A kú ìrọ́jú l‘Osun, ìyà ti pọ̀jú, ojojúmọ́ ní mò ń sunkún – Adeleke

Àkọlé fídíò, Osun 2022 Gubernatorial Election: Àwọn olùdíje g;omìnà sọ̀rọ̀ lórí èròǹgbà wọn fún aráàlú
A kú ìrọ́jú l‘Osun, ìyà ti pọ̀jú, ojojúmọ́ ní mò ń sunkún – Adeleke

Ọpọ koko ọrọ lo jẹyọ ninu eto ifọrọwerọ laarin awọn oludije sipo gomina nipinlẹ Osun, tileesẹ BBC Yoruba seto.

Awọn koko ọrọ naa si lo n ja rain nilẹ lori ayelujara, eyi ti kpo tii dawọ duro.

Idi si ree ta fi mu diẹ wa fun yin ninu awọn ohun tawọn oludije gomina naa sọ lasiko itakurọsọ naa.

Ba se pa awọn ohun amusọrọ ti ni Osun lo mu ka maa yawo kiri - Akin Ogunbiyi:

Nigba to n sọrọ lori ọrọ aje ipinlẹ Osun, oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu Accord, Akin Ogunbiyi ni gbogbo ohun to jẹ amusọrọ nipinlẹ naa, ni wọn ti pa ti.

O ni eyi lo mu ki ipinlẹ naa maa wa owo ya kiri eyi to ti se akoba nla fun gbogbo ẹka idagbasoke nipinlẹ naa.

Bakan naa lo gbara ta pe awọn ko mu eto ọgbin lọkunkundun rara eyi to yẹ ko maa mu owo nla wọle fun wọn.

Ninu gbogbo oludije gomina, emi nikan ni agbẹ, awọn yoku n ka ninu iwe ni – Lasun Yusuff:

Bakan naa ni oludije fun ipo gomina fẹgbẹ oselu Accord nipinlẹ Osun, Họnọrebu Lasun Yusuff ti kede faraye pe agbẹ paraku ni oun.

O ni awọn oludije yoku kan n ka isẹ ọgbin ninu iwe ni, oun nikan ni oun ni oko ọgbin, ti oun si mọ tifun tẹdọ eto ọgbin.

Mo mọ ibi ti iya ti n jẹ ipinlẹ Osun tori ibẹ ni mo ti lo gbogbo aye mi – Goke Omigbodun:

Oludije fun ẹgbẹ oselu SDP, Akinrinola Goke Omigbodun ti salaye pe oun nikan ni oun le wa ojutu sawọn ọpọ isoro to n ba ipinlẹ Osun finra.

O salaye pe ọmọ bibi ipinlẹ Osun ni oun, oun dagba sibẹ, lọ sile ẹkọ nibẹ, ti oun si tun n gbe nipinlẹ naa.

Bakan naa lo ni gbogbo awọn idokowo oun lo wa nipinlẹ Osun, ti gbogbo isoro to wa nipìnlẹ naa si ye oun yekeyeke.

Iya yii ti pọju, ojoojumọ ni n ma n sunkun, ara Osun ku irọju o – Ademola Adeleke

Ni ti oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu PDP, Sẹnetọ Ademola Adeleke, o ni iya ti pọ ju nipinlẹ naa ti awọn araalu n fara da.

O salaye pe ojoojumọ ni oun maa n sọkun ti oun ba wo awọn iya to n jẹ awọn araalu naa, to si n ki wọn ku irọju.

Adeleke ni awọn opopona ko dara mọ, ti ko si si ile iwosan to poju owo fawn alaisan.

O wa fi ọwọ sọya pe ti wọn ba le dibo fun oun wọle bii gomina, gbogbo awọn isoro yii ni yoo di ọrọ itan.

Ko si agbegbe wa ti ko nile iwosan, a si n fi oogun sibẹ:

Nigba to n sọrọ, gomina ipinlẹ Osun, to tun jẹ oludije fun ipo gomina fẹgbẹ oselu APC, Adegboyega Oyetola ni irọ to jinna sootọ ni pe ko si ile iwosan to pegede nipinlẹ naa.

Gomina ni gbogbo agbegbe to wa nipinlẹ naa ni awọn ile iwosan kọọkan wa, ti wọn si poju owo.

Oludije fẹgbẹ oselu APC naa ni loore koore ni awọn n pese oogun gidi sawọn ile iwosan naa fun itọju awọn alaisan.

Osi pọ tori awọn obinrin kii da si okoowo – Lasun Yusuff

Ni tiẹ, oludije fun ẹgbẹ oselu, Labour, amofin Lasun Yusuff ni banki agbaye ti kede pe osi pọ nitori awọn obinrin ki da si nnkan to jẹ mọ̀ ti okoowo.

Amọ o wa seleri pe oun yoo pese owo to to biliọnu marun si mẹsan naira gẹgẹ bii ẹyawo fawọn obinrin.

O ni igbesẹ naa yoo waye laarin osu mẹsan ti oun ba di gomina, ti awọn obinrin yoo si ya owo naa lati bẹrẹ okoowo.