Irọ́ ni pé àwọn agbésùnmọ̀mí ko ìwé ìdúnkookò sí àwọn ará Ilara Mokin ní Ondo – Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá

Aworan

Oríṣun àwòrán, Google

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo ti ni ko si otitọ ninu iroyin pe awọn agbẹsunmọmi ko iwe idunkoko ranṣẹ si awọn ara agbegbe Ilara Mokin ni ipinlẹ Ondo.

Iroyin ẹlẹjẹ naa ni awọn ikọ agbesunmọmi kọ iwe si awn araalu naa gba ọdọ ileeṣẹ redio Adaba FM to wa ni ilu Ilara Mokin.

Amọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ko si otitọ ninu iroyin naa ati pe awọn to gbe iroyin naa fẹ da ipaya silẹ ni ipinlẹ naa ni.

Bakan naa ni wọn ni awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Adaba FM naa ti gbe iroyin pe ko si nkan to jọ bẹẹ si ita, nitori naa ki awọn eniyan ma ṣe bẹru.

Ileeṣẹ ọlọpaa naa fikun un pe kọmiṣọnna ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo n gbe igbeṣẹ lati ri pe awọn eniyan ri aabo to daju ni ipinlẹ naa.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Amọ lara awọn eniyan to fesi ni oju opo Twitter naa ni ki awọn ọlọpaa ma lọ sun lori iroyin naa.

Ki wọn ri pe wọn ni ohun ija igbalode to fi mọ ẹrọ imọ aabo to peye ki wọn le ṣe iṣẹ wọn bi iṣẹ.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

Laipẹ yii ni gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu kede pe gbogbo ileeṣẹ ijọba ati awọn ile ijọsin gbọdọ ni ẹ̀rọ CCTV lati da abo bo ara wọn.

Eyi ko ṣẹyin awọn agbesunmọmi to ṣekọlu si ile ijọsin ni ilu Ọwọ ti wọn si pa awọn ijo to le ni ogoji.