Ó ṣeéṣe kó jẹ́ ọmọ Yahoo ló lo obìnrin tó ń gbó bí ajá - Ọlọ́pàá

Ajá

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Gbogbo abiyamọ ayé a ò ní dàámú lórí ọmọ.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé lóòótọ́ ni ọmọbìnrin kan ní ìlú Abeokuta, olú ìlú ìpínlẹ̀ náà ṣà déédé bọ́ ara rẹ̀ sí ìhòhò tó sì ń gbó bí ajá.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun, Abimbola Oyeyemi nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lọ́jọ́ Ẹtì ní àwọn ti wà lórí ọ̀rọ̀ náà.

Oyeyemi tó kọ̀ láti fi orúkọ ọmọbìnrin náà léde ní ó ṣeéṣe kó jẹ́ wí pé àwọn ọmọ Yahoo ló lo arábìnrin náà fún ògùn owó gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣe fẹ̀sùn kàn.

Ó ní ó ṣeéṣe kí ọ̀rọ̀ náà ríbẹ̀ ní tòótọ́ àti wí pé bóyá òhun ló fà á tí ọmọbìnrin náà fi ń gbó bí ajá.

Ó ṣàlàyé pé nígbà tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá gbọ́ sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, àwọn ti ọmọbìnrin ọ̀hún sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n ní àgọ́ ọlọ́pàá Enugada nítorí nígbà tí wọ́n máa fi mu wá, ó ti wà ní ìhòhò ọmọlúàbí, tó sì ń gbó bí ajá.

Ó fi kun pé gbogbo ìṣe rẹ̀ ló yàtọ̀ sí ti ẹni tí orí rẹ̀ pé nítorí kò mọ ohun tó ń ṣe mọ́ tí àwọn sì kàn sí àwọn òbí rẹ̀ ní ẹsẹ̀kẹsẹ̀.

Oyeyemi ṣàlàyé wí pé àwọn òbí arábìnrin náà pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ọlọ́pàá ti gbé ọmọbìnrin náà lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú tó péye.

Ó ní ará ọmọbìnrin náà sì ti ń balẹ́, tó sì ti mọ ohun tó ń ṣe báyìí.

Ọlọ́pàá nawọ́ gán afurasí ọmọ Yahoo tó lo arábìnrin náà

Bákan náà ló ní ọwọ́ kan ni àwọn ti fi ṣìkún òfin gbé ọmọkùnrin tó jẹ́ afurasí ọmọ Yahoo tí ìgbàgbọ́ wà pé òun ló fẹ́ lo arábìrin náà fi ṣètùtù ọlà.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ní àwọn ti ń fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò lọ́wọ́ tí Kọmíṣọ́nà ọlapàá ìpínlẹ̀ Ogun Lanre Bankole sì ti pa àwọn láṣẹ láti gbé ẹjọ́ lọ sí ẹ̀ka tó ń mójútó ìwà ọ̀daràn, CID.

Gbogbo awọn tó pín fídíò ọmọbìnrin náà lórí ayélujára yóò fojú winá òfin

Ẹ̀wẹ̀, Oyeyemi kọminú lórí bí àwọn ènìyàn ṣe ń pín fọ́nrán ọmọbìnrin náà tó wà ní ìhòhò tí kò sì mọ ohun tó ń ṣe mọ́ káàkiri orí ayélujára.

Ó ní èyí tó tilẹ̀ burú jùlọ ni pé fọ́nrán tí wọ́n ń pín kiri lórí ayélujára ṣàfihàn bí ọmọbìnrin náà ṣe wà ní àhàmọ́ ọlọ́pàá.

Ó ní Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá, Lanre Bankole ti wá pàṣẹ wí pé kí àwọn ṣe ìwádìí ẹni tó ya fídíò náà, kí àwọn sì fi ṣìkún òfin mú-un àti gbogbo àwọn tó ń pin fọ́nrán náà lórí ayélujára.

Oyeyemi ní irú ìwà tí àwọn ènìyàn yìí wù lòdì sí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tó sì túnbọ̀ le ṣe àkóbá fún ọmọbìnrin náà ní ọjọ́ iwájú.

Ó ní gbogbo àwọn tó bá lọ́wọ́ nínú pínpín fídíò náà lórí ayélujára ni yóò fojú winá òfin.

Wo ìlànà tuntun tí ìpínlẹ̀ Eko gbé kalẹ̀ lórí bí àwọn èèyàn ṣe lè gbà ṣẹ́ oyún lábẹ́ òfin

Aworan afihan oloyun

Oríṣun àwòrán, Getty

Ipinlẹ Eko ti ṣagbekalẹ ilana kan ti yoo faaye gba oyun ṣiṣẹ lọna ti ko lewu.

Ileeṣẹ ilera Eko sọ pe awọn gbe ilana yi kalẹ lati tọ awọn to n pese iṣẹ ilera bi wn yoo ṣe seto oyun ṣiṣẹ labẹ ofin ipinlẹ naa.

Wọn ni ilana oniwe oju ewe ogoji yi yoo mu adinku ba bawọn eeyan ṣe n padanu ẹmi wọn nipasẹ ṣiṣẹ oyun lọna ti ko tọ.

“A fẹ ri wi pe eto oyun ṣiṣẹ wa larọwọto awọn araalu a si fẹ fun awọn obinrin to loyun nipa ifipabanilopọ tabi ti mọlẹbi fun loyun lanfaani lati ṣe iru oyun bẹẹ''

Ohun ti akọwe agba ileeṣẹ eto ilera ipionlẹ Eko Dr. Olusegun Ogboye sọ ree.

O ni “Iwe ti a gbe jade yi ni iroyin nipa bi awọn oṣiṣẹ ilera to kọsẹmọṣẹ ṣe le ṣeto oyun ṣiṣẹ eleyi ti ko ni mu ewu lọwọ''

Dokita Ogboye fi kun un pe bi ko ṣe si ilana ẹkunrẹrẹ bi eeyan ṣe le yọ oyun ni ipinlẹ naa, awọn ko le fun awọn eeyan ni itọju ẹkunrẹrẹ eyi ti yoo dena iku aboyun.

Njẹ ijọba Eko faaye gba oyun ṣiṣẹ labẹ ofin?

Aworan iwe ilana oyun ṣiṣẹ ni Eko

Oríṣun àwòrán, lsmoh

Labẹ ofin, ipinlẹ Eko ni igbalaaye fun obinrin lati ṣe oyun eleyi ti yoo mu alaafia ba alaboyun naa.

Lọdun 2011 ni ile aṣofin ipinlẹ naa ṣe agbega ofin iwa ọdaran lati le faaye gba oyun ṣiṣẹ ti yoo doola ẹmi obinrin to loyun naa.

Nitori pe wọn fẹ ki idaabo bo deba ilera awọn obinrin, o di dandan lati gbe eto ipese itọju eleyi to wa ni ibamu pẹlu ofin ipinlẹ naa.

Ipinlẹ Eko ko ni awọn eto itọju yi ṣaaju tori naa ni wn fi gbe ilana tuntun yi jade.

Ki lohun to wa ninu ilana tuntun ti wọn gbe jade yi?

Aworan ifilọlẹ ilana oyun ṣiṣẹ ti ijọba Eko gbe kalẹ

Oríṣun àwòrán, lsmoh

Iwe ilana tuntun yi ṣalaye lori iru oyun ṣiṣẹ ti ofin faaye gba nipinlẹ Eko.

Nitori pe o wa ni ibamu pẹlu ofin, ilana yi ṣalaye awọn eto itọju to bojumu fun iru ẹni ti wn ba ṣe iṣẹ oyun ṣiṣẹ yi fun labẹ ofin ipinlẹ Eko.

Bẹẹ naa lo ṣalaye bawọn oṣiṣẹ ilera yoo ṣe ṣe iru oyun ṣiṣẹ yi ati bi wn yoo ṣe mojuto

Dokita Ogboye fi kun pe ''iwe ilana yi ọpọ awọn ti ọrọ kan lo ṣagbeyẹwo rẹ lẹka ilera ati ẹka ofin ni ipinlẹ Eko''

O ni ọdun 2018 lawọn bẹrẹ iṣẹ lori agbekalẹ ilana yi ti awọn akọṣẹmọṣẹ orisirisi si lọwọ ninu igbekalẹ rẹ.