Kemi Afolabi balẹ̀ bàgẹ̀ s’Amẹrika fún ìtọ́jú àrùn Lupus tó ń ba finra
Kemi Afolabi bẹ̀rẹ̀ ìtọ́jú àrùn Lupus tó ń ba finra nílé ìwòsàn Amérika

Oríṣun àwòrán, kemiafolabiadesipe
Oṣere tiata Yoruba, Kemi Afoplabi ti kede pe oun ti n gba itọju aisan Lupus to n ba oun finra.
Ọdun 2022 yii ni Afolabi kede fun awọn ololufẹ rẹ pe oun ni arun naa lara.
Nigba to n pin aworan ara rẹ nile iwosan, oṣere naa ni oun ti bẹrẹ si n gba iwosan nile iwosan John Hopkins to wa ni Maryland, l’Amẹrika.
O ni “Mo ti bẹrẹ itọju aisan Lupus to n ba mi finra lonii, ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 yii nile iwosan John Hopkins.”
“Awọn oninuure kan lo jẹ ki eyii ṣeeṣe, Ọlọrun a ba mi bukun yin lọpọlọpọ. Ẹ gbadura fun mi o.”
Awọn oṣere tiata wa lara awọn to kowo jọ fun Afolabi
Ṣaaju ni awọn ilumọọkan kan ti kọkọ ṣe agbekalẹ ikowojọ kan fun Afolabi lati fi tọju ara rẹ.
Ninu ọrọ idupẹ rẹ, o darukọ Mercy Aigbe, Funke Akindele-Bello, Toyin Abraham, Yomi Fabiyi, Akin Olaiya, Adeoti Kazim, Shola Kosoko, Wumi Toriola atawọn oṣere mii gẹgẹ bii awọn to dide iranlọwọ fun oun.
Lẹyin naa lo sọ pe ilẹ Amẹrika ni itọju naa yoo ti waye ninu oṣu Kẹfa.
Musulumi ni mi, mi o lọ gbawosan nile ṣọọṣi kankan
Ko pẹ lẹyin ti Afolabi kede pe oun ni aisan naa ti iroyin gbode pe o ti lọ sile ijọsin kan lati gba iwosan.
Amọ nigba to n fesi si iroyin ọhun, Afolabi ni Musulumi ododo ni oun, nitori naa ki awọn ololufẹ oun ma ṣe gba irufẹ iroyin bẹẹ gbọ.
O ni lati igba ti iroyin aisan oun ti jade ni oniruru awọn iroyin ofege nipa oun ti n milẹ titi lori ayelujara.
Lẹyijn naa lo fi kun pe oun ko ṣabẹwo sile ijọsin kankan fun iwosan gẹgẹ bii awọn iroyin to gbode.












