Ènìyàn mẹ́sàn án ti kú ní ìfẹ̀họ́núhàn tako ìjọba ológun

Aworan

Oríṣun àwòrán, AFP

Iye awọn eniyan to ti papoda ninu ifẹhọnu han to n lọ lọwọ lorilẹede Sudan ti pe eniyan mẹsan an.

Awọn afẹhọnuhan naa n ṣe tako ijọba ologun lorilẹede naa.

Gẹgẹ bi ikọ awọn dokita ṣe ṣọ, awọn to ku naa ni ọta ibọn lara, eleyii to ṣeeṣe ko niiṣe pẹlu awọn ologun to koju awọn afẹhọnuhan naa.

Awọn afẹhọnuhan naa gbegidi oju ọna, ti wọn si n gbe paali to sọ wi pe ki awọn ologun kuro nipo.

Lẹyin naa ni awọn ọlọpaa lo tajutaju, omi ati ọta ibọn lati dena awọn ẹro naa ti wọn lọ si ile aarẹ ni olu ilu naa ni Khartoum.

Awọn ẹlomiran to farapa ni wọn gbe lọ si ileewosan ni Khartoum ati ilu ko sunmọ wọn.

Saaju ni ijọba ti gbegile ẹrọ ayelujara ati ẹrọ ilewọ ti wọn fi n pe awọn eniyan fun ifẹhọnuhan naa.

Ọdun to kọja ni awọn eniyan kọkọ ṣe ifẹhọnuhan alagbara lẹyin ti ologun gba ijọba lọwọ awọn aṣejọba tiwantiwa.

Amọ awọn adari ijọba ologun naa ti ni awọn yoo gbe ijọba silẹ fun ijọba tiwantiwa ti awọn eniyan dibo yan.

Amo Ipade alaafia lati pada si iṣejọba awarawa naa ko i tii yọri si rere.