Olóòtú ìjọba tẹ́lẹ̀ rí ní Japan, Shinzo Abe dágbére fáyé

Shinzo Abe

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Olóòtú ìjọba tẹ́lẹ̀ rí ní orílẹ̀ èdè Japan, Shinzo Abe ti jáde láyé lẹ́yìn tí ọkùnrin yìbọn fun níbi ètò ìpolongo kan. Ìròyìn ní kò dín ní wàkátì mẹ́rin tí àwọn dókìtà lò lórí Abe nìkan.

Shinzo Abe

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Olóòtú ìjọba tẹ́lẹ̀ rí ní orílẹ̀ èdè Japan, Shinzo Abe ti wà ní ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀run lẹ́yìn tí ọkùnrin kan yìbọn fún níbi ayẹyẹ kan ní ìlú Nara.

Ẹ̀ẹmejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ọkùnrin náà yìbọn fún Abe kí èkejì tó bàá ní ẹ̀yin tó sì ṣubu sílẹ̀ lẹ́yìn ìgbà náà.

Afurasí tó yìbọn mọ́ Abe ti wa ni àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá.

Gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní Tokyo, Yoichi Masuzoe nínú àtẹ̀jáde tó fi sórí Twitter ní Abe wà ní ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀run.

Àwọn ọ̀rọ̀ yìí ni wọ́n máa ń sọ ṣáájú kí wọ́n tó túfọ̀ òkú ènìyàn ní Japan.

Akọ̀wé ìgbìmọ̀ aláṣẹ Japan Hirokazu Matsuno sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé àwọn kò ní fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Abe ń ṣe ìpolongo ìbò fún olùdíje kan ní Nara lọ́wọ́ lásìkò tí ọkùnrin náà ṣe ìkọlù sí i.

Óṣojúmi kòró kan tí ọ̀rọ̀ ṣojú rẹ̀ ní láti ẹ̀yìn ni ọkùnrin náà ti ṣe ìkọlù sí Abe pẹ̀lú ìbọn ńlá kan.

Àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ní ọkùnrin tó yin Abe níbọn kò gbìyànjú láti sá rárá tó sì ti wà ní àháma àwọn.

Bákan náà ni wọ́n ní ìbọn rẹ̀ tó lò dàbí èyí tí wọ́n rọ.

Ìròyìn ní ó ṣeéṣe kí ọkùnrin náà ti ṣiṣẹ́ rí gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ètò ààbò orí omi.

Ìṣẹ̀lẹ̀ ìbọn yíyín tàbí kí ẹnìkan dá ìbọn ní kò wọ́pọ̀ ní orílẹ̀ èdè Japan tí ìwà ọkùnrin yìí sì ti ń dá onírúurú ìbéèrè ṣọ́kàn àti ẹnu àwọn ènìyàn.