Iléeṣẹ́ ológun òfurufú ṣèèṣì ju àdó olóró sí abúlé kan ní Katsina, ẹnìkan ku, eèyàn 13 farapa

Kò dín ní ènìyàn mẹ́rìnlá tó farapa tí àwọn mìíràn sì pàdánù ẹ̀mí wọn bí àwọn ikọ ọmọ ogun òfurufú ṣe ṣèèṣì ju àdó olóró sí ibùgbé àwọn ènìyàn ní ìpínlẹ̀ Katsina.
Alága ìjọba ìbílẹ̀ Safana ní ìpínlẹ̀ Katsina, Alhaji Muhammadu Kabir Umar nígbà tó ń bá ikọ̀ ìròyìn BBC sọ̀rọ̀ ní àwọn agbébọn ni àwọn ọmọ ogún náà ń gbèrò láti lé kúrò ní agbègbè náà tí wọ́n sì ṣèèṣì ju àdó olóró sí ilé ìgbé àwọn ará Kunkuman.
Umar ní àwọn mẹ́rìnlá ló farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí àwọn gbé lọ sí ilé ìwòsàn.
Ó ṣàlàyé wí pé àwọn mẹ́fà ni ilé ìwosàn Dutsinma gbà láti tọ́jú tí wọ́n sì ní kí àwọn máa gbé àwọn mẹ́jọ yòókù lọ sí ilé ìwòsàn jẹ́nẹ́rà ìpínlẹ̀ Katsina.
Ó ní kí àwọn tó dé ilé ìwòsàn náà ni ẹnìkan nínú àwọn mẹ́jọ náà pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ tí àwọn sì rí ènìyàn méje kó dé ilé ìwòsàn.
Óṣojúmi kòró tí òun náà bá ikọ̀ ìròyìn BBC sọ̀rọ̀ ní nǹkan bí aago mọ́kànlá alẹ́ ni àwọn wà ní ìta níbi tí àwọn ti ń gba atẹ́gùn ni àwọn gbọ́ tí bàbálù ń fò ní orí òkè.
Ó ní ṣàdédé ní àwọn ń gbúròó tí nǹkan ń dún bọ̀ láti òkè tó sì balẹ̀ sí ilé àwọn gbogbo.
Ó ní kò dín ní ènìyàn ọgbọ̀n tí àdó olóró ọ̀hún ṣe àkóbá fún.
Bákan náà ló ní òun mọ ènìyàn kan tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìkọlù náà.
Kí ni iléeṣẹ́ ológun òfurufú sọ?
Àtẹ̀jáde kan tí iléeṣẹ́ ológun òfurufú fi léde kò mẹ́nubà á wí pé àwọn ọmọ ogún náà ṣe ìkọlù sí ilé ìgbé àwọn ènìyàn ní ìlú Kunkuna.
Ohun tó wà nínú àtẹ̀jáde náà ni wí pé àwọn ọmọ ogun òfurufú pẹ̀lú àjọṣepọ̀ àwọn ọlọ́pàá ní àwọn ti ṣekúpa àwọn agbébọn mẹ́rìnlélógún ni àwọn agbègbè kan ní ìpínlẹ̀ Katsina.
Wọ́n ní láàárín ìlú Zakka sí Umadan ní ìjọba ìbílẹ̀ Safana ni àwọn ti ṣe ìkọlù sí àwọn agbébọn náà.
Àtẹ̀jáde náà fi kun pé àwọn ará ìlú ọ̀hún fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ wí pé àwọn agbébọn náà ti pàdánù ẹ̀mí wọn.
Wọ́n ní àwọn ṣàwárí àwọn agbébọn tó sá sínú ilé kan ní agbègbè náà, àwọn sì ju àdó olóró síbẹ̀ nígbà tí wọ́n fún àwọn ní àṣẹ láti ju àdó olóró síbẹ̀.















