṣe ohun to tọ lati ṣe lai wo ẹyin.’’

Awọn to n kọ iwe fi ipo silẹ naa tako iyansipo oṣiṣẹ agba ni ijọba rẹ ti wọn fi ẹsun ifipabanilopọ kan an.

Igbiyanju nlọ lọwọ lati ba Johnson jiroro lori ati fi ipo silẹ rẹ nitori awọn ololufẹ rẹ pẹlu awọn to n pe fun ikọwe fi ipo silẹ rẹ.

Ki lo fa ipe fun Olootu Ilẹ Gẹẹsi, Boris Johnson lati fi ipo silẹ?

Ipe fun Olotu Ilẹ Gẹẹsi, Boris Johnson lati fi ipo silẹ niise pẹlu igbakeji aṣofin ile(deputy Chief whip), Chris Pincher to fi ipo silẹ ni ọsẹ to kọja lẹyin ti wọn fi ẹsun kan an pe o dimọ ọkunrin meji lọna aitọ, lẹyin to ti mu ọti yo.

Ileeṣẹ ijọba kọkọ sọ wi pe Johnson ko mọ nipa iṣẹlẹ ṣiṣẹ aṣemase ti wọn ti fi kan Pincher ri ki wọn to yan an si ipo.

Amọ ni Ọjọ Iṣẹgun ni oṣiṣẹ ijọba agba kan ni Boris Johnson mọ iru eniyan ti Pincher jẹ nitori ni ọdun 2019 ni wọn sọ fun Johnson to ṣe minisita fun ọrọ ilẹ okeere nigba naa pe ọrẹ rẹ tun ti ṣe aṣemaṣe.

Nibayii, o ti da aadọta oṣiṣẹ ijọba to ti fi ipo silẹ nitori iṣẹlẹ naa, ninu wọn ni minisita, aṣofin to fi mọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu rẹ ati awọn oṣiṣẹ ijọba miran.