Gbọ̀ nǹkan tí Ooni ní àwọn oríadé yóò fí tí INEC lẹ́yìn lórí ìdìbò Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun tó wọlé dé....

Oríṣun àwòrán, ooniadeyeye.enitanogunwusi.9
Ooni Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi ti fi ifarfajin awọn oriade nipinlẹ ọmọluabi han to si ni awọn ṣetan lati fọwọsowọpọ pẹlu ajọ eleto idibo Inec ki idibo Gomina baa le kẹsẹjari.
Idibo naa yoo waye lọjọ Kẹrindinlogun oṣu Keje.
Okaka kini fi ọrọ yi lede lasiko ti ọga agba INEC Ọjọgbọn Mahmood Yakubu ṣe ipade pẹlu awọn ori ade ati ilẹkẹ ni ipinlẹ Osun lọjọ Isẹgun.
Atẹjade lati ọwọ agbẹnusọ Ooni Moses Olafare sọ pe Oba Adeyeye ni awọn ori ade kii gbe lẹyin ẹnikẹni lasiko idibo gẹgẹ bi Inec naa ṣe n ṣe.
O ni “Awa,lọbalọba Osun dabi Inec nidi ka maa da ori apa kan si ṣegbe lẹyin ẹnikankan lasiko idibo.Awa kii se oloṣelu nitori naa laa fi le ba le gbogbo awọn to wa labẹ wa to fi mọ awọn oloṣelu lalae bikita eyikeyi ẹgbẹ ti wọn ba jẹ''
Ooni gbosuba kare fun ajọ eleto idibo Inec ni paapa lori bo ti se n lo awọn ẹrọ igbalode nibi eto idibo rẹ.
“Mo ni lati kan saara si ajọ Inec lori bi wọn ṣe n fi ojojumọ mu iyioada ba eto wọn nipasẹ imọ ẹrọ tẹkinọlọji ti o kapa ibo yiyi.''
O fi kun pe ''ẹ wo eyi ti wọn n pe ni Bimodal Voter Accreditation Sytems,BIVAS ti wọn fi kede esi idibo Ekiti to waye laipẹ yi lai gba asko to pẹ''
Ninu esi tirẹ, alaga ajọ INEC Ọjọgbọn Mahmood Yakubu ki awọn oriade fun ipa ribiribi ti wọn n ko lagbegbe wọn lati le jẹ ki alaafi jọba.
O ni Inec mọ riri nkan tawọn ọba n gbe ṣe to si ni ''kedere ni mo ri pe alaafia jọba mo si ni igbagbọ pe ẹyin lẹ ṣe iṣẹ to bi alaafi a taa n ri kaakiri yi''
O wa rọ awọn oriade naa lati ba awọn to n kopa ninu idije yi sọrọ ni paapa awọn oloselu ati alatilẹyin wọn lati tẹle ilana to tọ nitori idibo ko le waye nibi ti awọn eeyan ba ti n kaya soke.
''Awọn oloṣelu ati alatilẹyin wọn gbọdọ faaye gba alaafia ki a le ṣe idibo ni irọwọ rọsẹ lasiko ipolongo, lasiko ti ibo baa n lọ ati bi ibo ba pari tan''












