Àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ girama bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì bí Ghana

Iléeṣẹ́ ètò ẹ̀kọ́ ní orílẹ̀ èdè Ghana ti rọ àwọn òbí láti ṣe sùúrù, kí wọ́n fi ọkàn balẹ̀ bí àwọn olùkọ́ ṣe bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì káàkiri orílẹ̀ èdè náà.
Àwọn olùkọ́ náà da iṣẹ́ sílẹ̀ lẹ́yìn tí ìjọba Ghana kùnà láti mú àwọn àdéhùn tí wọ́n jọ ṣe ṣẹ.
Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ àwọn aláṣẹ ètò ẹ̀kọ́ Ghana rọ àwọn òbí láti ṣe sùúrù kí wan sì fi ọkàn balẹ̀ wí pá àwọn ń wá ọ̀nà láti fi yanjú ọ̀rọ̀ náà.
Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ètò ẹ̀kọ́, Cassandra Twum Ampofo ní àwọn ti ránṣẹ́ sí àwọn adarí ẹgbẹ́ olùkọ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó wa ní orílẹ̀ èdè náà fún ìpàdé.
Ampofo ní níbi ìpadé náà ni àwọn ti máa jíròrò lórí ọ̀nà tí wọ́n máa gbé ọ̀rọ̀ gbà.
Àwọn ilé ẹ̀kọ́ ṣì wà ní ṣíṣí bí ìyanṣẹ́lódì ṣe ń lọ lọ́wọ́
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyanṣẹ́lódì ṣì ń lọ lọ́wọ́, ilé iṣẹ́ ètò ẹ̀kọ́ ti rọ gbogbo àwọn olórí ilé ẹ̀kọ́ girama káàkiri orílẹ̀ èdè Ghana láti ri dájú wí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wà lábẹ́ ààbò tó péye.
Bákan náà ni wọ́n ní kí àwọn adarí ẹkùn kọ̀ọ̀kan ri dájú wí pé àwọn ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ wà ní ṣíṣí.

Kí ni àwọn olùkọ́ ń bèrè fún?
Àwọn olùkọ́ lábẹ́ àkóso ẹgbẹ́ Ghana National Association of Teachers, GNAT, National Association of Graduate Teachers, NAGRAT, Teachers and Educational Workers Union, TEWU ati de Coalition of Concerned Teachers, Ghana, CCT ń bèrè fén àfikún ìdá ogún lé owó oṣù wọn.
Ọgbọ̀n ojọ́, oṣù Kẹfa ni wọ́n fún ìjọba da láti dàhún ìbéèrè wọn ṣùgbọ́n nígbà tí ọjọ́ náà fi pé ìjọba kùnà láti dá wọn lóhùn ohun tí wọ́n ń bèrè fún.
Àwọn olùkọ́ náà ní tí ìjọba bá ṣe àfikún owó náà, ó máa mú ìdẹ̀kùn bá bí ọ̀wọ́n gógó kò ṣe jẹ́ kí owó oṣù àwọn tó àwọn ná.
Akọ̀wé ẹgbẹ́ GNAT, Thomas Musah ní àwọn kò lè fi ara da ìpalára tí àìtóná owó oṣù náà ń kó bá àwọn mọ́ nítorí pé ohun gbogbo ti gbówó lórí.
Bákan náà ló ni ìjọba gbọ́dọ̀ wá nǹkan ṣe sí owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́ tí kò jọ ara wọn ní orílẹ̀ èdè náà.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí ni àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì náà yan iṣẹ́ lódì nítorí owó oṣù















